Iran:: Ẹ má fi taratara dúró níbì kan nítorí àwọn tó fẹ́ gbẹ̀san ikú Soleimani

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Oju ni alakan fi n ṣọri lọrọ eto aabo gba bayii lorilẹ-ede Naijiria- Olatunbosun Abolarinwa.

Imọran yii waye lẹyin ti ọga ọlọpaa, Mohammed Adamu ti kesi gbogbo ileeṣẹ ọlọpaa kaakiri lati wa ni igbaradi ki wọn le koju ipenija to ba yọju.

Onimọ nipa ọrọ aabo, Olatubosun Abolarinwa to ba BBC Yoruba sọrọ lo fidi ọrọ yii mulẹ pe ifura loogun agba.

Eyi ko si ṣẹyin bi ile iṣẹ ọlọpaa ṣe sọ pe o ṣeeṣe ki awọn ọlọlufẹ ọgagun orilẹ-ede Iran, Qassem Soleimani ti ilẹ Amẹrika ṣekupa fẹ da rogbodiyan silẹ ni Naijiria.

Loju opo ikansiraẹni Twitter lọga ọlọpaa ti fi ọrọ naa lede.

Ninu ọrọ rẹ, Ọgbẹni Abolarinwa gba awọn ọmọ Naijiria ni imọran lori igbesẹ ti wọn le gbe ki wọn maa baa fara kaasa ti rogbodiyan ba bẹ ṣẹlẹ.

Ọgbẹni Abolarinwa to jẹ akọṣẹmọṣẹ lori eto aabo ni:

1. Toju tiyẹ laparo fi n riran, ki awọn eeyan ma fi taratara duro nibi kibi ti wọn ba wa.

Eyi ko ṣeyin pe awọn agbesunmọmi fẹran lati maa ṣekọlu si ibi tawọn eeyan ba pejọ pọ bi ṣọọṣi, mọṣalaaṣi, ile itaja, ibudokọ ati bẹẹbẹẹ lọ.

2. Awọn eeyan ni lati ṣora fun irin alẹ nitori awọn oniwa ijamba ti wọn maa n fẹran lati fi okunkun bora.

Ati pe jakunmọ kii rinde ọsan, ẹni a bii re kii rinrin oru ni awọn agba maa n wi.

3. Ti ẹnikẹni ba ri alejo ti irin rẹ jọ ti afurasi, ki iru ẹni bẹẹ tete kansi ile iṣẹ ọlọpaa lapapọ lori aago 112, bakan naa awọn olugbe ilu Eko le pe 727.

4. Awọn obi ni lati maa ṣamojuto awọn ọmọ wọn nile iwe ti wọn fi wọn si.

Awọn obi gbọdọ pe akiyesi awọn olukọ si ajeji kankan ti ihuwasi rẹ ba mu ifura dani ni ayika ile iwe awọn ọmọ wọn.

Opin ọsẹ to kọja yii ni orilẹ-ede Amerika fi ibugbamu oloro pa Ọgbẹni Soleimani lori ẹsun pe o ti pẹ ti ọgagun naa ti n wa nidi iṣekupani awọn ọmọ ilẹ Amerika.