Police Checkpoint: Wo àwọn ìgbésẹ̀ tí ó lè gbé láti bọ lọ́wọ́ ẹ̀sọ́ ọlọpàá lóju pópó

Oríṣun àwòrán, AFP
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá orilẹ̀-èdè Nàìjíríà ti sàlàyé àwọn àbàyọ láti bọ́yọ lọ́wọ́ ìdàmú nígbà ti ọlọ́pàá ba dá wọn dúro lójú pópó.
Gẹ́gẹ́ bi àwọn ọlọpàá s sọ ninu àwọn ìkìlọ rẹ̀ ni pe, Rẹ́rìrín músẹ́, wùwà tó tọ́, kí ó si dẹ̀yìn nínú bibá ọlapàá jà. Díẹ̀ lárá àwọn ìmọ̀ràn tí ilé ọlọ́pàá gbé sílẹ̀ rèé gẹ́gẹ́ bi ohun to le mú ki lílọ́ bíbọ̀ rọrun fún àwọn awakọ, pàápàá jùlọ ti àwọn ọlọpàá ba di ọ̀nà ní orilẹ̀-èdè Nàìjíríà.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ìdí ti àwọn ọlọpàá ṣe gbe àwọn ọ̀nà àbáyọ yìí kalẹ̀ kò yé ẹnikẹni sùgbọ̀n kò sàì rọ mọ fọ́nràn kan to n jà rainrain lóri ayelujara laipẹ yìí ni bi ti ọlọpàá kan ti ni dandan afi ki onu gba égbẹrun mẹrin naira lọ́wọ́ awakọ kan Ọlọ́pàá tó n gba rìbá sọ pé 'Ọlọ́run gan fara mọ́ olè jíjà'
Ní ọ̀pọ̀ ìgbà irú àwọn ǹkan báyìí ti sọ awakọ miran di ero ọrun ní ki ọlọpàá yìbọn pa irú ẹni bẹẹ ti o ba kọ lati san irú owo bẹ́ẹ̀.
Nínú àwọn ọ̀nà abayọ ti awọn ọlọpàá fi sita kò si ibi ti wọn tio gba ẹnikẹni nimọràn láti fún ọlọpàá ni rìbá.
Ọ̀pọ̀ àwọn alaye míran ti wọn tun ṣe ni pé ó ṣe pataki lati yin ohun rẹdio kalẹ ti o ba ti de ọdọ̀ ọlọpàá.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2