UEFA Champions League: Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí ikọ̀ Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì méjì wọ àṣekágbá?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ọjọ kini oṣu kẹfa, ikọ Ilẹ Gẹẹsi meji Liverpool ati Totenham yoo figa gbaga ni aṣekagba Champions League ti yoo waye ni papa iṣere Wanda Metropolitano to wa ni Madrid ni orilẹede Spain.
Ibikibi to wu ki igi ifẹsẹwọnṣe naa wọ si, aṣekagba yii yatọ gedegbe si ọpọlọpọ to ti waye ṣeyin ni Champions League.
Ọpọlọpọ ololufẹ ere bọọlu yoo ranti wipe, ọkan ṣoṣo bi iru aṣekagba yii lo ti waye sẹyin ri, iyẹn ni ọdun 2008.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aṣekagba Champions League to waye ni ọdun 2008 ni igba akọkọ ti ikọ Ilẹ Gẹẹsi meji yoo figa gbaga ninu aṣekagba idije Champions League.
Ki lẹ ranti ninu aṣekagba naa lọun?
Aṣekagba ọdun 2008 naa waye laarin ikọ Manchester United ati Chelsea, o si pari pẹlu ọ̀mì (àmi ayo kan si ọkan) ki wọn to lọ abala wòmí-n-gba-sí-ọ (penalties). Manchester United lo bori ninu abala yii pẹlu ami ayo mẹfa si marun, ti wọn si gba ife ẹyẹ naa.
Eniyan to din diẹ ni ẹgbẹrun mejidinlaadọrin (67,301) lo wo ifẹsẹwọnṣe naa ni papa iṣere Luzhniki to wa ni Moscow, orilẹede Russia. Milionu mẹtadinlogun ati aabọ eniyan lo wo ifẹsẹwọnsẹ naa lori ẹrọ mohun-maworan
Atamatase Cristiano Ronaldo lo kọkọ ṣide eto nigba to gba bọọlu si àwọ̀n ni iṣẹju mẹrindinlọgbọn nigba ti Wes Brown fori gbe bọọlu naa si i.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ko pẹ lẹyin rẹ ni Frank Lampard da a pada pẹlu ami ayo kan fun pẹlu ami ayo kan fun ikọ rẹ Chelsea. Titi ti ayo naa fi pari ti o si lọ abala wọmi-n-gba-si-ọ, ikọ mejeeji ko gba ayo kankan wọle.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ifẹsẹwọnṣẹ naa gbóná sii ni apa keji nigba ti olootu ọjọ naa ran Didier Drogba lọ ile nitori wi pe o gba Nemanja Vidić leti ni bii iṣẹju mẹrin si ipari ifẹsẹwọnṣẹ.
Ronaldo kùnà lati gba ayo tirẹ wọ awọn ninu wòmí-n-gba-sí-ọ to waye lọjọ naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin o rẹyin, Manchester United jawe olubori ninu idije naa, o si gba miliọnu meje Euro. Chelsea naa gba miliọnu mẹrin Euro.












