Buhari yóò ṣèpàdé pẹ̀lú Ọba Morocco

Buahri ati Ọba Mohammed Kẹfa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Èyí yòó wáyé lẹ́yìn ìpàdé tí wọ́n ti kọ́kọ́ ṣe l'óṣù Kejìlá, ọdún 2016, lásìkò tí Ọba nàá ṣàbẹ̀wò sí Nàìjíríà.

Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari yóò rìnrìn àjò lọ sí Morocco lọ́jọ́ ìsinmi, ọjọ́ kẹwàá, oṣù Kẹfà.

Agbẹnusọ fún Ààrẹ Buhari, Garba Shehu tó fi ìkéde nàá síta lójú òpó ìkànsíraẹni Twitter rẹ̀, sọ pé, Ọ̀ba Morocco, Mohammed Kẹfa, ló ránṣẹ́ pe Buhari.

Níbi ìpàdé ọ̀hún tí yòó wáyé ní Rabat, nìrètí wà pé , àwọn olórí méjéèjì yòó ti jíròrò lórí ọ̀nà láti ró àdéhùn tó wà láàrin orílẹ̀-èdè méjéèjì, lórí ẹ̀ka tó n pèsè ajílẹ̀, lágbára.

Àkọlé fídíò, 'Ọpọ̀ ẹ̀mí èèyàn ló bọ́ lọ́wọ́ Abacha láàrín 1993 sí 1998'

Ẹ̀wẹ̀, ìkéde nàá tún sọ pé wọn yòó sọ̀rọ̀ lórí ètò ẹ̀kọ́, àti iṣẹ́ àkànṣe afẹ́fẹ́ gáàsì tó pa orílẹ̀-èdè méjéèjì pọ̀.

Èyí yòó wáyé lẹ́yìn ìpàdé tí wọ́n ti kọ́kọ́ ṣe l'óṣù Kejìlá, ọdún 2016, lásìkò tí Ọba nàá ṣàbẹ̀wò sí Nàìjíríà.

Lára àwọn tí yòó kọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lú Ààrẹ Buhari ni gómìnà ìpínlẹ̀ Ebonyi, Dave Umahi, àti akẹgbẹ́ rẹ̀ láti ìpínlẹ̀ Jigawa, Abubakar Badaru.