You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
FIFA U-20 World Cup: Mali pa ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ Argentina lẹ́kún kúrò ni Poland
Bi awada bi ere, ẹgbẹ agbabọọlu Mali ṣe bẹẹ le ẹrujẹjẹ ikọ agbabọọlu Argentina lọ le ninu idije ife ẹyẹ agbaye FIFA U-20 lorilẹ-ede Poland.
Lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Flying Eagles jẹ ajẹtun iya lọwọ Senegal lọjọ Aje, Mali ṣe gudugudu meje ati yahaya mẹfa ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Argentina ni ipele komẹsẹoyọ ẹlẹni mẹrindinlogun.
Ẹẹmeji ọtọọtọ ni Mali tẹyin gberu Argentina lẹyin ti wọn ta ọmi alayo meji meji ninu ere bọọlu ọhun.
- Ìgbájú ìgbámú ni Senegal fi lé Nàìjíríà kùrò ní ìdíje ife àgbáyé FIFA U-20
- Liverpool da ata gúngún sójú Tottenham gba ife ẹ̀yẹ Champions League
- Beckham, àgbábọ́ọ́lù tẹ́lẹ̀ rèé tó ń sọ èdè Yorùbá
- Mi ò ní gbà! Joshua àti Ruiz gbà láti jàjà mííràn lóṣù kọkànlá
- Owó wọgbó! Gẹ̀ẹ́sì gbẹ́sẹ̀ lé ₦82bn owó Abacha
Adolfo Gaich lo gba goolu akọkọ sawọn fun Argentina ki Abdoulaye Diaby to dayo naa pada fun Mali.
Agbabọọlu Diaby kan naa lo fun Argentina lanfaani lati tun siwaju lẹyin to ṣaṣiṣe gba bọọlu sawọn ile rẹ, eleyi to mu Argentina siwaju pẹlu ami ayo meji sẹyọkan.
Ṣugbọn o ku diẹ ki ifẹsẹwọnsẹ naa o pari ni Aboubacar Konte gba goolu keji wọ le Argentina, lọrọ bi wo mi ki n gba siọ ti wọn pe ni pẹnariti.
Awọn agbabọọlu Mali gba pẹnariti marun un wọn wọ le nigba ti Argentina si le gba mẹrin pere sawọn.
Mali yoo waako pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Italy nipele komẹsẹoyọ ẹleni mẹjọ bayii lọjọ Ẹti.