AWCON: Ikọ̀ Super Falcons kijó mọ́lẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba ife ẹ̀yẹ Afirika

Àkọlé fídíò, Ikọ̀ Super Falcons kijó mọ́lẹ̀

Idunnun ṣubu layọ fun ikọ Super Falcons bi ẹgbẹ agbabọọlu naa ti kijo mọlẹ lẹyin ti wọn gba ife ẹyẹ ere bọọlu awọn obinrin ilẹ Afirika fun igb kẹsan an.

Gbogbo awọn agbabọọlu ni wọn fẹsẹ rajo nibi ti wọn ti n dawọọ aṣeyọri ọhun lorilẹede Ghana.

Naijiria fagba han South Africa pẹlu ami ayo mẹrin si mẹta nigba ti ọró di wo mi, ki n gba siọ(pẹnariti), lẹyin ti wọn ta ọọmi odo sodo.

Ikọ Super falcons, South Africa ati Cameroon ni yoo ṣoju ilẹ Afirika bayii ninu idije ife ẹyẹ agbaye awọn obinrin lorilẹede faranse lọdun 2019.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: