Mikel Obi: Ó ku díẹ̀ ká kojú Argentina ni wọ́n jí bábá mi gbé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Wakati mẹrin si igbati Naijiria yoo koju Argentina ninu idije ife ẹyẹ agbaye to n lọ lọwọ ni Russia, ni Balogun ikọ Super Eagles,Mikel Obi gbọ pe wọn ji baba rẹ gbe.

Mikel ni oun ko sọ ọrọ naa fun ẹnikẹni, to fi mọ akọnimọọgba Super Eagles, Gernot Rohr, nitori awọn ajinigbe naa sọ fun oun pe "awọn yoo pa baba naa ti oun ba fi sọ fun ẹni kankan."

Alagba Michael Obi ni wọn ji gbe nigbati o n rinrin ajo lati ilu Jos lọ si apa Iwọ-Oorun Gusu Naijiria nibi ti o ti fẹ lọ bawọn ṣe inawo oku.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igba keji re e ti awọn ajinigbe yoo ji Alagba Michael Obi gbe.

Awọn ọlọpaa sọ pe miliọnu mẹwa Naira ni awọn ajinigbe naa kọkọ bere fun gbara ti wọn ji baba naa gbe.

Mikel ti wa dupẹ lọwọ awọn ọlọpaa fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe ati gbogbo eeyan to gbaruku ti ẹbi wọn.