You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Champions League: Chelsea yoo waako pẹlu Barcelona
Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ati Barcelona yoo gbe'na wo'ju ara wọn nigbati idije Uefa champions league ba pada sori afẹfẹ lalẹ ọjọ isẹgun.
Ọkan ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ ti ko lẹgbẹ yoo waye nigba ti ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea yoo maa gba'lejo ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona lẹyin ọdun kẹfa ti iru rẹ waye kẹyin.
Awọn ẹgbẹ mejeeji ti pade ni igba mejila - lati ọdun 2000. Ipade yii ni ẹlẹẹkẹta iru rẹ fun ipele kẹrindinlogun ninu idije Champions League laarin Chelsea ati Barcelona
Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ti ni ilọsiwaju ninu idije yii kọja ipele akọkọ komẹsẹ o yọ fun saa marun to kọja, ti wọn si f'idirẹmi lẹẹmeji ni ipele yii.
Ipele idije Champions league yi tun jẹ ọkan ninu awọn meji ninu eyi ti FC Porto ati Liverpool FC yoo pade ara wọn.
Awọn ifẹsẹwọnsẹ Champions League ti yoo waye niyii:
Ọjọ iṣẹgun, ogunjọ osu keji
Chelsea vs Barcelona
Bayern Munich vs Besikta
Ọjọru, ọjọkọkanlelogun osu keji
Sevilla vs Manchester United
Shakhtar Donetsk vs Roma.