You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Eégún Oloolu jáde, Oluwo fi ọ̀rọ̀ àbùkù ránṣẹ́ sí i, àwọn àgbà Ibadan sọ òkò ọ̀rọ̀ padà
Ayẹyẹ ọdun egungun Oloolu ti gberasọ fun ti ọdun yii ni ana ọjọ Aje, ọjọ kejidinlogun, ti yoo si maa waye titi di ọjọ kọkandinlọgbọn Oṣu keje.
Ijọba ipinlẹ Oyo ti wa kede bi irinajo gbajugbaja eegun Ibadan naa yoo ṣe lọ, ti yoo si lọ kaakiri ilu naa bẹrẹ.
Awọn agbegbe ti Oloolu yoo de niluu Ibadan ni ijọba si ti gbe ikede sita lati si awọn eeyan leti, paapa awọn obinrin, ki wọn maa baa lugbadi rẹ.
Eyi lo wa ninu atẹjade kan ti Kọmisana fun eto igbafẹ ati asa nipinlẹ Oyo, Wasiu Olatubosun fi sita lati ṣalaye pataki ọdun eegun Oloolu niluu Ibadan.
Olatubosun tẹnumọ pe eewọ lo jẹ fun obinrin lati foju kan Oloolu, ayafi obinrin ti o ba jẹ ibẹta, ti ilu gbagbọ pe wọn jẹ ẹbun lati ọdọ eegun naa.
Wo awọn agbegbe ti eegun Oloolu yoo de nilẹ Ibadan lati sure fun ilu:
Olatunbosun fikun pe Oloolu ki rin bi awọn eegun yoku ṣe maa n rin nitori o ni awọn agbegbe kan ti Oloolu gbọdọ de lati suure fun ilu.
Awọn agbegbe naa ni Aafin Olubadan, Beere, Oje, Idi Arere, Gate, Agbeni, Orita Merin, Oja-Oba, Ayeye, Oranyan, Oke Aremo, Agugu, ati Ore Meji.
Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Oyo ti wa rọ araalu paapa awọn obinrin lati tẹle ofin ati ilana ọdun eegun nitori awọn agbofinro yoo wa ni ikalẹ lati ri pe rogbodiyan ko bẹ silẹ lasiko ijade eegun Oloolu.
Oloolu ti ko ba ti fẹ ri obinrin, ko morile inu Igbo, ko ba ofin mu, koda iwa ọdaran ni - Oluwo
Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi ti sọrọ abuku si Eegun Oloolu to n jade lọdọọdun nilẹ Ibadan.
Ninu fidio kan to gbe soju opo Facebook rẹ eyi to ti fọn ka ori ayelujara bayii, ni Oluwo ti salaye pe aye ti laju ju ki eegun kan maa fi ofin silẹ pe obinrin ko gbọdọ foju kan oun.
Ọba Adewale Akanbi wa ṣapejuwe aṣa yii gẹgẹ bii eyi to tako ẹtọ ọmọniyan, ti ko si yẹ ko fẹsẹ mulẹ lawujọ rara.
"Eyikeyi aṣa to ba tapa si ofin ẹtọ ọmọniyan, emi ki n kopa ninu rẹ.
Asa to ba ti jẹ pe yoo ma pa ọmọnikeji lara, atijọ ti wọn ti n ṣe e, ki n ṣe isin yii mọ.
"Ẹ wo iru Oloolu to wa ni Ibadan, to n sọ pe Obinrin ko gbọdọ jade, to ba jẹ ọdọ temi ni, irọ lo pa.
"Oloolu ti ko ba ti fẹ ri obinrin to n gbe ninu ilu, ko morile Igbo, ko ba ofin mu, koda iwa ọdaran ni."
A fun Oluwo ni ọjọ perete lati tọrọ aforijin lori ọrọ abuku to sọ si Oloolu, bibẹkọ, a gbe awọn iwa idojutini rẹ sita fun araaye - Awọn ọmọ Ibadan yari,
Wayi o, awọn Mogaji, Baalẹ ati apapọ ọmọ Ibadan fesi si ọrọ abuku ti Oluwo sọ nipa eegun Oloolu naa.
Awọn agbaagba nilẹ Ibadan naa ti wa fi ikilọ nla ranṣẹ si Oluwo ti ilu Iwo, Oba Abdulrasheed Adewale Akanbi pe ko dẹkun sisọ ọrọ alufansa si eegun ilẹ Ibadan naa.
Igbimọ yii ni awọn ṣetan lati gbe igbesẹ nla ti Oluwo ko ba dẹkun sisọ ọrọ tako aṣa ati iṣe Ilẹ Ibadan.
Ninu atẹjade kan ti Aarẹ ẹgbẹ Mogaji Ibadan, Magaji Asimiyu Ariori ati Mogaji Nuredeen Akinade fi sita, wọn ni ohun iyalẹnu lo jẹ pe aṣa ati iṣe ilu Ibadan di ohun ti ko mumu lookan aya Oluwo.
"Ti Oluwo ko ba ni oye nipa ẹwa aṣa, ti ko si ṣetan lati bu ọwọ fun aṣa to sọ ọ di Ọba alade, ko fi iwa rẹ mọ ilu Iwo ati ipinlẹ Osun to wa, ko si ma gbe de ilu Ibadan ti wa.
"Ko tọ si Oluwo lẹnu pe ko ma tabuku si aṣa ilẹ Ibadan.
"Aja digbolugi ni, o si dagba ni ilu Ibadan, a mọ ipinlẹsẹ rẹ, ki i ṣe eeyan gidi, ti iwa rẹ ko si da rara.
"To ba tẹsiwaju pẹlu iwa yii, a o lọ gbe awọn iwa idojitini rẹ sita fun araaye"
"Gomina Adeleke, kilọ fun Oluwo, tori ọrọ alufansa to sọ si Oloolu jẹ abuku si ipo Olubadan ati iwọsi si gbogbo ọba ni Ibadan"
Bakan naa ni igbimọ awọn Mọgaji yii tun ke si Gomina Ademola Adeleke ti ipinlẹ Osun, pe ko kilọ fun Oluwo lati ti ọwọ ọmọ rẹ bọ asọ nitori ko tọna ki Ọba maa tabuku si aṣa ilu miiran .
"A ko mọ idi ti ijọba ipinlẹ Osun ṣe fi ara wọn wọlẹ faye gba igbesi aaye Oba yii fun igba pipẹ.
"A n kesi ijọba ipinlẹ Osun pe ki wọn kilọ fun Oluwo, bibẹkọ, Ibadan yoo ri pe wọn fi ofin de nitori inu wa ko dun si,
"Ohun t sọ si Oloolu lo jẹ abuku si ipo Olubadan ati iwọsi si gbogbo lọbalọba niluu Ibadan.
"O jẹ iwọsi fun gbogbo ọmọ ibadan ni ile loko pata."
Igbimọ naa tẹsiwaju pe awọn fun Oluwo ni ọjọ diẹ lati tọrọ aforijin lọwọ gbogbo ọmọ Ibadan ati ilẹ Yoruba lapapọ, ti inu ọpọ ko si ni dun si i ti o ba kuna lati ṣe bẹẹ.
"A ko ni kawọ gbera, maa wo Oluwo ko ma tabuku Oloolu wa.
"Ajọsepọ wo lo wa laarin Oloolu ati Oluwo. Oluwo fẹ da ija ayeraye silẹ nilẹ Yoruba nitori a ko mọ ohun pato to fẹ.
"A ni ọpọ ẹsin ni ilẹ Ibadan, ti ko si si ede aiyede laarin wọn. A ti n gbe papọ pẹlu alaafia fun igba pipẹ."
Ta ni Eégún Olóòlù?
Òdú ni egúngún Oloolu fún àwọn ọmọ bíbí àti olùgbé ìlú Ibadan kódà àwọn ènìyàn tó wà ní ìlú mìíràn mọ̀ nípa eégún Oloolu.
Ní kété tí ènìyàn bá ti dárúkọ eégún Oloolu ní Ibadan ni kálukú ti ma máa forí gbárí, tí wọ́n máa sá àsálà fún ẹ̀mí ara wọn nítorí ẹ̀rù àti agbára tó wà lára rẹ̀.
Àwọn obìnrin kìí ti ẹ̀ sọsẹ̀ rárá nígbà tí wọ́n bá ti gbọ́hùn wí pé eégún Oloolu fẹ́ jáde.
Èèwọ̀ ni fún obìnrin láti ṣíjú wo eégún Oloolu nítorí egungun agbárí obìnrin tí eégún náà máa ń gbé sórí.
Ìgbàgbọ́ sì wà wí pé obìnrin kóbìnrin tó bá ṣíjú wo eégún Oloolu kò ní rí nǹkan oṣù rẹ̀ mọ́ títí tó ma fi jáde láyé.
Kódà ìgbàgbọ́ tún wà wí pé obìnrin bẹ́ẹ̀ le pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lọ́jọ́ àìpé.
Onírúurú àwọn ìgbàgbọ́ ló rọ̀ mọ́ eégún Oloolu lára rẹ̀ náà tún ni wí pé ẹnikẹ́ni tó bá kọ́kọ́ ṣíjú wo eégún Oloolu nígbà tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde, onítọ̀hún ma ṣe àárẹ̀, tí wọn kò bá sì tètè ṣe etùtù ẹni náà le jáde láyé.