You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ohun tí a mọ̀ rèé nípa jàndùkú tó gún èèyàn mọ́kànlá lọ́bẹ nínú ọkọ̀ ojú irin
Lalẹ ọjọ Satide to kọja yii ni awọn ero ọkọ oju irin kan koju ikọlu lọwọ ẹnikan ti wọn lo ṣadeede bẹrẹ si i gun wọn lọbẹ lasiko ti wọn n rin irinajo lati Doncaster si London, lorilẹede UK.
Nigba ti agunbẹ naa yoo fi pitu ọwọ rẹ tan, eeyan mọkanla lo balẹ sile iwosan fun itọju.
Ọkan ninu wọn to jẹ oṣiṣẹ ninu ọkọ irin naa si wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun lasiko ti a n kọ iroyin yii.
Lẹyin iṣẹlẹ naa, awọn ọmọ ilẹ Gẹẹsi meji ti ọjọ ori wọn wa laaarin ọgbọn ọdun ni awọn ọlọpaa mu, ti wọn si ni igunbẹ naa ko mu igbesunmọmi dani.
Wọn pada fi ọkan ninu awọn eeyan meji naa silẹ.
Ṣugbọn Olootu ijọba UK, Sir Keir Starmer, ṣapejuwe iṣẹlẹ naa bii eyi to jọ ni loju to si pe fun abojuto.
Àlàyé àwọn èrò ọkọ̀ nípa bó ṣe ṣẹlẹ̀
Nigba ti ọkọ oju irin London North Eastern Railway (LNER) naa n lọ lati Doncaster, South Yorkshire, si London ni ijamba naa waye.
Awọn ero ọkọ ṣalaye pe ẹnikan lo fa ọbẹ yọ to si fi n halẹ mọ wọn, lẹyin naa lo bẹrẹ si i fi ọbẹ ọhun gun wọn kiri lẹyin ti ọkọ naa gba Peterborough, ni Cambridgeshire, kọja.
Ọkan lara awọn ero ọkọ naa, Alistair Day, ẹni ọdun mejidinlọgọta (58), ṣalaye fun BBC pe oun sa sibi ti wọn ti n ta ipanu ninu ọkọ naa ni, pẹlu awọn ero ọkọ bii mọkanla miran.
O ni ero ọkọ kan sọ foun pe wọn ti gun oun lọbẹ laya: "Ẹjẹ wa ni gbogbo ara rẹ, a gbiyanju lati ba a da ẹjẹ naa a si di i mu."
Ero ọkọ miran, Olly Foster, ṣalaye pe oun gbọ ti awọn eeyan n pariwo pe kawọn maa sa lọ o, nitori ọmọkunrin kan ti wọnu ọkọ to n gun gbogbo ohun to ba ri lọbẹ.
O ni oun tiẹ kọkọ ro pe imuniṣere nipa ọdun Halloween ni.
Akẹkọọ Nottingham University kan to wa ninu ọkọ naa, Amira Ostalski, naa ṣalaye iriri rẹ.
O ni oun ri ẹni toun ro pe o n gunbẹ naa to n fo ori iganna kan kọja.
O ni loju oun bayii ni awọn ọlọpaa ti de ti wọn mu un lọ. Amira ni iṣẹlẹ yii ti mu ki ẹru maa ba oun lati wọ ọkọ oju irin.
Awọn ọlọpaa Cambridgeshire gba ipe ẹ gba wa akọkọ ni nnkan bii aago mẹjọ ku diẹ, wọn si fi to awọn ọlọpaa British Transport Police (BTP) leti laipẹ rara.
Awọn ọlọpaa to dihamọra wọnu ọkọ naa wọn si mu awọn ọkunrin meji laaarin iṣẹju mẹjọ ti wọn pe awọn ọlọpaa BTP.
Awọn ọlọpaa naa pada sọ pe awọn ri ọbe kan nibudo iṣẹlẹ yii.
Ọkan lara awọn ọmọ ile igbimọ Huntingdon, ni UK, Ben Obese-Jecty, sọ fun BBC pe o to ọkọ agboku-gbe alaaye mẹwaa to wa sibudo naa.
Bakan naa ni ẹka National Rail sọ pe ibudo reluwee naa yoo wa ni titipa titi di opin iṣẹ loni ọjọ Aje.
Ohun tí a mọ̀ nípa afurasi náà
Supt John Loveless, lati ẹka ọlọpaa irinna; British Transport Police, sọ pe awọn ọmọ UK meji ti ọjọ ori wọn jẹ mejilelọgbọn (32) ati marundinlogoji (35) ni awọn afurasi ti ọlọpaa mu nibi ijamba naa.
Nigba to di irọlẹ ọjọ Aiku ana ni BTP sọ pe awọn ti yọnda eyi to jẹ ẹni ọdun marundinlogoji naa, wọn ni awọn ko ni i fi ofin mu un mọ.
"Lẹyin iwadii, a fidi ẹ mulẹ pe ko mọwọ-mẹsẹ nibẹ"
Bẹẹ ni ileeṣẹ ọlọpaa naa wi.
Ṣugbọn afurasi ẹni ọdun mejilelọgbọn yoo ṣi wa ni ahamọ ọlọpaa ni tiẹ bi wọn ṣe wi, lẹyin ti ọrọ rẹ ti ni i ṣe pẹlu igbiyanju lati pa eeyan.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti I darukọ rẹ lasiko ti a n kọ iroyin yii, ohun ti awọn ọlọpaa kọkọ sọ ni pe alawọ dudu ọmọ ilẹ Gẹẹsi ni.
Wọn ni Peterborough lo ti wa, o si wọ ọkọ oju irin naa ni ibudokọ Peterborough.
Igbakeji ọga ọlọpaa, Stuart Cundy, ṣalaye pe awọn akọṣẹmọṣẹ oluwadii ti n ṣiṣẹ nipa bi wọn yoo ṣe mọ kulẹkulẹ nipa afurasi yii, ati ohun to mu un ṣe ikọlu naa.
Ohun tí a mọ̀ nípa àwọn tó gún lọ́bẹ
Ikọ onitọju pajawiri kọkọ ko eeyan mẹwaa lọ si ileewosan Addenbrooke's Hospital, ni Cambridge – eyi ti ko ju irin ọgbọn iṣẹju lọ sibudo ọkọ oju irin naa.
Nigba ti yoo fi di aago mẹfa irọlẹ ọjọ Aiku, awọn ọlọpaa sọ pe eeyan marun-un ti pada sile wọn lati ọsibitu naa.
Wọn ni ẹnikan lo wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.
"Ẹni to wa nipo boya yoo ku tabi yoo yè yii jẹ ọkan lara awọn oṣiṣẹ oju irin LNER, ẹni to gbiyanju lati ma ṣe jẹ ki agunbẹ naa ri awọn eeyan gun."
Bẹẹ ni awọn ọlọpaa wi.
" Awọn ọtẹlẹmuyẹ ti wo fidio bo ṣe ṣẹlẹ, wọn si ti ri I pe iwa akọni ni ọkunrin naa wu, o da aabo ẹmi ọpọ eeyan lọwọ iku ni."
Bẹẹ ni ọlọpaa wi nipa ẹni to wa lẹsẹ kan aye,ẹsẹ kan ọrun naa.
Wọn ko ti i darukọ awọn to farapa kankan.
Ẹẹmeloo ni ikọlu iru eyi ti waye ri ni UK?
Orilẹede UK ki I saba koju ikọlu bi eyi, onka iṣekupani nibẹ paapaa si kere bi a ba fi we ti awọn orilẹede agbaye mi-in to ti gunke agba.
Iṣẹlẹ ikọlu nipa ibọn naa kere ni UK, akọsilẹ ijọba wọn sọ pe ko ju 5,103 to ṣẹlẹ lọdun to kọja.
Bi a ba ṣe afiwe rẹ pẹlu ikọlu igunbẹ, iyẹn pọ si i lati 2011.
Iṣẹlẹ igunbẹ 51,527 ni akọsilẹ wa fun pe o waye ti wọn kọ silẹ ni England ati Wales loṣu mejila to kọja titi de oṣu Kẹfa ọdun 2025, gẹgẹ bi akọsilẹ lati ONS (Office of National Statistics) ṣe sọ.
Ninu rẹ, 15,689 lo ṣẹlẹ ni London.
Ọpọ awọn alẹnulọrọ lorilẹede naa ni wọn ti ba awọn ti iṣẹlẹ igunbẹ yii kan kẹdun, lara wọn ni Ọba Chales to ki wọn lorukọ rẹ ati ti iyawo rẹ.