"Digbí ni PDP wà, bí àwọn gómìnà kan ṣe fi ẹgbẹ́ sílẹ̀ kò tu irún kankan lára ẹgbẹ́ wa"

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Pẹlu bi awọn sanko ẹgbẹ osẹlu PDP kọọkan ṣe n fi ẹgbẹ naa silẹ Gomina, Ipinlẹ Adamawa Ahmadu Fintiri ti ni digbi ni ẹgbẹ oṣelu PDP wa

Fintiri lọ sọ ọrọ naa ni Ipinlẹ Oyo nigba ti awọn gomina ẹgẹ oṣelu PDP kan ṣe abewo si awọn ibudo ti wọn ti fẹ gbalejo eto ipade gbogbogbo apapọ ẹgbẹ PDP ti yoo waye lọjọ Karun-un ati ọjọ Kẹfa, oṣu Kọkanla, ọdun 2025.

Ẹ o ranti pe laipẹ yii ni Gomina Ipinlẹ Bayelsa, Duoye Diri àti Gomina ipinlẹ Enugu, Peter Mbah kọwe si ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP silẹ pe awọn ko ṣe ọmọ ẹgbẹ naa mọ.

Gomina ipinlẹ Adamawa tesiwaju wi pe gbogbo awọn to wa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, bayii ni wọn gbora wọn ye, ti ẹgbẹ naa si wa ni isọkan.

O ni pẹlu bii ẹgbẹ naa ṣe n palemọ fun ipade apapọ ọmọ ẹgbẹ oṣelu ọhun ti yoo waye niluu Ibadan, olu ilu Ipinlẹ Oyo, igbagbọ ẹgbẹ oṣelu naa ni wi pe gbogbo awọn to ti fi ẹgbẹ naa silẹ yoo pada sinu ẹgbẹ oṣelu PDP laipẹ.

Fintiri ni "Ẹgbẹ oṣelu PDP kii ṣe ẹgbẹ tí ẹnikan ṣoṣo ń dari, o jẹ ẹgbẹ to ni gbongbo, o lagbara ti o si ni ilana aatẹle ati pe bi igba eeyan ba kuro ninu ẹgbẹ naa digbi ni ẹgbẹ oselu PDP yoo duro.

O fi kun pe afojusun awọn lọwọ yii ni lati gba ijọba Naijiria pada lọdun 2027.

O ni wiwa si ipinlẹ Oyo oun jẹ lati wo ibi ti ipalemọ de duro fun ipade apapọ ẹgbẹ oselu PDP.

Fintiri ṣe abewo si papako ofurufu Ladoke Akintola, papa iṣere Lekan Salami ni Adamasigba.

Ṣaaju ni Gomina Ipinlẹ Oyo Seyi Makinde ti ṣalaye ninu ipade awọn oniroyin wi pe Ipinlẹ Oyo yọ goke agba pẹlu awọn iṣe idagbasoke ti ijọba ohun ti gunle.

Makinde nigba ti o n sọrọ lori ẹni ti yoo gba ìjọba lẹyin rẹ, o ni itesiwaju Ipinlẹ Oyo lọ jẹ oun logun, nitori naa ohun le yan ẹnikan lati tesiwaju sugbọn awọn ọmọ Ipinlẹ Oyo ni yoo dibo fun ẹni ti o ba wu wọn.

Makinde ni "ọpọlọpọ isẹ idagbasoke ni ijọba mi ti ṣe papaa julọ lori atunṣe awọn opopona ilu Ipinlẹ Oyo, ati gba olukọ 15,000, sugbọn ìyẹn kọ ni a fẹ ki wọn ranti wa fun, a fẹ ki gbogbo awọn olugbe Ipinlẹ Oyo ranti ijọba yii fun idagbasoke ti ijọba mi mu wa si Ipinlẹ Oyo.

Ipa wo ni bí àwọn gómìnà ẹgbẹ́ PDP ṣe ń bọ́ sí APC máa ní lórí òṣèlú Nàìjíríà?

Gómìnà ìpínlẹ̀ Bayelsa, Duoye Diri ti kọ̀wé sí ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP pé òun kò ṣe ọmọ ẹgbẹ́ náà mọ́.

Níbi ìpàdé ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹgbẹ́ náà ìpínlẹ̀ náà tó wáyé ní ilé ìjọba ní ìlú Yenegoa ni gómìnà náà ti kéde ìpinnu rẹ̀.

Ó ní ìdí tí òun fi fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀ jẹ́ ohun tó fojú hàn àti pé òun nìkan kọ́ ni àwọn ń fi ẹgbẹ́ òṣèlú náà bíkòṣe pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ilé aṣòfin tí iye wọn jẹ́ mẹ́tàlélógún.

Gómìnà Diri kò sọ ẹgbẹ́ òṣèlú tó fẹ́ lọ darapọ̀ mọ́.

Ìgbésẹ̀ gómìnà Diri yìí ló ń wáyé lẹ́yìn ọjọ́ kan tí gómìnà ìpínlẹ̀ Enugu, Peter Mbah fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀ bọ́ sí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC.

Ìròyìn ní ìgbésẹ̀ gómìnà Mbah ti ń fa ìpinyà láàárín àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Enugu bí àwọn kan ṣe ń faramọ́ ìgbésẹ̀ náà.

Àwọn tó faramọ́ ìgbésẹ̀ Mbah ní yóò mú kí ìpínlẹ̀ náà túnbọ̀ rí àǹfààní ìjọba àpapọ̀ nígbà tí àwọn míì wòye pé kò lè ní ipa kankan nítorí PDP ló ti ń ṣe ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀hún láti ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n sẹ́yìn.

Wo àwọn gómìnà tó ti darapọ̀ mọ́ APC láti ìgbà tí Tinubu ti di ààrẹ

Ọ̀pọ̀ àwọn gómìnà ló ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress láti ìgbà tí ààrẹ Bola Tinubu ti di ààrẹ Nàìjíríà lọ́dún 2023.

Nínú ọdún 2025, yàtọ̀ sí Diri, àwọn gómìnà mẹ́ta míì ló ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC láti PDP.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Enugu, Peter Mbah sọ pé òun ń fẹ́ kí àjọṣepọ̀ tó dán mọ́rán wà láàárín ìpínlẹ̀ òun àti ìjọba àpapọ̀ ni òun ṣe darapọ̀ mọ́ APC.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Kẹfà ni gómìnà ìpínlẹ̀ Akwa Ibom, Umo Eno náà digbá dagbọ̀n rẹ̀, tó ta kọ́sọ́ sí ẹgbẹ́ òṣèlú APC láti PDP tó wà tẹ́lẹ̀.

Gómìnà Eno ní ìdí tí òun fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni ọ̀wọ̀ tí òun ní sí Ààrẹ Tinubu àti láti ṣe àtìlẹyìn fún ààrẹ ilé aṣòfin àgbà, Godswill Akpabio.

Nínú oṣù Kẹrin ni gómìnà ìpínlẹ̀ Delta, Sheriff Oborevwori darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC bó ṣe ní àwọn kò lè máa tẹ̀síwájú nínú okọ̀ tó ti ń rì.

Ní báyìí, àwọn ìpínlẹ̀ tí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ti ní gómìnà kò ju mẹ́jọ lọ.

Àwọn náà ni Ahmadu Fintiri ti ìpínlẹ̀ Adamawa, Bala Mohammed ti Bauchi, Caleb Mutfwang ti Plateau, Agbu Kefas ti Taraba, àti Dauda Lawal ti ìpínlẹ̀ Zamfara ní ẹkùn àríwá Nàìjíríà.

Àwọn yòókù ni Seyi Makinde ní ìpínlẹ̀ Oyo, gómìnà Siminalayi Fubara ti ìpínlẹ̀ Rivers àti Ademola Adeleke tí Osun ní gúúsù Nàìjíríà.

Ipa wo ni kíkúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú bọ́ sí òmíràn máa ní lórí Nàìjíríà?

Malam Kabiru Sufi, olùkọ́ nípa ìmọ̀ ètò òṣèlú ní ilé ẹ̀kọ́ Kano College of Advanced Studies, CAS sọ pé ipa tí kò dára tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ ni bí àwọn gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ṣe ń fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀

Ó ní kìí ṣe ohun tó bójúmu tí ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò bá dojúdé ní Nàìjíríà.

Ó ní èyí yóò túmọ̀ sí pé kò ní sí ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò tó ṣe kókó tó le ìjọba tó wà lóde sí àkíyèsí tí wọ́n bá hu àwọn ìwà kò tọ́.

"Ìjọba yóò máa ṣe àwọn ihun tó bá wù wọ́n pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé kò sí ẹni tó máa yẹ àwọn lọ́wọ́ wò."

Akinola Ayobami, onímọ̀ nípa ètò òṣèlú ní ìpínlẹ̀ Eko sọ pé ìgbésẹ̀ náà léwu fún ọjọ́ iwájú ètò òṣèlú Nàìjíríà.

Ó ní ó dàbí pé Nàìjíríà ti ń lọ sọ́ko níní ẹgbẹ́ òṣèlú kan ṣoṣo láì sí ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò tó le máa sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìgbésẹ̀ ìjọba.

"Tí a bá wo bí ètò òṣèlú Nàìjíríà ṣe ń lọ, ó dàbí pé a ti fẹ́ di orílẹ̀ èdè oní ẹgbẹ́ òṣèlú kan ṣoṣo. Ààrẹ Bola Tinubu gbé irúfẹ́ ìgbésẹ̀ yìí nígbà tó ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Eki tó sì dàbí pé ó fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ lásìkò yìí náà," Ayobami sọ.