Kókó tó wà nínú ìlànà tuntun nídìí gbígba Físà tí Qatar gbé síta fún Nàíjíríà, ọkùnrin kò lè dá nìkan gba físà mọ́

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ileeṣẹ ijọba orilẹede Qatar to n ri si ọrọ abẹle ti kede ilana tuntun fawọn ọmọ Naijiria to ba fẹ gba fisa rinrin ajo lọ si orilẹede naa.

Ileeṣẹ ijọba naa sọ pe igbesẹ yii waye latari bi ọpọ ọmọ Naijiria ṣe n lo ju iye ọjọ to wa lori fisa wọn lọ nigba ti wọn ba rinrin ajo lọ si Qatar.

Ikede ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ abẹle ni Qatar ọhun ti di nnkan ti ọpọ eeyan n sọrọ lori rẹ bayii papaa julọ lori itakun ayelujara.

Wọnyii ni awọn ilana tuntun ti Qatar kede fawọn ọmọ Naijiria to ba fẹ gba fisa lọ si orilẹede naa

Atunṣe akọkọ ti Qatar kede bayii ni pe ọmọ Naijiria to ba fẹ gba fisa rinrin ajo lọ si Qatar gbọdọ sanwo ọkọ baalu ti yoo gbe pada wa si Naijiria silẹ bi o ba ti n sanwo ile itura ti o fẹ de si ni Qatar ki o to le ri fisa gba.

Ni bayii, awọn ọkunrin ko lanfaani mọ lati gba fisa Qatar ayafi ti wọn ba fẹ lọ pẹlu ẹbi wọn loku.

Awọn obinrin tabi idile ni Qatar yoo maa fun ni anfaani bayii lati gba fisa lati Naijiria rinrin ajo lọ si Qatar.

Ilana tuntun mii ti Qatar gbe jade ni pe ọmọ Naijiria to ba fẹ lọ si Qatar gbọdọ le gba ile itura ti owo rẹ ga, bi bẹẹ kọọ, ko ni ri fisa gba.

Ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ abẹle tun fidi rẹ mulẹ pe ọrọ yii kan awọn ọmọ Naijiria ti wọn ti forukọ silẹ lati gba fisa rinrin ajo lọ si Qatar lọwọ bayii.

Awọn orilẹede mii to ti fofin de ọmọ Naijiria lori ọrọ fisa

Orileede UAE wọgile fisa fawọn ọmọ Naijiria

Lọdun 2022 ni ijọba ilẹ UAE fofin de awọn ọmọ Naijiria lati ma le ṣabẹwo silẹ naa mọ.

Ninu atẹjade ti Dubai fi lede, wọn ko sọ eredi pato ti wọn ṣe gbe igbesẹ naa, wọn kan sọ pe ko si aye fun awọn ọmọ Naijiria lati wa silẹ Dubai mọ ni.

Igbesẹ tuntun yii lo n waye lẹyin ọsẹ diẹ ti wọn kọkọ kede awọn ofin tuntun kan nipa iwe irinna ilẹ naa fun awọn ọmọ Naijiria.

Lasiko naa ni wọn sọ pe awọn ko ni fun ọmọ Naijiria ti ọjọ ori rẹ ba kere ju ogoju ọdun lọ ni fisa, paapaa awọn to n lọ lati gbafẹ.

Yatọ si Dominican Republic ti kii ṣe orileede Afrika ṣugbọn ti wọn wọgile Visa fun ọmọ ilu wọn, awọn ogun jẹ orileede lati ilẹ Afrika ti UAE ko faaye gba wọn lati gba Visa wọ ilẹ wọn.

Ninu wọn la ti ri:

Ghana

Sierra Leone

Sudan

Cameroon

Nigeria

Liberia

Burundi

Republic of Guinea

Gambia

Togo

Democratic Republic of Congo

Senegal

Benin

Ivory Coast

Congo

Rwanda

Burkina Faso

Guinea Bissau

Comoros

Uganda

Ijọba Amẹrika ṣe ofin tuntun lori ọrọ fisa fawọn arinrinajo lati Naijiria

Loṣu Kẹjọ to kọja ni ọọfisi ijọba Amẹrika ni Naijiria ti kede pe awọn yoo bẹgi dina ẹnikẹni to ba fẹ gba fisa ilẹ naa lati lọ bi ọmọ ki ọmọ le di ọmọ oniluu l'Amẹrika.

Ọrọ yii lo jẹyọ ninu atẹjade kan loju opo X ijọba ilẹ ọhun lọjọ Aje.

Atẹjade naa sọ pe "a ko ni fun ọ ni fisa ti a ba gbagbọ pe eredi abẹwo rẹ si Amẹrika ni lati lọ bimọ sọhun ki ọmọ rẹ le jẹ ọmọ ilẹ Amẹrika."

Wọn fidi rẹ mulẹ pe awọn ko ni gba ẹnikẹni laaye lati maa lọ silẹ awọn "latari ọmọ bibi nikan ṣoṣo."

Ọrọ yii lo n jade lẹyin ti ile ẹjọ kan sọ ninu oṣu Kẹfa pe Trump le tẹsiwaju ninu igbesẹ to fẹ gbe lati dena awọn to n lọ Amẹrika lati lọ bi ọmọ sibẹ.

Amọ ṣa, awọn ilẹ ẹjọ kan ti pe ẹjọ kotẹmilọrun tako idajọ ọhun.

Ti ẹ ko ba ba gbagbe, lara awọn igbesẹ ti Trump kọkọ gbe gẹgẹ bii Aarẹ kẹtadinlaadọta ilẹ Amẹrika ni lati fopin si bi awọn eeyan ṣe n gba we igbelu latari ibi ti wọn bi wọn si.

Ijọba Canada gbe ofin tuntun jade fawọn to fẹ japa lọ si orilẹede naa

Ṣaaju loṣu Kẹsan an ọdun 2024 to kọja ni ijọba orilẹede Canada gbe ofin tuntun kalẹ fawọn akẹkọọ, awọn oṣiṣẹ lati ilẹ okeere at'awọn ọkọ ati aya wọn to ba fẹ lọ si orilẹede naa.

Ijọba Canada kede pe oun yoo mi adinku ba iwe aṣẹ lati le ṣiṣẹ fawọn akẹkọọ at'awọn oṣiṣẹ lati ilẹ okeere di ida 35% lọdun 2024 yii.

Ijọba orilẹede naa ni 485,000 iwe aṣẹ lati kẹkọọ loun yoo fi sita.

Ijọba ni adinku yoo tun ba eleyii sii lọdun 2025 ati 2026 pẹlu ida 10% tori 437,000 iwe aṣẹ lati kẹkọọ loun yoo fi sita lọdun 2025.

Ninu atẹjade kan eyi ti o ṣẹṣẹ fi sita ni ijọba Canada ti fidi ọrọ yii mulẹ.

Ijọba ṣalaye siwaju si ninu atẹjade ọhun pe iye iwe aṣẹ lati ṣiṣẹ ati lati kawe kan naa loun maa fi sita fun ọdun 2025 ati 2026.

Ijọba mu adinku ba iwe aṣẹ lati kẹkọọ ati ṣiṣẹ fawọn oṣiṣẹ ati akẹkọọ ti wọn fẹ kẹkọọ gboye keji ni fasiti at'awọn to fẹ kẹkọọ gboye Ọmọwe.

Ijọba tun ṣe atunṣe lori anfani tawọn akẹkọọ ti wọn ti kẹkọọ jade yoo ni lati ṣiṣẹ lẹyin ti wọn ba ti kẹkọọ tan.

Ijọba ṣe adinku iwe aṣẹ lati ṣiṣẹ fawọn iyawo ati ọkọ awọn akẹkọọ to n kẹkọọ gboye keji ni fasiti si awọn to maa lo ọdun kan ati oṣu mẹrin nikan lati pari eto ẹkọ wọn.

Ijọba tun ṣe adinku iwe aṣẹ lati ṣiṣẹ lọdun 2024 yii fawọn iyawo ati ọkọ awọn oṣiṣẹ ilẹ okeere lorilẹede Canada.

Ijọba UK fofin de iṣẹ to le lọgọrun-un ti awọn ajoji ti n ṣe

Lojuna ati din bi awọn ọmọ Naijiria atawọn eeyan orilẹede mii ṣe n japa lọ si orilẹede United Kingdom ku, ijọba ibẹ ti fofin de iṣẹ to le lọgọrun-un ti awọn ajoji ti n ṣe tẹlẹ lorilẹede naa.

Ọjọ Satide, ọgbọnjọ oṣu Kẹjọ ọdun 2025 yii ni ọfiisi ijọba UK kede eyi loju opo X wọn.

Ikede naa ṣalaye pe awọn gbegidina awọn iṣẹ naa fun awọn ajoji, ki awọn oṣiṣẹ ọmọ Gẹẹsi le ni anfaani iṣẹ to tọ si wọn.

Wọn fi kun un pe eyi yoo yi ilana atijọ ti orilẹede naa ti n ba bọ nipa awọn ajoji ṣe n gba fisa ilu naa pada.

"Bi a ṣe fẹẹ din bi alaejo ṣe n wọle ku tumọ si fifun awọn to yẹ ni ẹtọ wọn.

"O le ni iṣẹ ọgọrun-un ti awọn ajoji ko le ṣe mọ bayii – eyi ti yoo jẹ ki awọn oṣiṣẹ ilẹ Britain riṣẹ ṣe si i.

"Ilana to n pin in dọgba to si n lo awọn to kaju ẹ lo wọle de yii"

Bẹẹ ni atẹjade ti ọfiisi UK fi sita naa wi.