Ó yẹ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé àjọ̀ ASUU lọ sílé ẹjọ́ fún ìfàkókò ẹni ṣòfò- Mínístà Adamu

Ijọba apapọ ti ni o yẹ ki awọn akẹkọọ gbe ajọ awọn olukọ fasiti (ASUU) lo si ile ẹjọ fun bi wọn ṣe gba ni asiko lati igba ti wọn ti bẹrẹ iyansẹlodi.

Adamu Adamu sọ ọrọ yii ni ile ìjọba l'Abuja lana nibi ti o ti ṣalaye pe o yẹ kí awọn akẹkọọ gbe ASUU lọ sí ileẹjọ fun akoko wọn tí wọn fi n ṣofo.

O fi kun un pe ìjọba o ní gbafun ajọ naa lorí sísan owo fun wọn ní oṣu mẹfa ti wọ́n ko fi ṣiṣẹ.

“O yẹ ki ẹ ẹgbẹ awọn adari Asuu lọ si ile ẹjọ lati san owo pe wọn fi akoko yin sofo.”

Minisita tẹwsiwaju pe Aarẹ Muhammad Buhari ko palasẹ fun oun lati fi opin si iyansẹlodi awọn olukọ fasiti Asuu, koda ko ni ki oun yanju gbogbo awọ naa laarin ọsẹ meji.

O ni nikan ti Aarẹ sọ fun oun nipe ki oun ri daju pe oun yanju pẹlu ajọ Asuu lai fi akoko sofo.

Ẹ ní gbà owó oṣù mẹ́fà tí ẹ fí ṣé ìyabṣẹ́lódi- Adamu

Bakana ni minisita ni ijọba apapọ ko ni san owo oṣu mẹfa ti ajọ olukọ fasiti fi ṣe iyansẹlodi naa.

Adamu tẹsiwaju sapejuwe ajọ Asuu gẹgẹ bi alamore lẹyin ti ijọba apapọ labẹ isakoso Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣe afikun si owo ti ijọba gbe kale fun idagbasoke eto ẹkọ lorilẹede Naijiria.

“Owo ti ajọ Asuu n bẹrẹ fun lo jẹ trilọnu kan kan ati ẹgbẹrun mẹji maira,

“Iyansẹlodi wọn ki ko yẹ ko waye rara.”