Ewu tó wà lára afẹ́fẹ́ tajútajú 'Tear gas' àti iṣẹ́ tó ń ṣe lára èèyàn?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lábẹ́lé, awọn ọlọpaa le lo ẹrọ tajutaju lati tu awọn eeyan ka lasiko ifẹhonuhan.

Ṣugbọn eewọ ni lati lo irinṣe to kun fun kẹmika oriṣiiriṣii yii nibi ti ogun ba ti le.

Eyi ri bẹẹ nitori afẹfẹ to le mu eemi eeyan duro, ti eeyan yoo si ku, wa ninu ẹrọ tajutaju ti a mọ si Tear gas yii.

Ṣugbọn ki gan-an ni ẹrọ tajutaju yii? Ọṣẹ́ wo ni yoo si ṣe lara bi eeyan ba ṣe alabapade ẹ?

Tajutaju ki i ṣe afẹfẹ bo ti jọ loju eeyan, apapọ awọn eroja kan to le ṣe akoba fun ẹdọforo, oju ati àwọ̀ ara eeyan ni.

Oyinbo n pe e ni Tear gas nitori eroja to n mu omije jade loju eeyan to wa ninu rẹ.

Eroja to n mu omije jade yii yoo daamu oju ẹni to ba ṣalabapade tajutaju, ko si ọgbọn ti ẹni naa le da, omije ti oloyinbo n pe ni ‘tears’ yoo jade loju rẹ.

Eyi lo mu ki wọn maa pe e ni Tear gas.

Àwọn ọṣẹ́ míràn wo ni tajútajú ń ṣe lára èèyàn?

Bi o ba mi (breath) lasiko ti tajutaju wa nitosi, ti o fa a simu, o le jẹ ki o maa hukọ.

Tajutaju le ma jẹ ki o mi daadaa. Eyi tun lewu pupọ bi o ba ni ikọọ seemi-seemi ti a mọ si Asthma.

Tajutaju le jẹ ki àárẹ̀ mu ọ, o si le bì (Throw up).

Yatọ si awọn eyi, ẹrọ tajutaju le koba ọkan eeyan, o le ko ba bi ifun eeyan ṣe n ṣiṣẹ pẹlu.

Paripari rẹ ni pe o le ja si iku.

Kí làwọn ohun tó yẹ kí o sáré ṣe bí o bá lùgbàdì tajútajú?

*Fi omi fọ oju rẹ lẹsẹkẹsẹ. O le lo omi kan ti wọn ti pese fun eyi, ‘Saline water’ ni oloyinbo n pe e.

*Bọ si ibi ti atẹgun yoo ti fẹ si ọ daadaa ki o si bọ aṣọ ti tajutaju naa wa lara rẹ silẹ.

* Ri i daju pe o wẹ ara rẹ pẹlu ọṣẹ ati omi.

Laarin iṣẹju mẹwaa si mẹẹẹdogun, alaafia le de si ara rẹ bi o ba ti bọ sibi ti atẹgun yoo ti fẹ si ọ daadaa.

Bi o ko ba waa ri iyatọ, kan si dokita rẹ.

Iwadii fi han pe bi eeyan ba n lugbadi tajutaju fun ọpọ igba, mímí ẹni naa le kun fun wahala.

Ẹyinju rẹ le ko iyọnu, bẹẹ ni awọ ara rẹ paapaa ko le jọlọ.

Ninu ifẹhonuhan to waye laipẹ yii lorilẹede Kenya ati Bangladesh, niṣe lọpọ eeyan n sọ pe wọn lo tajutaju lọna ti ko yẹ fun awọn olufẹhonuhan naa.

Wọn ni wọn ko yọ ọmọde ati awọn arugbo silẹ, pẹlu awọn ẹni to ti ni aarẹ kan tabi omi-in lara tẹlẹ, wọn ni ẹni to ba lugbadi ẹ, ko maa ran an ni wọn fi ṣe.

Labẹ ofin agbaye, wọn fofin de lilo ẹrọ tajutaju loju ogun, ṣugbọn wọn faaye gba a lati fi tu awọn onijagidijagan ka labẹle.

Aṣilo tajutaju n fa iku.

Awọn orilẹde kan lagbaaye, bii America, gbe ilana kalẹ nipa lilo ẹrọ tajutaju yii, nitori ọṣẹ́ to n ṣe fun ilera eeyan.

Lara rẹ ni ki ara eeyan ma balẹ ati idaamu ọpọlọ.