Ṣé lóòótọ́ ni ẹgbẹ́ agbébọn tuntun Mahmuda, kọlu àwọn agbègbè kan ní Kwara?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara ti fesi si iroyin kan to gbode pe, ẹgbẹ agbebọn kan, ti wọn pe orukọ wọn ni Mahmuda ṣekọlu si agbegbe kan nipinlẹ naa.

Iroyin naa ni iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe ijọba ibilẹ Kaiama ati Baruten nipinlẹ Kwara,

Ileeṣẹ ọlọpaa ninu atẹjade ti agbẹnusọ wọn, SP Adetoun Ejire-Adeyemi buwọlu fun awọn akọroyin ni, iwadii ileeṣẹ ọlọpaa fihan pe irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ ko waye ni awọn ijọba ibilẹ naa.

Adeyemi ni, iroyin to ni eeyan mẹẹdogun padanu ẹmi wọn lo jẹ irọ to jina si otitọ, to si n si awọn araalu lọna.

Bakan naa ni Adeyemi ni ko si nnkan to n jẹ ẹgbẹ agbebọn Mahmuda nipinlẹ Kwara.

"A n fi da awọn eeyan ipinlẹ Kwara loju pe awọn ọlọpaa wa ni gbogbo agbegbe wọn lati ri pe wọn da bobo ẹmi ati dukia

"Bakan naa ni a n rọ awọn araalu ati awọn ileeṣẹ igbohunṣafẹfẹ pe ki wọn yago fun pinpin iroyin ẹlẹjẹ kiri eyi to jẹ ki awọn araalu ma paya nibi ki bi ti wọn b awa.

"Gbogbo awọn olori ilu, awọn ẹsọ alabo ibilẹ ni a ti kan si, ti wọn si jẹ ko ye wa iṣẹlẹ naa ko waye rara."

Saaju ni ileeṣẹ iroyin Sahara Reporters gbe iroyin kan ni sita pe ẹgbẹ agbebọn Mahmuda ṣekọlu si awọn agbegbe kan nipinlẹ Kwara, ti eeyan mẹdogun si padanu ẹmi wọn.

Eyi ki n ṣe igba akọkọ ti ileeṣẹ ọlọpaa yoo wọgile iroyin lati ọwọ ileeṣẹ iroyin Sahara Reporters.

Iroyin yii n jade lẹyin ti iṣẹlẹ to waye nipinlẹ Kogi nibi ti eeyan ogun mi-in tun ti di oloogbe ninu ikọlu tuntun kan to waye lagbegbe Logo ati Gbagir, nijọba ibilẹ Ukum, ipinlẹ Kogi.

Ikọlu to waye ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ Ọjọbọ naa ni a gbọ pe awọn darandaran lo wa nidii rẹ.

Atẹjade ti Alukoro ọlọpaa ipinle Benue, CSP Anene Sewuese Catherine, buwọ lu, ṣalaye, pe lasiko ti ìró ibọn n dun lati le awọn agbebọn naa lọ ni awọn eeyan naa bẹrẹ si i yinbọn bo ṣe wu wọn.