You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Atiku, Peter Obi àti El-Rufai gbéná wojú ara wọn lágbo òṣèlú, òkò ọ̀rọ̀ ń bọ́
Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, ti ṣapejuwe Atiku Abubakar, Peter Obi ati Nasir El-Rufai bii ẹni to ti kùnà, ọ̀rọ̀ ara wọn ko si ye wọn mọ bi APC ṣe sọ.
Agbẹnusọ APC, Felix Morka, lo fi atẹjade to ṣalaye pe Atiku to fẹẹ di aarẹ ninu PDP ni 2023, Obi to dije funpo kan naa labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour, ati El-Rufai to kuro nipo gomina ipinlẹ Kaduna, wulẹ n wa ọna ti aye ko fi ni i gbagbe wọn ṣaaju idibo 2027 ni.
Atẹjade APC naa sọ pe awọn eeyan mẹtẹeta yii ko le da gbọ ọrọ ara wọn, wọn si n sọrọ abuku nipa ẹgbẹ APC to n ṣejọba lọwọ.
Báwo lọ̀rọ̀ ṣe dà báyìí?
Nibi eto kan ti wọn ṣe niluu Abuja lọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kin-in-ni ọdun 2025, nipa bi a ṣe le ro ijọba Dẹmokresi lagbara; ni Atiku, Obi ati El-Rufai ti sọ awọn ọrọ kan ti ko tẹ ẹgbẹ APC lọrun.
Nigba ti Atiku n sọrọ nibẹ lo fi ẹsun kan APC, pe ẹgbẹ naa lo n da rogbodiyan silẹ ninu ẹgbẹ alatako, nipa fifi owo ran awọn to n jiṣẹ aburu lọwọ.
"Nibi eto naa 'Strengthening Democracy in Nigeria', ni Atiku ti fẹsun kan Aarẹ Bola Tinubu lai ni ẹri, pe Tinubu n san 50m fun awọn agbagba kan lati maa da wahala silẹ ninu ẹgbẹ alatako ni Naijiria"
Apa kan atẹjade APC lo ka bẹẹ.
Ọrọ Atiku yii pẹlu eyi ti wọn lo sọ, pe ko yẹ ki kootu maa da si ọrọ idibo ni APC fesi si, to si ko awọn yooku ti wọn jọ sọrọ naa mọ ọn pẹlu.
"Iyalẹnu lo jẹ, pe Atiku ti ki i yee lọ si kootu lorii ibo lo n sọ pe bi ile ẹjọ ṣe n da si ọrọ ibo le pa Dẹmokresi lara.
" Dẹmokresi Naijiria rẹsẹ duro nilẹ ju erongba Atiku funra ẹ lọ nipa oṣelu. Ko yẹ ki agba oṣelu maa sọ awọn ọrọ aṣa bi eyi lagbo oṣelu.
"Gẹgẹ bi agba oṣelu, o yẹ ki Atiku mọ pe ijọba awarawa kuro ni ti ki eeyan bori nibi idibo lasan, bi nnkan yoo ṣe daa lo yẹ ko maa wa.
''Ki Atiku gbaju mọ ẹgbẹ oṣelu rẹ o, ko si maa sọrọ to le yi nnkan pada si daadaa ni Naijiria.
" Ọrọ ijọloju ti awọn alatako bii Atiku, Peter Obi, Mallam Nasir El-Rufai sọ, pe ẹgbẹ wa lọwọ ninu rogbodiyan ẹgbẹ alatako, ṣeni laaanu pupọ.
"Wọn ko le dari ẹgbẹ wọn, ṣugbọn wọn fẹẹ fipa dari orilẹede to pọ julọ nilẹẹ Africa''
APC kasi ọrọ rẹ nilẹ, pẹlu alaye pe awọn ọmọ Naijiria mọ ohun ti wọn fẹ.
Wọn ni wọn mọ pe awọn Atiku n wa ọna lati fi APC lorukọ ṣaaju idibo 2027 ni.