You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo oríṣìí oúnjẹ mẹwàá ́tó wọ́n jùlọ ní orílẹ́èdè Nàìjíríà báyìí
Oúnjẹ jíjẹ jẹ́ ohun kòṣémàní ní ìgbésí ayé ọmọnìyàn.
Oúnjẹ ló máa ń fún ènìyàn lókun àti agbára.
Láti ìgbà tí ọ̀wọ́n gógó ti ń bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà látàrí bí ìjọba ṣe yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù ni iye tí wọ́n ń ta oúnjẹ náà ń ní àlékún.
Ìwádìí fi hàn pé ìdá 150% ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ tó jẹ́ oúnjẹ ilẹ̀ wa fi lékún láàárín ọdún kan sí àsìkò yìí.
Àjọ tó ń rí sí òǹkà nǹkan ní Nàìjíríà ìyẹn Nigeria Bureau of Statistics, NBS nínú àtẹ tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde ní àwọn oúnjẹ tó jẹ́ oúnjẹ tiwa-n-tiwa ni ó wọ́n gege báyìí.
Ọ̀dùnkún
Ọ̀dùnkún ni ó lékè àwọn oúnjẹ tí àjọ NBS ní ó wọ́n púpọ̀ níye láàárín ọdún kan pẹ̀lú ìdá 182.04%.
Ọ̀dùnkún tí iye rẹ̀ tó N286. 26 nínú oṣù Kẹrin ọdún 2023 ni wọ́n ń tà ní N807.35 ní oṣù Kẹrin 2024.
Bákan náà ni ọ̀dùnkún tí àwọn òyìnbó ń pè ní Irish potato tí wọ́n ń tà ní N609.57 ní oṣù kẹrin ọdún 2023 ló ti di N1, 413.57 ní oṣù kẹrin 2024.
Ìdá 149.18% ni àlékún fi bá iye owó oúnjẹ yìí.
Ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà
Iye tí wọ́n ń ta ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà tí kò ì tíì pọ́n ni àlékún ti bá pẹ̀lú ìdá 168.29%.
Ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà tí wọ́n ń tà ní N372.89 ní oṣù kẹrin 2023 ni wọ́n ti ń tà ní 1000.41 báyìí.
Bákan náà ni ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà tó ti pọ́n rí àlékún pẹ̀lú ìdá 144.68%.
Èyí tí wọ́n ń tà ní N412.39 ló ti di N1009.05.
Ìrẹsì ọ̀fadà
Ìrẹsì ọ̀fadà jẹ́ oúnjẹ tí ọ̀pọ̀ fẹ́ràn pàápàá nítorí òórùn àti adùn rẹ̀.
Àmọ́ láti ìgbà tí oúnjẹ ti ń gbowó lórí ni ohun náà ti rí àlékún pẹ̀lú ìdá 158%.
Ìrẹsì ọ̀fadà tí wọ́n ń tà ní N601.61 ní oṣù kẹrin ọdún 2023 ti dí N1,552.18 ní oṣù kẹrin 2024.
Ìrẹsì tiwa-n-tiwa
Ìdá 155.93% ni Ìrẹsì tó jẹ́ èyí tí à ń pèsè ní Nàìjíríà fi lékún sí ti ọdún 2023.
Ìrẹsì Nàìjíríà tí wọ́n ń tà ní N546.76 ló ti di N1,399.34 ní oṣù Kẹrin 2024.
Ìrẹsì
Ìrẹsì wẹ́wẹ́ ni àlékún ti bá iye tí wọ́n ń tà á di ìdá 151.95%.
Ìrẹsì wẹ́wẹ́ tí wọ́n ń tà ní N609.57 ni oṣù kẹrin ọdún 2023 ló ti di N1,535.83 ní oṣù kẹrin 2024.
Bákan náà ni àlékún tún bá iye Ìrẹsì wúwo pẹ̀lú ìdá 135.62%.
Kílógíráàmù kan Ìrẹsì wúwo tí wọ́n ń tà ní N631.50 ní oṣù kẹrin ọdún 2023 ló ti di N1,487.91 ní oṣù Kẹrin ọdún 2024.
Iṣu
Iṣu
Iṣu jẹ́ oúnjẹ tí ọ̀pọ̀ fẹ́ràn tí òhun náà sì ti gbowó lórí báyìí.
Ìdá 154.19% ni àlékún fi bá iṣu láàárín ọdún kan sí àsìkò yìí.
Iṣu tí wọ́n tà ní N444.69 ni oṣù kẹrin ọdún 2023 ló ti wà ní N1,130.37 ni oṣù kẹrin 2024 yìí.
Ẹsẹ̀ adìyẹ
Ẹsẹ̀ adìyẹ tí owó rẹ̀ jẹ́ N1,115.29 ní oṣù kẹrin ọdún 2023 ló ti di N2,660.90 ni ọdún 2024.
Èyí ló jẹ́ àlékún ìdá 138.58% sí iye tí wọ́n tà á lọ́dún tó kọjá.