You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ló mú Obesere ṣe iṣẹ́ abẹ tó fẹ́ la ẹ̀mí rẹ̀ lọ?
Gbajúmọ̀ olórin Fújì nnì, Alhaji Abass Akande Obesere tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Obesere ti dúpẹ́ lọ́wọ́ fún Ọlọ́run fún àṣeyọrí iṣẹ́ abẹ tó fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ tó ṣe.
Ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Kẹjọ ni Obesere ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run lórí ìkànnì Instagram rẹ̀ pé ó dá ẹ̀mí òun sí lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ náà.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sọ nǹkan tàbí ìdí tó fi ṣe iṣẹ́ abẹ náà, Obesere ní ẹ̀mí òun fẹ́ẹ̀ bọ́ lórí iṣẹ́ abẹ náà àmọ́ òun dúpẹ́ pé ẹ̀mí òun ṣì wà.
Ó kọ sójú òpó náà pé Ọlọ́run ń ṣe àánú púpọ̀ fún òun “Mo mórí bọ́ lọ́wọ́ iṣẹ́ abẹ tó fẹ́ gba ẹ̀mí mi àmọ́ Allah sọ pé rárá”.
Èyí mú kí àwọn olólùfẹ́ akọrin náà máa kọminú lórí ohun tó mú u ṣe iṣẹ́ abẹ, tí wọ́n sì ń ba dáwọ́ ìdùnnú pé iṣẹ́ abẹ náà kẹ́sẹ járí.
Ta ni Obesere?
Ní ogúnjọ́ oṣù Kìíní ọdún 1965 ni wọ́n bí gbajúgbajà olórin Fújì Abass Akande Obesere.
Obesere àti Ọmọrapala ni orúkọ tí àwọn èèyàn mọ̀ ọ́ sí jùlọ.
Ọmọ bíbí ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo ni Obesere tó sì gbajúmọ̀ fún àwọn àṣà tó máa ń dá nínú àwọn orin rẹ̀.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwò orin ni Obesere ti gbé jáde tó fi mọ́ Omorapala Overthrow, Egunun Be Careful, Obaadan, Old Skool Lape, Mr Magic, Introduction àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Obesere ti kọrin káàkiri ìpínlẹ̀ ní Nàìjíríà àti lókè òkun.
Bákan náà ló ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì ẹ̀yẹ nílé àti lẹ́yìn odi.