Sunday Igboho wọ Gani Adams lọ ilé ẹjọ́ fẹ́sùn ìbanilórúkọ jẹ́

Olóyè Sunday Adeyemo tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Sunday Igboho, tó ń jà fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀ èdè Yorùbá, Yoruba Nation ti wọ́ Ààrẹ Ọ̀nà Kakaǹfò ilẹ̀ Yorùbá, Iba Gani Adams lọ sílé ẹjọ́ fẹ́sùn ìbanilórúkọ jẹ́.

Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Oyo tó fi ibùjókòósí ìlú Ibadan, olú ìlú ìpínlẹ̀ Oyo ni Sunday Igboho ti pe Iba Gani Adams lẹ́jọ́.

Ìgbìmọ̀ àwọn agbẹjórò Sunday Igboho èyí tí agbẹjọ́rò J. A. Sanusi ló ń ṣaájú ẹjọ́ náà nílé ẹjọ́.

Sunday Igboho ní kí ilé ẹjọ́ pa Gani Adams láṣẹ láti san ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta mílíọ̀nù náírà fún òun gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn lórí àwọn ọ̀rọ̀ ìbanilórúkọ jẹ́ tó ṣe sí òun.

Ó fẹ̀sùn kan Gani Adams pé ó pe òun ní apaàyàn àti pé òun máa ń ṣiṣẹ́ agbanipa fún àwọn olóṣèlú tó fi ààrẹ Bola Ahmed Tinubu.

Ó ní nínú fọ́nrán kan tó gba orí ayélujára kan lọ́dún 2021 ni Gani Adams ti fẹ̀sùn náà kan òun.

"Gani Adams pè mí ní agbanipa, ó ní àwọn olóṣèlú ló máa ń lo mí láti kọlù àwọn ènìyàn"

Nínú ìwé ìpẹ̀jọ́ tí Sunday Igboho gbé síwájú ilé ẹjọ́ ní ló ti ń fẹ̀sùn kan Gani Adams pé ó sọ nínú fọ́nrán náà pé òun kò lòdì sí Igboho tẹ́lẹ̀ àyàfi ìgbà tó bẹ̀rẹ̀ sí ní bá Tinubu ṣe.

Ó ní Gani Adams sọ nínú fọ́nrán náà pé “gẹ́gẹ́ bí Aare Onakakanfo ilẹ̀ Yorùbá, òun máa ń gbọ́ oríṣiríṣi nǹkan àṣírí tó bá ń lọ nílẹ̀ Yorùbá.

“Igboho wà pẹ̀lú olórí òṣìṣẹ́ ilé ìjọba Eko, Tayo Ayinde lálẹ́ àná pẹ̀lú ìròyìn tí mo gbọ́. Nǹkan bíi aago mẹ́ta òru ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún ló kúrò lọ́dọ̀ Tayo Ayinde, ẹ sì mọ̀ pé Tinubu máa ń lo Tayo Ayinde fún iṣẹ́ ibi ló ṣe fun ní ipò olórí òṣìṣẹ́ ilé ìjọba.

“Òṣìṣẹ́ àjọ ẹ̀ṣọ́ ààbò ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ni Tayo Ayinde tẹ́lẹ̀, wọ́n gbé owọ fun láti fi wá àwọn ọ̀daràn jọ.

Àwọn olóṣèlú ló máa ń lo Sunday Igboho láti fi ṣèkọlù sáwọn ènìyàn. Tinubu kò ní fi ara rẹ̀ hàn , Tayo Syinde ló máa ń rán.

“Tinubu fún wọn ní àádọ́ta mílíọ̀nù náírà àmọ́ Tayo Ayinde yọ mílíọ̀nù márùn-ún náírà níbẹ̀, ó sì fún Sunday Igboho ni ìyókù, ẹ má gba gbogbo ohun tó ń sọ gbọ́, ó ní kí Tinubu wá jẹ ààrẹ.

“Mi ò mọ ìdí tí àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní ilẹ̀ òkèrè ṣe ń gba Sunday Igboho gbọ́, ẹ má gbà á gbọ́ rárá, ọwọ́ àwọn olóṣèlú ló ti ń gba owó káàkiri, oníjìbìtì àti àrékérekè èèyàn ni.

"Gani Adams ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò dá òun lójú, àmọ́ mo wà lára àwọn tó pa Bola Ige pẹ̀lú Fryo"

“Sunday Igboho kàn ń lo ayélujára láti fi wá àtìléyìn àwón èèyàn ni.

Ó ní kí àwọn iléeṣẹ́ ìroyìn parọ́ mọ́ mi.

Ó ma ma ṣe àtìlẹyìn fún mi lójú mi ṣùgbọ́n ìbàjẹ́ mi ló máa ń ṣe tí mi ò bá ti sí níbẹ̀ mọ́. Ẹ má ṣe àtìlẹyìn fun, kìí ṣe ẹni tó ṣe é gbọ́kàn lé.

“Tinubu ti ṣèlérí láti fun ní ilé ní Lekki àti mílíọ̀nù igba náírà.

Tinubu ń lo Sunday láti fi gba tíkẹ́ẹ̀tì lọ́wọ́ Buhari. Tinubu ló ń lo Sunday, òun ni èèyàn tó burú jùlọ ní ìpínlẹ̀ Oyo báyìí.

“Mi ò sọ ìpínlẹ̀ Eko, àmọ́ tí Sunday Igboho bá rí owó, kò sí ẹni tí Sunday Igboho kò lè pa.

Pẹ̀lú àwọn ìròyìn tí mo gbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò dá mi lójú, ó wà lára àwọn tó pa Bola Ige pẹ̀lú Fryo.

“Tinubu ní kí àwọn 10 million Boys darapọ̀ mọ́ Igboho láti ṣekúpa mí.

Ọ̀pọ̀ ẹ̀sùn ìpànìyàn ló wà lọ́rùn Sunday àmọ́ ó mọ bó ṣe máa ń yọ ara rẹ̀ kúrò nínú àwọn ẹjọ́ náà.

“Lára àwọn ọmọ tó máa ń lò wà ní àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n ń kojú ẹ̀sùn ìpànìyàn lọ́kan-ò-jọ̀kan, àwọn mìíràn ti wà ní ẹ̀wọ̀n gbére àmọ́ òun máa ń lo àwọn olóṣèlú láti fi gba ara rẹ̀ sílẹ̀.

"Gbogbo ilé iṣẹ́ ìròyìn ní wọ́n ti gbé fọ́nrán, mó fẹ kí Gani Adams yí ohùn ẹnu rẹ̀ padà"

Ẹ̀wẹ̀, Igboho jiyàn àwọn ẹ̀sùn yìí nílé ẹjọ́, tó sì ní gbogbo ohun tí Gani Adams sọ nínú fọ́nrán náà ló jẹ́ irọ́ àti pé ìbanilórúkọ jẹ́ gbá à ni ọ̀rọ̀ náà jẹ́.

Agbẹjọ́rò Sunday Igboho sọ fún ilé ẹjọ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ ìbanilórúkọ jẹ́ náà tí Gani Adams sọ pẹ̀lú èèyàn kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Nuru Banjo náà ló wà káàkiri orí ayélujára tó fi mọ́ Youtube.

Ó ní ìjìyà wà fún lábẹ́ òfin àti pé ó yẹ kí Gani Adams kojú ìjìyà tó tọ́ lórí àwọn ẹ̀sùn ọ́hún.

Sunday Igboho ní yàtọ̀ sí owó ìtanràn tí òun ń bèèrè lọ́wọ́ Gani Adams, ó ní kó sọ ní gbangba pé òun kó àwọn ọ̀rọ̀ náà jẹ́ láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìbanilórúkọ jẹ́ lásán ni.