Èèyàn 123 pàdánú ẹ̀mí wọn nípasẹ̀ ààrùn kọ́lẹ́rà ní Zimbabwe ní oṣù mẹ́jọ

Orilẹ-ede Zimbabwe lo n gbiyanju lati dena itankale aarun apaniyan onigba-meji (kọ́lẹ́rà) ni awọn ilu ati abule rẹ nitori aisi omi mimu ati lilo to mọ gaara.

Kọlẹra to jẹ aarun to maa n mu ni ya igbẹ gbuuru ati eebi nigba kan naa lo maa n waye nipasẹ jijẹ ounjẹ tabi omi ti kokoro-arun kan to n jẹ “Vibrio cholerae”, to si lee tan kalẹ ni awọn ipo ati aaye idọti.

Aarun yii ni kii ṣe ajoji si orilẹ-ede naa nitori pe o le ni ẹgbẹrun mẹrin eeyan to padanu ẹmi wọn nipasẹ aarun ọun ni ọdun 2008-2009.

Oṣu keji odun yii ni aarun buruku naa tun yọju to si jẹ pe awọn bii ẹgbẹrun mẹfa ni ẹka to n mojuto eto ilera ni orilẹ-ede naa wi pe o ti lugbadi aarun naa nipari oṣu kẹwa ti awọn bii mẹtalelọgọfa si ti padanu ẹmi wọn.

Aarẹ Emmerson Mnangagwa lo ti ṣeleri ipese kọngadẹrọ jakejado orilẹ-ede naa ti wọn yoo maa lo ina “solar” lati ṣe agbara ni awọn ilu bii ẹgbẹrun marundinlogoji ti wọn ko ti ni omi mimu to mọ gaara.

Ni Harare to jẹ olu-ilu orilẹ-ede naa, awọn araalu le lọ fun ọsẹ tabi oṣu diẹ laisi ipese omi deede latọwọ ileeṣẹ to n pese omi nilu naa.

Ni awọn ilu ati ileto ti awọn alatako ti saba maa n jẹ adari, awọn alakoso ibẹ lo di ẹbi ru ijọba pe wọn ko pese awọn ohun elo ti yoo mu ki omi o di mimọ gaara, eyi lo si fara han ninu bii aarun kọlẹra ṣe maa n bẹẹlẹ loorekoore.

Bakan naa lawọn kan di ẹbi ru awọn ileeṣẹ to n dari awọn ẹgbin wọn si odo Chivero to jẹ olori odo to n pese omi ni Harare.