Gbogbo èrò ọkàn mi ní pé kí n wà ''tanker'' tó ń jóná wọ́ inú odò lọ- Ejiro Otarigho awakọ̀ Ọkọ̀ agbépo tí aráàlú ń kàn sáárá sí

Awakọ to wa ninu fidio to gbode nibi to ti wa ọkọ agbepo to n jona kuro nibi tawọn eeyan wa ti salaye fun BBC bi iṣẹlẹ naa ti ṣe waye.

Kaakiri oju opo ayelujara ni Naijiria, orukọ Ejiro Otarigho lawọn eeyan kan n mu bẹnu ti onikaluku si n ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi akin to yọ awọn eeyan kuro ninu ewu nla.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC, Ejiro ni oun dupẹ pe ewu nla yi re kọja lori oun ati awọn eeyan rẹ to wa ni ilu Agbarho, ijọba ibilẹ Ughelli ni ipinlẹ Delta.

Ejiro ni oun ko mọ ibi ti imisinaa ti wa ṣugbọn oun kan ṣa wa ọkọ naa titi to fi gunlẹ sibi ti ko ti le ṣakoba fawọn eeyan.

Agbegbe ibi ti ina ti ṣẹyọ, ero pọ biba nibẹ

Nigba ti BBC ribi kan si Ejiro lori ago rẹ, o sọ pe oun ṣẹṣẹ n dari bọ lati ibi isin idupẹ kan tawọn eeyan rẹ ladugbo Agbarho ṣeto nile ijọsin fun.

O ni pe; ''Ni nkan bi aago meje alẹ ni iṣẹlẹ yi waye lọjọ Kẹwaa, oṣu Kẹfa.

A ṣẹṣẹ ja epo tan ni aaye kan ta si fẹ maa lọ si ibomiran.

Ṣadede ni ọmọ ẹyin ọkọ mi figbe ta pe ina n yọ lẹyin ọkọ wa.

Mo ri ina naa ọkan mi si sọ fun mi pe adugbo ti eeyan pọ si ni ibi to ti ṣẹyọ yi.''

O tẹsiwaju pe oun sọ fun ọmọ naa ko bọ silẹ ti oun si bẹrẹ si ni wa ọkọ naa kuro lagbegbe ibi ti ina ti ṣẹyọ

''Mo wa ọkọ naa fun nkan bi iṣẹju mẹẹdogun ki n to ribi wa ọkọ naa gunlẹ.Gbogbo ero ọkan mi si ni pe ki n wa wọ inu odo tabi ibi ti omi ba wa''

Gẹgẹ bi ohun taa ri ninu awọn fọnran fidio loju opo ayelujara kaakiri, Ejiro wa ọkọ naa ṣugbọn ko ribi de inu odo ki ọkọ to gunlẹ amọ ibi to gunlẹ si jina si ibi tawọn eeyan wa.

Ninu ọkan lara awọn fidio taa ri, awọn eeyan rọ yika Ejiro ti wọn si gbe digba kuro nibi ewu ọkọ ọhun.

Niṣe lawọn eeyan kan n sọ labẹlẹ pe ''o ku oriire.alakitiyan ni awakọ yi bo ṣe wa ọkọ naa kuro laarin awọn eeyan''

O yẹ ki ijọba fimoore han si Ejiro,iwa akin lo wu

Ohun ti ọpọ ọmọ Naijiria n sọ ree loju opo ayelujara ti wọn si n ṣapejuwe Ejiro gẹgẹ bi akikanju eeyan.

Ni Twitter paapaa, orukọ Ejiro le tente ni ti awọn eeyan si n ṣe alabapin fidio bi o ṣe wa ọkọ agbepo to n jona naa kuro laarin ibi ti ero wa.

Bawọn kan ṣe n beere oju opo rẹ lawọn mii n sọ pe o yẹ ki ijọba ṣe idanimọ rẹ ki wọn si ṣe moriwu fun nitori bo ṣe yọ ọpọ ẹmi kuro ninu ewu.

Iṣẹlẹ yi jẹ nkan moriwu fun awọn eeyan pẹlu bi ọpọ ṣe maa n padanu ẹmi wọn ninu ijamba ina to niṣe pẹlu ọkọ agbepo to gbina.

Ni Naijiria, aimọye igba ni ẹmi ati dukia ti n ṣofo nidi ijamba ọkọ agbepo to gbina.

Ejiro kọ lo ni ọkọ agbepo naa ṣugbọn o ni oun to jẹ oun logun bayi ni pe oun ko padanu ẹmi oun.

''Iyawo mi ṣẹṣẹ bimọ laipẹ yi ni. Idupẹ ti mo lọ ṣe ni ile ijọsin ni pe mo wa laaye mo wa laaye ti mo si tun ribi ri iyawo mi layọ ati alaafia.Mo dupẹ pupọ fawọn eeyan to fiẹ han simi''