You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àjọ ECOWAS àti EU kéde àtìlẹ́yìn fún Naijiria lórí ọ̀rọ̀ tí Trump sọ, pè fún ìrànwọ́ láti kojú àwọn agbésùnmọ̀mí
Ajọ ECOWAS to n ri si eto ọrọaje lẹkun iwọ oorun Afirika ti sọ pe awọn agbesunmọmi to n ṣọṣẹ lẹkun ko fi ti ẹsin kankan ṣe.
Ajọ ECOWAS ni awọn ẹlẹsin musulumi atawọn ọmọlẹyin Kristi to fi mawọn ẹlẹsin mii lawọn agbesunmọmi n ṣeku pa lẹkun iwọ oorun ilẹ Afirika.
Ajọ naa sọrọ yii latari ọrọ ti Aarẹ Donald Trump sọ wi pe awọn agbesunmọmi n ṣeku pa awọn kristẹni ni Naijiria.
Fun idi eyi ni Trump fi kede pe Amẹrika yoo kogun ja awọn agbesunmọmi naa ti ijọba Naijiria ko ba le ṣẹgun wọn.
ECOWAS ni awọn alakatakiti ẹsin yii ko mọ ẹsin kan yatọ si omiran, bẹẹ ni wọn o fi ti ọjọ ori tabi ẹya kan ṣe pẹlu bi wọn ṣe n fẹmi awọn eeyan ṣofo.
''Ajọ ECOWAS n lo asiko yii lati pe akiyesi awọn alabaṣiṣẹpọ wa ati gbogbo agbaye si ọṣẹ tawọn agbesunmọmi n ṣe lawọn orilẹede to wa lẹkun iwọ oorun ilẹ Afirika to fi mọ Naijiria.
Iwadii ti fi han pe awọn agbesunmọmi maa n ṣọṣẹ lai fi ti ẹsin, ẹya kan tabi ti ọjọ ori ṣe.''
ECOWAS wa kepe ajọ iṣọkan agbaye UN atawọn lajọlajọ kaakiri agbaye lati ṣeranwọ fawọn orilẹede tawọn agbesunmọmi ti n ṣọṣẹ.
Ajọ naa tun koro oju sawọn ọrọ kan to n jade eyi to le jẹ ki eto abo lawọn orilẹede yii bajẹ si i.
A gbọ́dọ̀ fún Naijiria ní ọ̀wọ̀ ilẹ̀ olómìnira rẹ̀- EU
Ajọ European Union tun ti fidi ọwọ ti wọn ni fun orilẹede Naijiria mulẹ, ti wọn si yẹra fun ọrọ to n lọ kiri nipa ọrọ ti Aarẹ Trump sọ pẹlu ileri lati tunbọ se atilẹyin fun idagbasoke alaafia lorilẹede naa.
Aṣoju EU si orilẹede Naijiria ati ECOWAS, Gautier Mignot, lo sọ eyi lọjọ Isẹgun niluu Eko lasiko to n ṣe ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin News Agency of Nigeria, NAN, nibi to ti ṣalaye ipo ti ajọ naa wa lori ọrọ ti Aarẹ Donald Trump ti orilẹede Amẹrika sọ nipa Naijiria.
Mignot ni orilẹede Naijiria ati EU ti jọ wa tipẹ, ti EU ko si ni tẹti si ọrọ miiran ti orilẹede mii ba sọ sita nipa Naijiria.
"A duro ti orilẹede Naijiria – a duro ti awọn eeyan ti iṣẹlẹ ijamba sẹlẹ si, ti awọn alaṣẹ ijọba si n gbe igbesẹ lati da aabo bo awọn araalu.
"Awọn eeyan Naijiria ti n gbe papọ tipẹ lai ro ẹsin tabi ẹya.''
O tun fidi rẹ mulẹ pe EU bọwọ fun ominira orilẹede Naijiria ati iwe ofin to faye gba ẹsin ti araalu ba fẹ sẹ.
Gẹgẹ bii o ṣe sọ, EU setan lati pese iranlọwọ fun alaafia, ọrọ nipa eto aabo ati didasi ọrọ nipa aabo pẹlu awọn eeyan ti ọrọ ba kan.
Mignot ni EU ko ni dawọ atilẹyin fun Naijiria duro ati wi pe ajọ naa naa yoo maa lepa alaafia ati igbayegbadun araalu.
Mignot ni otitọ ni pe Naijiria n koju ọpọ ikọlu nipa ẹtọ ọmọniyan ati awọn iṣoro miiran.
"Nnkan to n waye yii ko dara, o si le waye ni orilẹede miiran, ṣugbọn ofin wa to da bobo ẹtọ ọmọniyan lorilẹede Naijiria.
"O wa lọwọ awọn alaṣẹ Naijiria ati awujọ lati wa ọna fun alaafia lati wa kaakiri agbegbe," o sọ.