You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
"Ó yẹ kí ọlọ́pàá ti mú Ero Arike báyìí lórí fídíò tó gbé jáde, àmọ́, agbófinró kìí fọwọ́ kan ọmọ ẹgbẹ́ APC"
Agbaọjẹ ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ Osun, Falilat Oyetunji, ẹni ti ọpọ mọ si Ero Arike, ni o ti n ita gbangba mọ awọn ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party nipinlẹ Osun, to si jẹ ko di mimọ pe oun ni ibọn, ti oun si le yin mọ ẹnikẹni to ba tafelefele wa ba.
Ero Arike sọ ọrọ yii ninu fọnran kan to tan kiri oju opo Facebook, to si tun fẹsun kan awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP pe wọn ko mọ pe oun ko ka iwe nigba ti wọn n gba ẹbun lọwọ oun.
Tibinu-tibinu ninu fọnran naa, Ero Arike ni oun ko ni faye gba ki eeyan kan tabuku oun, to si kilọ fun awọn ẹgbẹ oṣelu PDP lati jina si oun.
"O sọ pe n ko ka iwe, sibẹsibẹ o gba maalu meji ati apo elubọ lọwọ mi," o sọ ninu fidio naa.
"Ẹ ma sun mọ mi, ẹru rẹ ko ba mi rara. Ipo ti ẹ wa lonii, o ko ṣiṣẹ fun rara.
"Mo ni ibọn. Ko da, ni alẹ, ẹ ma gboro ibọn ni ori aja mi. Mo n lo lati da bobo ara mi. Mo n gbe kiri. Ti ẹnikẹni ba wa fun mi, ile ori oke ni mo n gbe, mow a yin fun ẹni naa lati oke, koda ma yin kiri gbogbo agbegbe, n ko ran ẹnikẹni."
Ṣaaju ni agbaọjẹ naa ṣekilọ fun ẹgbẹ oṣelu APC pe ki wọn ma yan apaniyan gẹgẹ bii oludije ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress fun eto idibo Gomina to n bọ ni ọdun 2026.
Lọdun to kọja, awọn fidio kan jade sori ayelujara, nibi ti Ẹrọ Arike ti n fi ẹsun kan Alaga ẹgbẹ PDP Osun, Ọnarebu Sunday Bisi.
Ninu fidio naa ni Ẹrọ Arike ti ṣalaye pe Alaga PDP ati Yeyeluwa, Modupeola Sanni, ṣeleri lati fun ọkọ oun ni ipo alaga ijọba ibilẹ Boripẹ, iyẹn lẹyin awọn iṣẹ nla-nla toun ti ṣe ni Iragbiji ati agbegbe rẹ.
O ni wọn fẹẹ fi ipo naa san ọkọ oun lẹsan iṣẹ idagbasoke ilu ti oun fi owo ara oun ṣe lagbegbe Iragbiji ni.
Ẹrọ Arike sọ pe ẹrọ loun n ta, ọkọ oun si jẹ eekan ninu oloṣelu Osun, nitori ẹ loun ṣe ni ki wọn gbe ipo naa fun un.
O ni ṣugbọn niṣe ni wọn gbe ipo naa fun ẹlomiran lẹyin gbogbo idaamu oun, eyi lo fa a ti iya naa fi n gbera yilẹ ninu fidio to ṣe.
Ko yẹ ki a ṣẹṣẹ ma ranṣẹ si agbofinro lori Ero Arike, wọn wo fidio naa – PDP
Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party nipinlẹ Osun ti ni ohun itiju gbaa ni ohun ti o tẹnu Falilat Oyetunji, ẹni ti ọpọ mọ si Ero Arike jade sita lori ayelujara.
Agbẹnusọ PDP Osu, Oladele Bamiji ni o dabi pe awọn agbofinro ki n fọwọ kan awọn eeyan kan nitori wọn jẹ ọmo ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress.
"O da bi pe eto oṣelu ti a n ṣe lorilẹede Naijiria bayii ni oṣelu pe to ba ti wa ni ẹgbẹ oṣelu APC, nnkan to ba wu ẹ lo le ṣe, ti o ko ba si ni APC ni o le ni iru anfanni bẹẹ.
"Ohun to yẹ ka ma sọ bayii ni pe obinirin yii ti wa lọdọ awọn agbofinro lati lọ wi tẹnu rẹ lori fidio to gbe sita lori ayelujara.
Bamiji ni iru aya wo ni Ero Arike ni lati sọ ohun to sọ sita pe oun ko ibọn si ile jẹ ohun iyalẹnu fun gan fun ara oun.
O tẹnumọ ileeṣẹ ọlọpaa ko le sọ pe awọn ko ti ri fidio ti Ero Arike gbe sita, ki wọn si kesi pe ko wa ṣalaye iru to wa lọwọ rẹ nitori ofin ko faye gba ki eeyan ni oun gbe ibọn sile rara.
A ti n wa Ero Arike- Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ni awọn ti ri fidio ti Ero Arike gbe sita lopin ọsẹ, ti wọn si ti n gbe igbesẹ lati fi ọwọ ofin mu arabinrin pe ko wa wi tẹnu rẹ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun, DSP Abiodun Ojelabi ni kete ti oun ri fidio naa ni oun pe akiyesi Kọmisana fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun, to si ti palaṣẹ pe ki wọn sawari Ero Arike lori ohun to sọ sita.
Ojelabi ni awọn n rọ araalu lati pesi iranlọwọ lori bi wọn ṣe le mu Ero Arike ni kiakia.
"Ọrọ ti ẹniyẹn sọ ki n ṣe sọrọ to yẹ ki eeyan ma sọ sita ṣugbọn o ti sọ, ti a si ti bẹrẹ iwadii wa lori bi a ṣe le mu, ti a si fẹ ki araalu ran wa lọwọ lori bi a ṣe le mu Ero Arike."