You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo àwọn nǹkan tó yẹ láti ṣe tí o bá fẹ́ máa lo ẹ̀rọ a-mú-oúnjẹ-gbóná
- Author, Nazanin Motamedi
- Role, BBC Persian
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Lóde òní, ọ̀kan lára àwọn ohun èèlò ilé táwọn obìnrin máa ń gbìyànjú láti ní ni ẹ̀rọ a-mú-oúnjẹ-gbóná (microwave).
Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí ìrọ̀rùn tí ẹ̀rọ yìí máa ń mú wá nígbà tí èèyàn bá fẹ́ tún oúnjẹ gbé kaná láì ṣẹ̀ṣẹ̀ máa dáná sí ààrò.
Àmọ́ gbígbé oúnjẹ sínú ẹ̀rọ a-mú-oúnjẹ-gbóná (microwave) ní àwọn ipa kan tó máa ń ní lórí ìlera èèyàn pàápàá látara àwọn oúnjẹ tí èèyàn ń gbé sínú ẹ̀rọ yìí.
Àwọn ọ̀nà tí èèyàn lè gbà dá ààbò bo ara ẹni lọ́wọ́ àwọn àìsàn tó lè ti ìdí àwọn oúnjẹ náà jáde.
Àwọn nǹkan tí o kò gbọdọ̀ ṣe
- Má fi oúnjẹ sínú ẹ̀rọ a-mú-oúnjẹ-gbóná fún ìgbà pípẹ́
Má jẹ̀ ẹ́ kí oúnjẹ máa pẹ́ nínú ẹ̀rọ a-mú-oúnjẹ-gbóná ju bí ó ṣe yẹ lọ pàápàá ìrẹsì. Ìrẹsì ní kòkòrò àìfojúrí kan tó ń jẹ́ bacillus cereus tó le pọ̀ si nígbà tó bá pẹ́ nínú ẹ̀rọ a-mú-oúnjẹ-gbóná.
- Má gbè é ìrẹsì tí o bá rà níta sínú ẹ̀rọ a-mú-oúnjẹ-gbóná
Lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn ilé ìtajà tó ń ta oúnjẹ síse máa ń gbé oúnjẹ sínú ẹ̀rọ a-mú-oúnjẹ-gbóná kí wọ́n tó gbe fún oníbàárà wọn. Tí èèyàn bá ń tún àwọn oúnjẹ náà gbé sí inú ẹ̀rọ a-mú-oúnjẹ-gbóná le dákún kí oúnjẹ náà léwu ní jíjẹ.
- Má gbè é oúnjẹ sínú ẹ̀rọ a-mú-oúnjẹ-tutù (refrigerator) fún ìgbà pípẹ́
Ó dára láti jẹ oúnjẹ tí èèyàn bá sè láàárín ọjọ́ kan sí ọjọ́ méjì. Tí o bà le parí oúnjẹ láàárín ọjọ́ kan sí ọjọ́ méjì, ó dára láti gbe sínú ẹ̀rọ a-mú-oúnjẹ-dì (freezer) dípò ẹ̀rọ a-mú-oúnjẹ-tutù (refrigerator).
- Má gbè é ẹran adìyẹ sínú omi gbígbóná tí o bá dì
Gbígbé ẹran adìyẹ tí ó bá dì sínú omi gbígbóná nígbà tí ẹ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbe jáde nínú ẹ̀rọ a-mú-oúnjẹ-dì (freezer) láti le fi jẹ́ kó rọ̀ le mú kí kòkòrò àìfojúrí Campylobacter tó máa ń fa inú rírùn àti èébì wọ inú rẹ̀.
Àwọn ohun tó yẹ láti ṣe
- Ri dájú láti gbé oúnjẹ sínú ẹ̀rọ a-mú-oúnjẹ-tutù kí o tó gbé sínú ẹ̀rọ a-mú-oúnjẹ-gbóná
Ìwádìí fi hàn pé gbígbé oúnjẹ sínú fíríìjì máa ń dènà kí àwọn kòkòrò àìfojúrí le hù níbẹ̀.
- Dènà gbígbé oúnjẹ gbígbóná sínú fíríìjì
Gbígbé oúnjẹ tọ bá gbóná gidi sínú fíríìjì le mú kí fíríìjì náà gbóná èyí ló sì lè ṣàkóbá fáwọn oúnjẹ mìíràn tó bá wà nínú rẹ̀.
Jẹ́ kí oúnjẹ máa tutu kí o tó gbe sínú fíríìjì.
- Jẹ́ kí oúnjẹ tó dì túká kí o tó gbe sínú ẹ̀rọ a-mú-oúnjẹ-gbóná
Ohun tó dára jùlọ ni pé kí èèyàn ri dájú pé oúnjẹ tó bá dì tutu dáadáa kí èèyàn tó gbé sínú ẹ̀rọ a-mú-oúnjẹ-gbóná.
- Ri pé ó jẹ oúnjẹ tí ẹ bá ti gbé sínú ẹ̀rọ a-mú-oúnjẹ-gbóná láàárín ọjọ́ kan
- Mọ irú àwọn nǹkan tó yẹ láti ṣe nígbà tí ó bá ń lo ẹ̀rọ a-mú-oúnjẹ-gbóná láti fi ṣe oúnjẹ fáwọn tí ìlera wọn ń ṣòjòjò.
- Ri dájú pé oúnjẹ tí ò ń gbé gbóná nínú ẹ̀rọ a-mú-oúnjẹ-gbóná gbóná dáadáa.