You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
A fẹ́ àlàyé lórí owó Abacha tẹ fẹ́ gbà lọ́wọ́ Amẹ́ríkà - SERAP
Àjọ SERAP ti kọ̀wé ránṣẹ́ sí Ààrẹ Muhammadu Buhari lórí owó tuntun tí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà fẹ́ dá padà fún Nàìjíríà lára àwọn owó tí Abacha jíkó.
Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni ìjọba Amẹ́ríkà tọwọ́ bọ àdéhùn pẹ̀lú ìjọba Nàìjíríà láti dá mílíọ̀nù mẹ́tàlélógún dọ́là tó jẹ́ lára owó tí ọ̀gágun Sani Abacha jíkó nígbà tó wá nípò Ààrẹ padà fún orílẹ̀ èdè yìí.
Nínú ìwé àkọránṣẹ́ tí SERAP kọ sí Ààrẹ Muhammadu Buhari lọ́jọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Kẹjọ ọdún 2022 rọ Ààrẹ Buhari láti darí Mínísítà fétò ìdájọ́, Abubakar Malami láti fi ẹ̀dà àdéhùn náà léde fún gbogbo ọmọ Nàìjíríuà láti rí.
Wọ́n ní lábẹ́ ìwé òfin Nàìjíríà ti tọdún 1999 àti àwọn òfin mìíràn, ó pọ́n dandan fún ìjọba láti ṣe àgbéjáde gbogbo ìwé àdéhùn tí ìjoba tọwọ́ bọ̀ lórí pwó náà.
Wọ́n ní èyí yóò fún àwọn ọmọ Nàìjíríà láti ṣe àgbéyẹ̀wò àdéhùn náà fínífíní, kí wọ́n sì sẹ àmójútó bí ìjọba yóò ṣe náà owó náà.
SERAP ní èyí máa fún àwọn ọmọ Nàìjíríà ní àǹfàní láti mọ bí owó náà yóò ṣe jẹ́ níná, tí yóò sì tún dín ìwà olè gbe, olè gbà á kú àti gbígbé owó náà gba oko ibòmíràn lọ.
Wọ́n ní ó ṣeéṣe kí owó kí owó náà má wúlò bó ṣe tọ́ tí ìjọba kò bá mójúto dada nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n ti ń gbà látẹ̀yìnwá náà ni kò sí àǹfàní kan gbòógi tí wọ́n fi ṣe fún àwọn ará ìlú.
Bákan náà ni wọ́n fún ìjọba ní ọjọ́ méje péré láti ṣe èyí bíbẹ́ẹ̀kọ́ àwọn yóò gba ilé ẹjọ́ láti fi òfin kàn-án nípá fún ìjọba láti gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ lórí owó náà.
Wọ́n fi kun pé owó tí ìjọba Nàìjíríà ti rígbà padà gẹ́gẹ́ bí owó tí Abacha jókó lọ sílẹ̀ òkèrè ni owó rẹ̀ ti tó bílíọ̀nù márùn-ún dọ́là láti ọdún 1999 sí àsìkò yìí láìsí kókó kan láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀.
SERAP ní mílíọ̀nù mẹ́tàlélógún dọ́là tuntun tí Amẹ́ríkà fẹ́ dá padà fún Nàìjíríà báyìí ni yóò jẹ́ ọ̀tàlélọ́ọ̀dúnrún mílíọ̀nù dọ́là tí Amẹ́ríkà nìkan dá padà fún Nàìjíríà lára owó tí Abacha jíkó.
‘’Ìjọba Naijiria fẹ́ jí owó Abacha tí wọ́n dápadà ní, kò sí isẹ́ àkànṣẹ tí wọ́n fẹ́ fi ṣe’’
Onimọ nipa eto ọrọ aje lorilẹede Naijiria, Bisi Iyaniwura ti ni ole ni ijọba Naijiria fẹ ja pẹlu owo ti Abacha lu ni ponpo ti ijọba ilẹ Amerika fẹ da pada fun Naijiria.
Iyaniwura ni ko si otitọ ninu ọrọ ti olootu eto idajọ sọ pe awọn fẹ ki pari oju ọna marosẹ Ibadan si Eko ati ori afaras Niger Bridge.
O ni ijọba Naijiria ti sọ tẹlẹ pe ọwọ alajẹṣẹju Naijiria ti wọn pe ni Nigeria Sovereign wealth ni wọn ti fẹ mu owo ti wọn fẹ fi ṣe oju ọna naa ati afara Niger Bridge, ti wọn yoo si san owo ele rẹ pada.
Bakan naa lo ni wọn ti sọ pe awọn to ba n gba oju ọna naa ti wọn yoo ma san owo ni wọn yoo fi da owo naa pada.
Onimọ nipa eto ọrọ aje naa ni igba akọkọ kọ niyii ti wọn n sọ pe awọn n fi owo ṣe oju ọna naa, ti ko si pari ni ati ọjọ yii.
Bisi Iyaniwura ni o ṣeeṣe ko jẹ pe nitori ati ko awọn owo yii jẹ ni wọn ko fi pari awọn ọna naa lati ọjọ yii, jegudujẹra ni wọn fẹ fi ṣe.
‘’Ọmọ ti a ko kọ ni oun gbe ile ti a kọ ta’’
Onimọ nipa eto ọrọ aje naa ni owo naa lo yẹ ki ijọba ti san owo awọn olukọ fasiti ti wọn ti gunle iyanṣelodi fun bi oṣu meje bayii.
O ni ti ijọba ba ṣe ọna, ti awọn akẹkọọ to jẹ ọjọ ọla Naijiria n fi ẹṣẹ gbalẹ kiri, awọn naa ni yoo di ole, agbebọn ti yoo ma fọ ile ti ijọba kọ ati gbogbo ohun ti wọn ro pe wọn ṣe.
‘’Bawo ni yahoo-yahoo ko sẹ ni pọ nita nigba ti awọn to ba yẹ ki wọn wa ni ile iwe ko si nibẹ.'
Ero awọn ọmọ Naijiria ṣe ọtọọtọ lori nkan ti ijọba gbọdọ fi owo Abacha naa ṣe
Ero awọn ọmọ Naijiria ṣe ọtọọtọ lori ohun to yẹ ki ijọba se peẹlu owo Abacha ti orilẹede Amerika da pada
Ninu ọrọ ti Bachir Ahmad kọ si Twitter, o ni ijọba ni awọn fẹ fi ṣe awọn oju ọna marosẹ to fi mọ ori afara Niger.
Amọ awọn ọmọ Naijiria kan ni o yẹ ki ijẹba mu lara owo naa fi san owo awọn oṣiṣẹ fasiti to da iṣẹ silẹ lati bi osu mẹfa sẹyin.
Wọn fikun un pè ọrọ eto ẹkọ ko jọ ijọba loju ni wọn fi gbe igbeṣẹ naa.
Kini Bisi Onimo tun sọ?
Onimọ nipa eto ọrọ aje lorilẹede Naijiria, Bisi Iyaniwura ni pe: ‘’Bakan naa ni awọn to yẹ ki wọn maa kẹkọọ ni ile iwe n ṣe agbowo ode, onijagidijagan nitori wọn ko ri nkan ṣe’’
Imọ ẹkọ ṣe pataki o ṣe koko, kii sẹ ohun ti o yẹ ki ijọba fi ọwọ yẹpẹrẹ mu nitori ọjọ ọla wọn ni wọn n bajẹ.
‘’Ki wọn ma gbagbe owe Yoruba to ni ọmọ ti a ko kọ lo n gbe ile ti a kọ ta’’
Nitori naa kii ijọba Naijiria fi owo ti wọn ri gba pada san owo awọn oṣiṣẹ to n yan iṣẹ lodi ati titun awọn ile ẹkọ ṣe kaakiri orilẹede Naijiria, ki ọjọ ọla le dara.
Amọ awọn miran ni adehun ti ijọba ṣe pẹlu orilẹede Amerika lo mu ki wọn gbe igbesẹ lati fi ṣe iṣẹ akanṣe lai bikita eto ẹkọ.
Miliọnu mẹtalelogun dọla ni owo ti Abacha lu ni ponpo ti wọn fẹ da pada.
Orílẹ̀-èdè Amerika yóò dá $23 million tí Abacha lù ní póńpó padà
Orilẹede Amẹrika ti sọ wi pe awọn yoo da iye owo to to miliọnu mẹtalelogun dola pada si orilẹede Naijiria.
Iye owo yii ti adari ijọba ologun ni Niajiria tẹlẹri, Sani Abacha jigbe nigba to wa ni ipo.
O ti ṣe diẹ ṣẹyin ti ijọba Naijiria ti n beere fun owo naa ti Abacha ji ko lọ si oke okun.
Ọdun 1993 si ọdun 1998 ti Abacha fi wa ni ipo ni Ajọ Transparency International wi pe Abacha ji biliọnu marun un dola ninu apo owo ijọba Naijiria.
Amọ ko si ẹnikẹni to fi ẹsun naa kan an ni ileẹjọ.
Bawo ni ijọba Naijiria yoo ṣe na owo ti wọn rigba pada yii?
Aṣoju orilẹede Naijiria, Mary Beth Leonard ni iye owo yii ni wọn ri ni apo ifiowopamọ si ni ilẹ okeere amọ ti awọn alaṣẹ orilẹede Amerika fi ofin de e.
Bakan naa lo fikun un pe yato si owo eleyii, o ṣi ni ọọdunrun miliọnu dọla ti wọn yoo da pada fun orilẹede Niajiria.
Ninu ọrọ rẹ, Olootu eto idajọ ni Naijiria, Abubakar Malami ni owo ti wọn ri gba pada naa ni wọn yoo fi sẹ atunṣe opopona Abuja si Kano, Eko si Ibadan ati afara keji ni agbegbe Niger.
Ninu ọrọ rẹ, o ni aarẹ Buhari ti paṣẹ fun oun pe oun gbọdọ ri pe awọn owo ti wọn da pada lati oke okun di lilo fun awọn iṣẹ akanṣe awọn araalu.
Bakan naa ni ijọba orilẹede Amerika ati ti Naijiria ti buwolu iwe adehun pe wọn gbọdọ lọ awọn owo ti wọn ba ri gba pada fun iṣẹ akanṣe awọn araalu.