You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Omíyalé pa èèyàn 1,033
Orilẹede Pakistan ti n beere fun iranwọ latọdọ awọn orilẹede agbaye lati koju ajalu ẹkun omi to n ba a finra.
Ajalu Ẹkun omi ti sọ ọpọ eeyan di alarinkiri lorilẹede Pakistan nibi ti wọn ti n wa ilẹ to gbẹ lati tẹdo si.
Ẹgbẹrun kan ati mẹtalelọgbọn eeyan lo ti ku nipasẹ ẹkun omi naa, mọkandinlọgọfa ninu wọn ni ẹkun omi ti ran lọ sọrun laarun wakati mẹrinlelogun bayii, gẹgẹbi ajọ to n ṣamojuto iṣẹlẹ pajawiri lorilẹede naa ṣe sọ.
Awọn orilẹede bii Amẹrika, UK ati United Arab Emirates ti gbọn ọwọ sinu awo fun orilẹede Pakistan, ṣugbọn owo ti wọn nilo ṣi pọ diẹ ni awọn alakoso nibẹ n sọ.
Arakunrin kan tilẹ ṣalaye fun BBC pe ẹkun omi odo kan ti gbe ọmọ oun obinrin lọ.
“O sọ fun mi pe: Baba mi mo fẹ lọ ja ewe fun ewurẹ mi. O lọ si eti odo, ọwọ omi si gbe e lọ”
Ọrọ ti Muhammad Fareed, to n gbe lagbegbe Keghan Valley ni ariwa Khyber Pakhtunkhwa sọ niyi.
Awọn igbesẹ ti ijọba ti n gbe lorilẹede naa
Oṣiṣẹ ileeṣẹ ọrọ abẹle nijọba orilẹede Pakistan, Salman Sufi tun fi to BBC leti pe ijọba orilẹede naa nilo iranwọ awujọ agbaye gidigid ni.
“Ipenija ọrọ aje n ba orilẹede Pakistan finra ṣugbọn lasiko yii ti a n gbero ati ja ajabọ lọwọ ipenija yii niajalu ẹkun omi yii tun waye.”
Gẹgẹbi Salman Sufi ṣe sọ, Ọpọlọpọ iṣuna fun oniruuru iṣẹ idagbasoke gbogbo lorilẹede naa ni wọn ti doju wọn kọ awọn eeyan ti n doju kọ iṣoro ẹkun omi nibẹ.
Gẹgẹbi iroyin ti Iwe iroyin abẹle kan lorilẹede naa, Dawn Newspapaper ṣe sọ olotu ijọba orilẹede naa, Shebaz Sharif ti kede owona oni miliọnu marundinlaadọta dọla ($45Million) fun awọn ti ajalu ẹkun omi naa de ba lẹkun Khyber Pakhtunkhwa.
Olotu ijọba, Shebaz Sharif ni gbogbo idile to fara gba ninu ajalu ẹkun omi naa ni yoo gba owo iranwọ to to dọla mejilelaadọfa ($112) laarin ọsẹ kan.
Loju wa bayii ni ile wa ti n ri sinu omi ti a ko lee ṣe nnkankan - olugbe Pakistan
Ni agbegbe iwọ oorun ariwa orilẹede naa, ẹgbẹlẹgbẹ awọn olugbe agbegbe naa ni wọn ti sa fi ile wọn silẹ lẹyin ti awọn odo to wa ni Khyber Paktunkhwa kun akunfaya eyi to fa omiyale nibẹ.
“Ile ti a ti kọ pẹlu oogun pọlọpọ ọdun ri wọmi loju wa bayii ni”
Eyi lọrọ ti Junaid Khan, ẹni ọdun mẹtalelogun sọ fun ileeṣẹ akoroyinjọ AFP.
Oju popo bayii la joko si ti a n woran lai la ṣe ohunhun ti ile wa si n wo loju wa.”
Bakan naa ni omiyale naa tun kan agbegbe Sindh lapa ila oorun ariwa orilẹede naa eyi to si ti sọ ọpọ di alainilelori nibẹ.