Ẹnikẹ́ni tó bá ṣe ìpolongo ìdìbò ní ṣọ́ọ̀ṣì, mọ́ṣálásí yóò fi ẹ̀wọ̀n jura – Àjọ INEC

Ajọ to n risi eto idibo lorilẹede Naijiria, INEC ti ṣe ikilọ pe awọn oloṣelu to ba lọ ṣe ipolongo idibo ni ile ijọsin tabi mọsalasi yoo fi ẹwọn jura.

Eyi n waye lasiko ti ipolongo idibo fun idibo gbogboogbo yoo bẹrẹ ni Ọjọ Kẹjidinlọgbọn, Oṣu Kẹsan an, ọdun 2022.

Ajọ INEC ni pupọ ninu iṣe awọn oloṣelu lasiko ipolongo idibo lo tako ofin orilẹede Naijiria.

Kọmiṣọnna ati Alaga INEC nipa eto ilanilọye fun awọn oludibo lorilẹede Naijiria, Arakunrin Festus Okoye salaye fun ileeṣẹ iroyin Punch ohun ti awọn oloṣelu ko gbọdọ ṣe lasiko idibo.

O ni gbogbo alakalẹ ofin ati ijiya to wa fun ẹni to ba tako wa ni ‘’Section 92 of the Electoral Act, 2022’’, ti iwe ofin orilẹede Naijiria.

Lara awọn eewo ipolongo idibo lorilẹede Niajiria re e...

  • Oloṣelu ko gbọdọ lo awọn ileeṣẹ ijọba ati ibi ti awọn eniyan gbogbo nlo lati fi ṣe ipolongo idibo
  • Wọn ko gbọdọ lo eegun lati fi dapara lasiko ipolongo idibo
  • Wọn ko gbọdọ ṣe ipolongo fun ẹgbẹ oṣelu wọn ni ile ijọsin tabi mọsalasi
  • Awọn oloṣelu ko gbọdọ fa rogbodiyan tabi sọ ọrọ kugbakugbẹ si ara wọn lasiko ipolongo idibo
  • Ọlọṣelu kankan ko gbọdọ lọ awọn ọmọ ita tabi awọn onijagidijagan lati dunkoko mọ awọn ẹgbẹ oṣelu miran lasiko ipolongo idibo
  • Oloṣelu ko gbọdọ ya awọn eruuku tabi elto aabo adani lati da ipaya silẹ fun awọn eniyan lasiko ipolongo idibo ni Naijiria ( eleyii wa ni ṣection 6, iwe ofin Electoral Act, 2022.)

Fifi ẹwọn jura ni ijiya fun awọn to ba rufin

Ajọ INEC tun salaye ijiya to wa fun ẹnikẹni to ba ru awọn ofin wọnyii labẹ ofin to de eto idibo lorilẹede Naijiria

INEC ni gbigbe ofin ro gbọdọ jẹ awọn oloṣelu logun lasiko idibo ni Naijiria.

  • Labẹ iwe ofin Section 92 of the Electoral Act, 2022,, ẹnikẹni to ba rufin naa ṣeeṣe ki o fi ẹwọn ọdun kan jura tabi ki o san owo itanran to to miliọnu kan naira si miliọnu meji naira
  • Ẹnikẹni to ba ṣe atilẹyin fun awọn oloṣelu to rufin wọnyii yoo fi ẹwọn ọdun mẹta jura tabi ki o san owo itanran to to N500,000.