You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo àwọn ọmọ Nàìjíríà àtàwọn ọmọ ilẹ̀ Afirika míì tó lè gba àmì ẹyẹ́ ni ìdíje 2024 Paralympics
Ayẹyẹ iside idije Paralympics bẹrẹ lalẹ oni Ọjọru, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ti apapọ ami ẹyẹ ti yoo wa fun gbigba si jẹ 549 ninu ere idaraya mejilelogun.
Ilẹ Afrika gba mẹtalelọgọta ni idije Paralympics to waye ni ọdun mẹta sẹyin.
Ọpọ aṣeyọri ti ilẹ Afrika se lo wa lati ibi ere sisa, gbigbe irin ati awọn ere idaraya mii lori paapa.
Afrika gba ami ẹyẹ Goolu ni bi ere idaraya kẹkẹ gigun, judo, ere bọọlu, bọọlu ẹlẹyin ati taekwondo.
Awọn orilẹ-ede Afirika mẹwa Ako fi elere idaraya kankan ranṣẹ fun idije naa, ti awọn mẹsan an miiran si parapọ lati ni aṣoju kan ṣoṣo.
Orilẹede Eritrea jẹ ọkan lara awọn orilẹede tuntun ti yoo kopa ninu idije ti ọdun yii.
Orile-ede Egypt yoo ma kopa ninu ere idaraya bọọlu afẹsẹgba ati bọọlu Volly Ball, yoo ni awọn elere idaraya 54 ni idije naa, nigba ti Morocco, South Africa, Tunisia ati Algeria gbogbo ni awọn ẹgbẹ ti o ju 25 lọ.
Afirika ko ni awọn oludije eyikeyi ni ibon yiyan, fifo iganna, bọọlu inu apẹẹrẹ lori kẹkẹ kẹkẹ tabi rugby.
BBC Sport Africa se akojọpọ awọn orukọ ti ọpọ le fojusọna fun ninu idije naa ti yoo waye niluu Paris.
Thomas Kure(Nigeria)
Ọkunrin kan ṣoṣo ti o wa ninu ẹgbẹ agbara to n gbe irin lorilẹ-ede rẹ ni awọn ere idaraya, Kure le nilo lati tẹ pa mọṣẹ lasti le de ibi to fẹ de
Ẹni ọdun 35 gba ami-ẹyẹ baba ni idije Agbaye ti ere idaraya ni Dubai ni ọdun to kọja.
Kure n kọwọ rin pẹlu tomo ilu Bose Omolayo ati Folashade Oluwafemiayo ti n gbeja oyè Paralympic wọn ni ilu Paris, se Kure le pada si ilu Eko pẹlu ami ẹyẹ?
Tọkọtaya Christiana ati Kayode Alabi(Nigeria)
Aṣiwaju ni Kayode ati Christiana Alabi ni isọri ti wọn wa ninu ere idaraya tẹniisi ori tabili ni ilẹ Afirika.
Christiana gba amí ẹyẹ fadaka ninu idije Commonwealth Games lọdun 2022 nigba ti ọkọ rẹ gba goolu meji ninu idije African Para Championship lọdun to lọ.
Kayode ati Christiana ti mura si igbaradi wọn lati le gbami ẹyẹ ninu idije 2024 Paralympics niluu Paris.
Lẹyin igbaradi ti wọn n ṣe pẹlu awọn akẹgbẹ wọn, tọkọtaya yii tun maa n wo fidio igbaradi wọn nile lati le mọ ibi ti wọn ku si.
Christiana sọ pe "afojusun mi lati goke, lati mu iyi wa fun ẹbi mi ati orilẹede Naijiria ati ọkọ mi ẹni to ti n gbaradi pẹlu mi."
Wakati meji ni wọn maa fi n gbaradi ni aarọ.
Lẹyin ti wọn ba ni isinmi lọsan an, wọn yoo tun pada sibi igbaradi wọn ni irọlẹ.
Gbogbo akitiyan wọn da lori ati gba ami ẹyẹ ninu idije Paralympics to n bọ.
Noemi Alphonse(Mauritius)
Elere sisa kẹkẹ fun awọn akanda ni o jẹ ẹni ọdun mejidinlọgbọn, fi itan lalẹ nibi idije awọn akanda ẹda to waye ninu oṣu karun un, to si gba ami ẹyẹ goolu akọkọ fun orilẹeede Maurtius .
Bakan naa lo gba ami ẹyẹ fadaka nibi ere sisa pẹlu awọn obinrin ni ididje 200m.
Ohun to kan bayii ni kikipa nibi idije Paralymipics akọkọ , ko si tun gba ami ẹyẹ akọkọ fun orilẹede rẹ.
O sumọ lati gba ami ẹyẹ ni idije Tokyo to kọja sugbọn ipo karun un lo gbe.
Brahim Guendouz(Algeria)
Wiwa ọkọ oju omi ni eyin pẹlu erongba lati fi itan lelẹ
Guendouz di elere idaraya Para-akọkọ ti o n soju Algeria lati gba ami-ẹyẹ World Championship nigba ti o gbe ipo kẹta ni bi idije KL3 200m ni Germany ni ọdun to kọja.
Abajade yẹn lo fun orilẹede apa Ariwa Afirika ni anfani lati kopa Ilu Paris ati pe o tungba ami ẹyẹ elere idaraya to da ju ni orilẹede Algeria
Ẹni ọdun mẹdọgbọn 25 ti n ṣe igbaradi ni orilẹede Spain lọdun yii, to si n gbaradi fun idije Paralympics rẹ akọkọ.
Husanh Kukundakwe(Uganda)
Ni ọdun mẹta sẹyin, oun lo jẹ oludije ti o kere julọ ni Tokyo, ti o jẹ ọmọ ọdun mẹrinla ati ọjọ 154 nikan, itumo Kukundakwe yoo kopa ninu idije Paralympics rẹ keji ṣaaju ki o to dagba.
O pari pẹlu ipo kejila ni idije to waye ni Japan ṣugbọn o ni ilọsiwaju lati bọ si ipo keje ni idije Agbaye ti ọdun to kọja ni Ilu Manchester.
Uganda gba ami-eye kan ni Tokyo, sugbọn wọn si n duro de ami ẹyẹ goolu rẹ akọkọ.
Raoua Tlili(Tunisia)
Ẹni ọdun 34 naa jẹ ọkan elere idaraya lo ti fi itan balẹ pe o jẹ eeyan o gba ami ẹyẹ goolu julọ lorilẹede rẹ ni idije Paralympics.
O bori ere idaraya meji ni Rio de Janeiro ati Tokyo.
Koda, ẹnikẹni ko fidi Tlili janlẹ lati igba akọkọ rẹ ninu ere idaraya Paralympic ni Ilu Beijing ni ọdun 2008