You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àdúà ọjọ́ mẹ́jọ Olúbàdàn Lekan Balogun tó wàjà yóò wáyé lónìí ọjọ́ Ẹtì
Gbogbo eto lo ti to bayii fun adua ọjọ mẹjọ (Fidau) ti yoo waye lonii ọjọ Ẹti, ọjọ kejilelogun oṣu kẹta ọdun 2024 yii, ni iranti Olubadan Ọba Lekan Balogun to waja lọsẹ to kọja.
Amugbalẹgbẹẹ Olubadan ana naa, Ọladele Ogunṣọla, lo sọ eyi di mimọ.
O ni gbọngan Mapo, niluu Ibadan ni eto adua naa yoo ti waye.
Awọn eeyan lati origun kaakiri ni wọn si n reti nibẹ.
Ẹka iroyin BBC Yoruba yoo maa mu ẹkunrẹrẹ iṣẹlẹ naa wa bo ba ṣe lọ.