You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Obasanjo tàbùkù àwọn Ọba Yorùbá, ó gbọdọ̀ tọrọ àforíjìn - Afenifere
Ẹgbẹ Afenifere ilẹ Yoruba ti koro oju sí aarẹ Naijiria tẹlẹ ri, Oloye olusegun Obasanjo lori ihuwasi rẹ s'awọn Ori-ade ipinlẹ Oyo.
Fidio to ṣafihan bi Obasanjo ṣe peṣẹ fawọn ọba alaye naa pe ki wọn dide kí wọn sí tun joko lasiko ti gomina Seyi Makinde de si ibi eto ti wọn wa di iṣu ata yan-an yan-an papaa julọ lori ayelujara.
Ninu atẹjade to fi sita lẹyin ipade rẹ ni Ọjọru niluu Akure, Afenifere sọ pe Obasanjo gbọdọ tọrọ aforijin lọwọ awọn Ori-ade tọrọ kan.
Afenifere sọ ninu atẹjade ti akọwe ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Jare Àjàyí ka sita pe "iyalẹnu ni iṣẹlẹ to waye lọjọ kẹẹdogun oṣu kẹsan an niluu Iseyin jẹ nibi ti Obasanjo paṣẹ fawọn ọba alaye to sí tun sọ fún wọn pe ki wọn jokoo pada.
Niṣe lo dàbí ẹni pe ọgagun kan lo n peṣẹ fawọn ọmọ ogún.
Awa Yoruba bọwọ fun àṣà wa at'awọn to jẹ aṣoju aṣa wa bakan naa eleyii tii ṣe awọn ọba alaye.
Ati wipe kii ṣe lásán ni Yoruba maa n pe awọn ọba ni igbakeji oriṣa.
Idi eyi ni àwa ẹgbẹ Afenifere fi kepe aarẹ Naijiria tẹlẹ lati tọrọ aforijin lọwọ awọn ọba alaye yii.
A ko gbọdọ faye gba ẹnikẹni lati takubu aṣa ati iṣe wa nilẹ Yoruba.
Eyi gan an l'awọn Ọba ko ṣe maa dide lawujọ lati ki ẹnikẹni gẹgẹ bi o ṣe wa ni ilẹ Gẹẹsi ati káàkiri agbaye."
Ẹwẹ, Afenifere tun kepe ijọba apapọ lori eto abo to mẹhẹ lorilẹ ede Naijiria.
Ẹgbẹ naa ni ijọba gbọdọ ri pe eto abo mulẹ, ati pe ijọba gbọdọ wa iṣẹ fawọn ọdọ tori ọwọ to ba dilẹ ni Esu maa n bẹ niṣẹ k'iṣẹ.
Afenifere ni ijọba gbọdọ ri pe awọn agbesunmọmi, janduku at'awọn to n ti wọn lẹyin gbọdọ foju wina ofin.