Ṣé lóòótọ́ ni àwọn òṣìṣẹ́ NNPC ní iléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń fọ epo lókè òkun? Ohun táa mọ̀ rèé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọpọ ariwo lo ti jẹyọ lati igba ti ede aiyede ti n waye laarin Aliko Dangote, alaga ileeṣẹ Dangote Industries Limited ati ileeṣẹ to n ri si eporọbi lorilẹede Naijiria, NNPC.

Fakinfa naa ko ṣẹyin ọrọ epo bẹntiro to di ọwọngogo ni Naijiria ati akitiyan ileeṣẹ Dangote lati bẹrẹ si n ta epo naa laipẹ yii.

Ṣaaju ni Dangote ti sọ pe ileeṣẹ oun yoo bẹrẹ si n ta epo ko to di idaji ọdun 2024 amọ erongba rẹ ko bọ si.

Oniruru ipenija ni Dangote koju lọna ati ṣaṣeyọri lati bẹrẹ si n ta epo naa, lara rẹ ni bo ṣe sun ọjọ ti yoo bẹrẹ si ni ta epo siwaju ati bi ijamba ina kan se sọ nileeṣẹ naa

Dangote ti wa fẹsun kan awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to n ri si epo rọbi lorilẹede Naijiria, NNPC, pe wọn ni ileeṣẹ to n fọ epo, to tun n se atunse si eporọbi fun lilo.

Dangote sọ eyi nigba to gba alejo olori ile igbimọ aṣofin kekere lorilẹede Naijiria, Tajudeen Abbas ati igbekeji rẹ pẹlu awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin mii.

O ni epo ti ileeṣẹ Dangote n pese jẹ ojulowo ju eyi ti awọn ontaja n ko wọle lati oke okun.

O tẹsiwaju pe eporọbi ti wọn n ko wọle n se ọpọ akoba fun awọn ọkọ ayọkẹlẹ lorilẹede Naijiria.

"Mo duro le nnkan ti mo sọ . Ẹ lọ si awọn ile-epo, ẹ lọ se ayẹwo epo wọn. Ọna abayọ kan soso nìyẹn. "

“Awọn oṣiṣẹ NNPC ati awọn ontaja kan ti ṣi ileeṣẹ silẹ ni orile-ede Malta.

“A mọ gbogbo ibi to wa. A mọ nnkan ti wọn n se.” Dangote tẹnubọrọ.

Dangote tun tẹsiwaju pe ọrọ kan ti awọn eeyan kan sọ pe oun jẹ gaba le ọpọ nnkan lo jẹ irọ to jina si otitọ.

“Ti ẹ ba wo nnkan ti a n se ni ileeṣẹ Dangote, a n fi apọnle kun nnkan, a lọ gbe awọn nnkan yii, sọ wọn di ohun to wulo, ti a si ta wọn sita.

“A ko fi igba kankan da ẹnikẹni duro pe ki wọn se irufẹ okowo ti a n se.”

Darukọ awọn oṣiṣẹ NNPC to ni ileeṣẹ epo ni Malta, Ọga NNPC fesi fun Dangote

Ọga agba fun ileeṣẹ NNPC, Mele Kyari ti pariwo sita pe oun ko ni ileeṣẹ kankan to n fọ eporọbi fun lilo ni orilẹede Malta.

Kyari fikun pe oun ko mọ oṣiṣẹ kankan ni ileeṣẹ NNPC to ni ileeṣẹ afọpo aladani ni ilẹ Yuroopu.

Eyi jade ninu atẹjade kan ti Kyari fi sita lori opo ayelujara X rẹ, to si n rọ Aliko Dangote pe ko kede orukọ awọn eeyan yii fun araye lati mọ.

“Ọpọ ipe ni mo ti gba lọwọ mọlẹbi, ọrẹ ati awọn eeyan to mọ mi lori ẹsun ti ọga agba ileeṣẹ Dangote fi kan awọn osisẹ NNPC pe wọn ni ileeṣẹ afọpo aladani ni Malta, to si n fa idiwọ fun pipese epo ni orilẹede Naijiria.

“Lori ẹsun ti Dangote fi kan awọn oṣiṣẹ NNPC, n ko ni ileeṣẹ kankan ni ibikibi lagbaye. Bakan naa ni n ko mọ awọn oṣiṣẹ NNPC to ni ileeṣẹ afọpo aladani ni Malta tabi ni ibikibi.

“Fun idaniloju, a o gbe igbesẹ lati bẹrẹ iwadii, oṣiṣẹ NNPC ti iwadii ba fihan pe o ni ileeṣẹ afọpo aladani ni Malta, mo n gba lero pe ki wọn da orukọ rẹ, ki wọn si fa le awọn agbofinro lọwọ.”

O se koko ki orilẹede Naijiria se atilẹyin fun Dangote - Otedola

Gbajumọ oniṣowo, Femi Otedola ti kesi ijọba apapọ pe ki wọn se atilẹyin fun oniṣowo to jẹ omo orilẹede Naijiria bi ti Aliko Dangote.

Nigba to n da si ọrọ naa, Otedola ṣapejuwe Dangote gẹgẹ bii eeyan ti Ọlọrun da lati mu irọrun wa nitori o ti rin jina pupọ ninu okowo lagbaye.

“Ni Naijiria, a ni awọn eeyan ti wa, o se koko ka da wọn mọ, ki a si se atilẹyin fun wọn.

“Gbigba ruku ti eeyan bi Dangote lo se koko fun idagbasoke orilẹede ati ọrọ aje wa.

“Ẹ jẹ ka tẹsiwaju lati ma pese atilẹyin fun eeyan ni ero ọjọ ọla rere fun idagbasoke orilẹede Naijiria.

Ta ni Aliko Dangote

Ọmọ Naijiria lati iha ariwa ni Dangote, o si jẹ oniṣowo to gbajumọ kaakiri agbaye.

Ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun 1957 ni wọn bi ni ipinlẹ Kano.

Dangote ni ọpọlọpọ ileeṣẹ to n ta nnkan jijẹ ati nnkan ikọle bii spaghetti, ṣuga, simẹnti, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Yatọ si pe o jẹ oniṣowo, Dangote tun jẹ oloju aanu to maa n fi owo rẹ ran awọn alaini lọwọ.

Ọkunrin ọhun jẹ ọkan lara awọn ọmọ ilẹ adulawọ to lowo julọ lagbaye.