Ọkọ dáná sun ìyàwó àti ọmọ nítorí owó oúnjẹ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Níṣe ni ọ̀rọ̀ di a! a! lẹ́nu àwọn ará ìlú Asa Umudioka ní ìjọba ìbílẹ̀ Osisioma Ngwa, ìpínlẹ̀ Abia nígbà tí ọkùnrin kan dáná sun ìyàwó àti ọmọ rẹ̀, ọmọ ọdún kan mọ́lé ní òru mọ́jú.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú wọn ṣe sọ, òru tí gbogbo èèyàn ti sùn ni ọkùnrin náà da epo bẹntiróòlù sílé wọn, tó sì dáná si, ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ sì wà nínú ilé.

Wọ́n ní ọkùnrin náà, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ugochukwu àmọ́ tí wọ́n máa ń pè é ní Ude Papa, jẹ́ ẹni tó máa ṣe bàtà ní ọjà Ariaria ní Aba.

Wọ́n ṣàlàyé pé ọmọ bíbí ìlú Umuogbala ni àmọ́ tó fi Umudioka ṣe ibùgbé, òun pẹ̀lú ìyàwó àti ọmọ.

Nígbà tí akọ̀ròyìn BBC News Igbo kàn sí ìlú tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, àwọn ará àdúgbò sọ pé nígbà tí Ugochukwu dé láti ṣọ́ọ̀bù rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ló ti ń kanran, tó sì ń bínú pé ìyàwó òun wá dójú ti òun ní ṣọ́ọ̀bù òun.

Wọ́n ní ó ń sọ̀ pé ìyàwó òun wá bèèrè owó oúnjẹ lọ́wọ́ òun ní ṣọ́ọ̀bù, tó sì fi dá ìdójútì kalẹ̀ fún òun.

Àwọn ará àdúgbò náà ní ìgbà tó di òru ni Ugochukwu da epo bẹntiróòlù sínú yàrá tí ìyàwó àti ọmọ sùn, tó sì dáná sun wọ́n.

Iná náà gba ẹ̀mí ìyá àti ọmọ náà.

Wọ́n ní ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí Ugochukwu ti gbìyànjú láti gbẹ̀mí lọ́rùn ìyàwọ rẹ̀ àmọ́ tí àwọn máa ń gbìyànjú láti báwọn dá sí aáwọ̀ wọn.

Wọ́n ní àwọn ti mú obìnrin náà lọ sílé wọn padà nígbà kan rí àmọ́ Ugochukwu lọ mu padà wá.

Ọkùnrin kan sọ fún BBC pé Ugochukwu sọ fáwọn pé ìdí tí òun àti ìyàwó òun fi máa ń ní gbólóhùn asọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà ni pé ó máa ń fi fóònù rẹ̀ pé àwọn èèyàn tí òun kò mọ̀.

Ìròyìn ní Ugochukwu náà pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì àmọ́ ohun tó ṣokùnfà ikú rẹ̀ kò ye ẹnikẹ́ni.

Àwọn ará ìlú náà sọ pé àdánù ńlá ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́, tó sì jẹ́ ìbànújẹ́ fáwọn nítorí àjòjì ni ìyàwó Ugochukwu nínú ìlú náà.

Wọ́n ní ọmọ ìlú Umuahia, olú ìlú ìpínlẹ̀ Abia ni ọmọbìnrin náà.

Nígbà tí BBC News Igbo kàn sí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Abia, Maureen Chinaka Desmond, ó sọ pé ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.