Kà nípa àìsàn tó lè pa ọmọ ìkókó

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọlọkan-o-jọkan arun lo le kọlu ọmọ ikoko, ṣugbọn awọn kan wa ti wọn le fa iku ọmọ lai pẹ rara.

Awọn aisan miran wa ti ko ni I pa ọmọ ikoko, ṣugbọn ko ni I jẹ ki wọn dagba, rin tabi sọrọ.

Iru rẹ ni ti ọmọkunrin kan, Babatunde Fashola, ẹni ọdun mejilelogun (22) ti ko ga ju ẹsẹ bata meji lọ.

Aisan kan ti wọn n pe ni 'neonatal influenza' la gbọ pe o n ṣe e.

Babatunde Fashola ko le rin, ko le sọrọ bẹẹ ni ko le da jẹun, afi bi wọn ba gba inu nnkan elo ta a mọ si 'tube', fun un lounjẹ jẹ.

Olutọju rẹ, Nonye Nweke, ṣalaye fun BBC pe lati igba to ti wa ni ikoko ni awọn obi rẹ gan-an ti ta a nu.

Ẹka to n ri si itọju awọn ọmọde lo si ti pada ba ara rẹ ni nnkan bii ọdun mẹwaa sẹyin, lọsibitu ijọba ipinlẹ Eko.

Ninu ile to ti n tọju awọn ọmọ to ni iṣoro yii, Arabinrin Nweke ati awọn oṣiṣẹ rẹ, ṣalaye pe ọpọlọ awọn ọmọde naa ni aisan n da laamu.

Gẹgẹ bi ofin, eeyan gbọdọ tọju aisan neonatal jaundice yii laaarin ọjọ mẹwaa.

Bi ko ba si itọju to peye ti ọjọ mẹwaa fi pe, o le fa ijamba ayeraye fun ọpọlọ ọmọ naa.

Ọjọgbọn Chinyere Ezeaka, Dokita awọn ọmọde nileewosan ẹkọṣẹ iṣegun oyinbo, nipinlẹ Eko, lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.

'Ọmọ ti wọn ni ko ni i lò ju ọdún méji láyé ti di ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún báyìí'

Nigba to n tẹsiwaju, Arabinrin Nweke toun naa ni ọmọbinrin kan ti ẹya ara pe nija, ṣalaye pe itọju ṣe pataki fun awọn ọmọ bẹẹ.

"Nigba ti mo gbe ọmọ mi de ile itọju, wọn ni ki i n gbe e pada, nitori bawọn obi miran ba ri i, wọn maa mu ọmọ wọn kuro ni.

"Wọn ni ki n lọọ gba ọmọ mi-in nile ọmọ alailobi ti mo ti gba ọmọ mi, Zimuzo.

"Dokita kan tilẹ sọ fun mi pe Zimuzo ko le lo ju ọdun meji lọ ti yoo fi jade laye, ṣugbọn oun ree bayii, o ti pe ẹni ọdun mẹtadinlogun (17), ko si ku.

Ki lohun to n ṣe ọmọ naa gan-an?

Nweke sọ pe oun ko mọ pe arun to n daamu ọpọlọ ọmọ ati idagbasoke rẹ, 'autism', lo n ṣe Zimuzo nigba toun gba a wale.

O sọ fun BBC pe nigba ti ko dagba bo ṣe yẹ kọmọ dagba loun gbe e lọ sileewosan, ibẹ ni wọn si ti sọ pe autism lo n da a laamu.

Iranlọwọ ti awọn ajọ bii The Oscar Project Foundation, bẹrẹ l'Ekoo, wa lara ohun to n ro awọn ile itọju awọn akanda ọmọ naa lagbara gẹgẹ bo ṣe sọ.

Akiyesi ọmọ nigba ti eeyan ba ṣẹṣẹ bi i ṣe pataki, bi nnkan ko ba si ri bo ṣe yẹ lara ọmọ ikoko, kawọn obi rẹ tete gba ileewosan lọ lo yẹ .