Kò ṣeé má gbọ̀ọ́

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ajijagbara fun ominira ilẹ Yoruba, Sunday Igboho tun ti gbe ijọba apapọ ati ajọ DSS lọ sile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria

Lẹyin ti wọn kuna lati san owo gba mabinu to yẹ ki wọn san fun lori dukia rẹ ti wọn bajẹ

Ọdun 2021 ni DSS kọlu ile Igboho niluu Ibadan, nibi ti wọn ti ba ọpọ dukia jẹ, ti ẹmi si sọnu

Ajọ EFCC, ti kede orukọ ileeṣẹ mejidinlọgọta ti araalu ko gbọdọ ba dowopọ

EFCC ni awọn ileeṣẹ naa yoo tan awọn eeyan pe ki wọn wa dowopọ pẹlu wọn pẹlu owo perete lọna ati gba ere gọbọi lẹyin akoko diẹ

Wọn ni ẹnikẹni to ba dowopọ pẹlu awọn ileeṣẹ naa yoo jẹ ika abamọ ni ikẹyin

Orukọ awọn ileeṣẹ ọhun wa loju opo wa

Senetọ Natasha Akpoti-Uguaghan ti wọn da duro nile igbimọ aṣofin agba l'Abuja

Ti gbe ẹjọ naa lọ si ọdọ ajọ isọkan agbaye niluu New York

Aṣofin naa, to n ṣoju Aarin-gbungbun ipinlẹ Kogi ni ẹtọ awọn obinrin loun n ja fun

Ati pe idaduro oun nile aṣofin ko ba ofin mu