Wo àwọn ìpínlẹ̀ ti àwọn òṣìṣẹ́ tí bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì lónìí

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede ti bẹrẹ iyansẹlodi ni awọn ipinlẹ ti wọn kọ lati kede sisan owo oṣu tuntun fun awọn oṣiṣẹ, eyi to jẹ N70,000.

Saaju ni ẹgbẹ oṣiṣẹ kede pe awọn uoo bẹrẹ iyanṣẹlodi ni awọn ipinlẹ to ba kọ lati kede sisan owo oṣu ni ni ọjọ kinni oṣu kejila ọdun 2024.

Ipinlẹ mẹrinla ni ko ti kede pe oun yoo san owo oṣu tuntun naa.

Ni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu keje ọdun 2024, Aarẹ Bola Tinubu kede pe oun ti buwọlu sisan owo oṣu tuntun fun awọn oṣiṣẹ, to si ṣe ileri pe atunṣe yoo ma de ba owo oṣu oṣiṣẹ laarin ọdun mẹta.

Iroyin to tẹ wa lọwọ fidi rẹ mulẹ pe ipinlẹ marun un ni ko ti ma san owo oṣu tuntun ti wọn si ti bẹrẹ iyansẹlodi, awọn ipinlẹ naa ni, Ipinlẹ Kaduna, Nasarawa, Zamfara, Ebonyi ati olu ilu Abuja.

Awọn ipinlẹ mẹsan an yooku ni ko ti bẹrẹ iyanṣẹlodi, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe awọn ti bẹrẹ ijiroro pẹlu ijọba ipinlẹ kowa wọn.

Iroyin to tẹ BBC lọwó ṣafihan pe iyanṣẹlodi ni awọn ipinlẹ kan lo ti ni ipa ti ko da , ti ijọba si ti bẹrẹ si ni wa ojutu si iyanṣẹlodi naa

Awọn ipinlẹ ti ko ti ma san owo oṣu tuntun

Bo ti lẹ jẹ pe ọpọ lo ti kede awọn yoo san owo oṣu tuntun naa, ọpọ wọn ni ko ti ma san owo naa rara.

Lati oṣu kẹwaa ti ipinlẹ Katsina ti kede pe oun yoo san owo oṣu tuntun, Gomina Radda kede pe oṣu kejila ni awọn yoo bẹrẹ si ni ma san.

Baka naa nipinlẹ Nasarawa, ijọba o ti sọ igba to ma bẹrẹ sini san owo oṣu naa.

Ẹgbẹ oṣisẹ nipinlẹ Kaduna ni ijọba ti bẹrẹ sini san owo naa ṣugbọn ki ṣe iye ti awọn ni adehun le lori ni wọn san.

“A ni adehun pẹlu ijọba ṣiugbọn wọn yii adehun pada.

‘Wọn ti bẹrẹ sini san owo naa ṣiugbọn ki i se iye ti aj ọ ṣe adehun lo lori ni wọn n san.

Awọn ipinlẹ ti wọn ti bẹrẹ sini san owo oṣu tuntun naa ni ipinlẹ Abia, Akwa Ibom, Ebonyi, Ekiti, Imo, Nasarawa, Kaduna, Katsina, Oyo, Cross River, Sokoto, Yobe , Zamfara, Enugu ati olu ilu Abuja.