You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo iye owó tí epo rọ̀bì tó wà nínú ọ̀kọ̀ ojú omi agbépo lítà 800,000 epo tó
Laipẹ yii ni ọwo awọn ọmọogun ikọ amuṣẹya JTF Operation Delta Safe pẹlu ileeṣẹ aladani kan tẹ ọkọ ojuomi agbepo naa pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin (800,000) lita epo rọbi to ji ko.
Ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin (800,000) lita epo rọbi ọhun lo to milọnu mẹtale-lẹwaa-lelọọdun owo naira.
Iwadi BBC fihan pe iye owo ọhun yoo kọ ile wosan alabode mẹta, ti owo ọkọọkan rẹ yoo jẹ aadọta milọnu naira.
Bakan naa ni yoo kọ yara ikẹkọọ mẹrindinlaadọrin pẹlu miliọnu marundinlogun naira.
Saaju ni iroyin gbe e pe ipinlẹ Ondo ni awọn ajigunjale naa ti ji epo naa wa ti wọn ko si ni iwe aṣẹ kankan lasiko ti wọn mu wọn.
Bakan naa ni wọn fi kun un pe ọkọ oju omi naa ti wa lẹnu iṣẹ lati nnkan bi ọdun mejila sẹyin.
Ìjọba dáná sun ọkọ̀ ojú omi agbépo tó jí epo rọ̀bì lítà 800,000 gbé
Awon agbofinro ti dana sun ọkọ ojuomi agbepo ti wọn ka mọ pẹlu epo robi to ji lagbegbe Escravos ni ipinlẹ Delta.
Baluu hẹlikọputa ologun kan ni wọn fi dana sun ọkọ oju omi agbepo naa.
Owo awọn ọmọogun ikọ amuṣẹya JTF Operation Delta Safe pẹlu ileeṣẹ aladani kan tẹ ọkọ ojuomi agbepo naa pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin (800,000) lita epo rọbi to ji ko.
Awọn ologun ni ileeṣẹ kan lorilẹede Naijiria lo ni ọkọ oju omi naa ati pe orilẹede Cameroun ni wọn n gbe wpo ti wọn ji wa naa sa lọ.
Wọn ni ipinlẹ Ondo ni wọn ti ji epo naa wati wọn ko si ni iwe aṣẹ kankan lasiko ti wọn mu wọn.
Bakan naa ni wọn fi kun un pe ọkọ oju omi naa ti wa lẹnu iṣẹ lati nnkan bi ọdun mejila sẹyin.
Ọkọ̀ ojú omi táa gbámú ti n jí epo rọ̀bì láti ọdún méjìlá sẹ́yìn-NNPCL
Ile iṣẹ to n risi ọrọ epo rọbi ni Naijiria, NNPC Ltd ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ ọkọ oju omi awọn oni fayawọ epo rọbi to ji epo lati Naijiria lọ si Cameroon.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, ọkọ oju omi yi gbe epo rọbi lita 800,000 ti wọn pọn lọna eru lati ipinlẹ Ondo ti wọn si fẹ lọ ta ni orileede Cameroon.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita lọjọ Aje, NNPC Ltd sọ pe ileeṣẹ Holab Maritime Services Ltd lo ni ọkọ oju omi naa ti wọn pe orukọ rẹ ni MT- TURA II.
Wọn ṣalaye pe lati nkan bi ọdun mejila ni wọn ti n fi ọkọ oju omi yi ṣiṣẹ ni bonkẹlẹ lalaẹ jẹ ki awọn alaṣẹ mọ.
NNPC Ltd wa sọ pe lati le jẹ ki eleyi jẹ ikilọ fawọn mii to n ji epo rọbi gbe awọn yoo dana sun ọkọ naa ni.
NNPC Ltd sọ pe ''Didana sun ọkọ ọju omi to ji epo rọbi gbe jẹ ọna kan gboogi lati kilọ fawọn to n hu iru iwa bayii.''
Wọn ko sọ boya wọn yoo dana sun ọkọ naa pẹlu epo ninu tabi wọn yoo gbe epo inu rẹ kuro ṣaaju.
Ọrọ awọn to n ji epo rọbi ni Naijiria jẹ eleyi to n kan awọn onwoye lominu.
Ẹka epo rọbi jẹ eleyi ti epo taa si aṣọ aala rẹ nitori kudiẹ kudiẹ to n waye nibi ka ma ji epo rọbi gbe.
Lọdun 2022, ijọba kede pe awọn n padanu nkan to le ni barẹli epo 470,000 lojumọ kọọkan sọwọ awọn alaburuyi.
Ni oṣu Kẹjọ ọdun 2022 ni iye epo rọbi ti Naijiria n pọn dẹnukọle debi pe ko to miliọnu barẹẹli kan lojumọ ti wọn pọn jade.
Iye yi lo kere julọ ni epo rọbi ti wọn n pọn lati nkan bi ọgbọn ọdun sẹyin.
Ninu iwadii wọn, NNPCLtd sọ pe awọn ṣawari ayederu oju opo ipọnpo mẹrinlelọgọta.
Bẹẹ ni wọn lawọn dana sun ibudo ipọnpo mẹtadinlọgọrin lagbegbe Niger Delta laarin ọsẹ to kọja.
Ijọba aarẹ tuntun Bola Tinubu ti ṣe ileri lati koju awọn ajẹlojuolohun to n mu ki Naijiria padanu obitibiti owo nipa jiji epo rọbi ilẹ ọhun.