You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn igun tó ń jà ní Sudan ti gbà láti sinmi ogun fún ọjọ́ Méje -Amẹ́ríkà
Ifẹnuko awon igun to n jagun lorilẹede Sudan lati dawọ aawọ to n waye nibẹ duro naa fun igba diẹ ti wọ ọsẹ kẹfa bayii.
Ọpọ awọn igbesẹ ipẹtusaawọ laarin ileeṣẹ ọmọ ogun ati ikọ ajagun ti kii ṣe ologun, Rapid Support Force (RSF) ṣaaju eyi lo ti foriṣanpọn laarin iṣẹju ranpẹ.
Gẹgẹ bi atẹjade kan ti orilẹede Amẹrika ati Saudi Arabia fi sita, “eto amojuto ipẹtusaawọ” kan ti wọn gbe kalẹ lo jẹ ki eyi jẹsẹjari.
Gẹgẹ bi ara aaye ọjọ meje ti wọn gbe kalẹ lati fi ṣe eto itọju fun awon eeyan ti ogun naa ti sọ di alarinkiri, awọn alaṣẹ orilẹede Sudan gba lati da awọn ohun amayedẹrun to ṣe pataki pada.
Aawọ laarin awọn igun mejeeji yii ti ko wahala ba orilẹede Sudan lati igba ti wọn ti bẹrẹ rẹ ni oṣu to kọja to si ti sọ nnkan bii miliọnu kan eeyan di alarinkiri lorilẹede ọhun.
Ounjẹ, owo ati awọn ohun pataki miran ti n dinku, bẹẹ ni gbogbo awọn ikọ aṣeranwọ gbogbo to wa nibẹ ti n ke gbajare pe o n nira fun awọn lati pese iranwọ fun awọn eeyan ni ilu Khartoum, tiiṣe olu ilu Sudan nibi ti rogbodiyan to n waye naa sodo si julọ.
Wọn parọwa si awọn ọmọ-ogun at’awọn ikọ RSF lati fi aaye gba awọn ọmọ ikọ aṣeranwọ lati pin awọn ohun arẹmọlẹkun kaakiri, ki wọn si da awọn ohun elo amayedẹrun pada ki wọn si ko awọn ologun wọn kuro lawọn ile iwosan nibẹ.
Orilẹede Amẹrika ati Saudi Arabia to ṣe agbatẹru ijiroro ipẹtusaawọ ọhun ni ilu Jeddah sọ pe eto naa yoo fidi mulẹ bẹrẹ lati irọlẹ ọjọ Aje.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọrọ ilẹ okeere ni Amẹrika tọka si, awọn ijakulẹ to ti waye pẹlu ṣiṣe eto alaafia ni Sudan, o ni iyatọ to ṣe koko wa ninu ti ọtẹ yii.
Ilu Jeddah ni wọn ti fẹnuko lori adehun alaafia yii, orilẹede Amẹrika ati Saudi Arabia lo ṣe agbatẹru rẹ pẹlu ifọwọsowọpọ awọn orilẹede agbaye.
Minisita fun ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Amẹrika, Antony Blinken sọ pe: “Asiko to lati sinmi iro ibọn ki awọn ikọ arẹmọlẹkun lee ri aaye de ibi gbogbo to yẹ.''
“Mo rọ igun mejeeji lati jẹ olotitọ si adehun yii- gbogbo agbaye lo n wo wọn.”
Ọjọ karundinlogun oṣu kẹrin ni ogun bẹ silẹ ni Khartoum lẹyin ọpọ ọjọ ti ikayasoke ti wa pẹlu bi wọn ṣe pin awọn ọmọ ogun ikọ RSF kaakiri orilẹede naa.
Bakan naa ni aawọ olori pẹlu n waye laarin olori ileeṣẹ ọmọ ogun orilẹede Sudan, Abdel Fattah al-Burhan ati igbakeji rẹ tẹlẹ, Mohamed Hamdan Daglo, to jẹ adari ikọ RSF bayii.
Ọpọ eeyan lo ti ku sinu ogun yii, bẹẹ si ni ajọ iṣọkan agbaye pẹlu n ṣe ikilọ pe ṣe lọrọ naa n buru sii nibẹ.
O ti pe ọsẹ meji bayii ti awọn aṣoju igun mejeeji kọkọ peju si olu ilu Saudi Arabia fun ijiroro alaafia.
Ni ọjọ kọkanla oṣu karun un ni igun mejeeji tọwọ bọ iwe adehun alaafia eyi ti ireti wa pe yoo to ipilẹ fun iranwoọ eto arẹmọ lẹkun ni Sudan.
Amoṣa, ṣaaju lọsẹ to kọja, adari eto arẹmọlẹkun labẹ ajọ iṣọkan agbaye, UN, Ọgbẹni Martin Griffiths sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe awọn kan ti tapa si adehun naa.
Iroyin sọ pe ina wahala ṣi n ru lorilẹede Sudan, pẹlu awọn ikọlu kan to waye lọjọ Satide ni gusu Omdurman ati ariwa Bahri, awọn ilu meji to sun mọ Khartoum ṣugbọn to fara kan odo nla Nile.
Awọn olugbe ilu Omdurman kan ṣalaye pe nṣe ni ile awọn n mi ni owurọ ọjọ Satide nitori awọn nnkan ogun to n dun lakọlakọ laarin awọn igun naa.
“ Ṣe ni jinijini bo mi, gbogbo wa la sapamọ si abẹ ibusun wa”
Alaye yii ni Sanaa Hassan ẹni ọdun mẹtalelọgbọn to jẹ olugbe agbegbe al-Salha fi to ileeṣẹ iroyin Reuters leti lori ẹrọ ibanisọrọ.