Òfin tó de ọ̀kadà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rin mìí ní Eko

Ofin to de lilọ-bibọ ọkada eero ni ijọba ibilẹ mẹrin miran nipinlẹ Eko, ti bẹrẹ iṣẹ lọjọ kinni, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2022.

Oṣu Kẹjọ ni Ijọba ipinlẹ Eko kede pe oun yoo fẹ ofin naa loju de ijọba ibilẹ mẹrin ati awọn ijọba agbegbe mẹfa to wa labẹ wọn.

Awọn ijọba ibilẹ naa ni Kosofe (Ikosi-Isheri ati Agboyi-Ketu LCDA); Mushin (Odi-Olowo LCDA); Oshodi (Oshodi-Isolo ati Egigbo LCDA), ati Shomolu (Bariga LCDA).

Oṣu Keji, ọdun 2022 ni ijọba kọkọ fi ofin de lilọ-bibọ ọkada eero ni ijọba ibilẹ mẹfa ati ijọba ibilẹ agbegbe mẹsan-an.

Ijọba sọ pe igbesẹ naa jẹ ọna lati mu adinku ba ijamba oju popo ati awọn iwa ipanle miran lawujọ to wọpọ si aarin awọn ọlọkada.

Ijọba sọ pe laarin ọdun 2016 si 2019, ko din ni ẹgbẹrun mẹwaa ijamba ojupopo to waye, pupọ ninu wọn si lo niṣe pẹlu ọkada.

Gomina Babajide Sanwo-Olu sọ pe ijamba naa si ti dinku pupọ lati igba ti wọn ti gbe ofin naa jade.

'Ọmọ marun-un ni mo n fi iṣẹ ọkada bọ́'

BBC Yoruba dé agbegbe Onipanu labẹ ijoba ibile Shomolu lati ri bi ofin náà ṣe múlẹ.

Ọkan lára àwọn olokada ni ofin náà bawọn lojiji. O tun ṣàlàyé siwaju pe ọlọmọ marun ùn loun to sì jẹ pe iṣẹ ọkada yii lo fi n bọ wọn.

Wọn rọ ijọba ipinlẹ eko lati wa nkan ṣe sí òfin to gbẹsẹle igbokegbodo alupupu ọkada ni ipinlẹ naa

Lati Ọjọru si ni awọn oṣiṣẹ alaabo ti wa ni igboro lati fi ẹsẹ ofin naa mulẹ.

Ẹwẹ, kọmisanna fun eto irinna nipinlẹ Eko, Frederick Oladeinde, sọ pe ẹwọn ọdun mẹta ni ọlọkada ti ọwọ ba tẹ yoo fi jura.

O ni idajọ ẹwọn naa wa ni ibamu pẹlu atunṣe ti wọn ṣe si ofin irinna nipinlẹ Eko lọdun 2018.