You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Osimhen, Ndidi kò níí kópa fún Naijiria nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìgbáradì fún ife ẹ̀yẹ àgbáyé lóṣù yí
Ikọ agbabọọlu Super Eagles ti ilẹ Naijiria ni atamatase wọn, Victor Osimhen, ati aramanda agbabọọlu ikọ Leicester City, Wilfred Ndidi, ko nii lee ba kopa ninu idije komẹṣeoyọ tako orilẹ-ede Zimbabwe ati Lesotho fun ife ẹyẹ agbaye ti ọdun 2026.
Awọn ti yoo ṣoju ikọ Super Eagles ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ ti oṣu kọkanla ni ajọ NFF fi orukọ wọn lede ni Ọjọbọ ọsẹ yi.
Agbabọọlu mẹtalelogun ni orukọ wọn wa ninu iwe ifilede naa ni bi ikọ ọun ṣe n gbaradi lati le wa lara awọn orilẹ-ede to yoo ṣoju gbogbo ilẹ adulawọ nibi idije ọun ti yoo waye nilẹ Amẹrika, Mexico ati Canada.
Osimhen ni ko nii lee kopa nitori ifarapa to ni nibi ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹ-sọrẹ to waye laarin Naijiria ati Saudi Arabia.
Bakan naa ni ohun to nii ṣe pẹlu ifarapa ko nii jẹ ki Ndidi naa lee kopa ninu awọn ifẹsẹwọnasẹ ọhun.
Samuel Chukwueze to n tayo fun ikọ agbabọọlu AC Milan naa ni orukọ rẹ ko tun si nibẹ amọ ti Francis Uzoho, aṣọle tawọn eeyan ko fi bẹẹ gba tiẹ lẹnu ọjọ mẹta yii, wa nibẹ.
Orilẹ-ede Naijiria to ti gba ife ẹyẹ ilẹ Africa lẹẹmẹta ọtọọtọ ni yoo waako pẹlu Lesotho lọjọ kẹrindinlogun oṣu yii nilu Uyo, ko too di pe wọn yoo naa tan bi owo pẹlu Zimbabwe ni ọjọ kọkandinlogun oṣu yi kan naa.
Ipin ‘C’ ni Naijiria wa nibi idije komẹsẹoyọ naa pẹlu South Africa, Rwanda, Benin, Zimbabwe ati Lesotho.
Àwọn wo ni NFF fi ìwe pe?
Aṣọle: Francis Uzoho (Omonia FC, Cyprus); Olorunleke Ojo (Enyimba FC); Maduka Okoye (Udinese Calcio, Italy)
Awọn agbabọọlu lọwọ ẹyin: Olaoluwa Aina (Nottingham Forest, England); Chidozie Awaziem (Boavista FC, Portugal); Bright Osayi- Samuel (Fenerbahce FC, Turkey); Bruno Onyemaechi (Boavista FC, Portugal); Kenneth Omeruo (Kasimpasa FC, Turkey); Oluwasemilogo Ajayi (West Bromwich Albion, England); Calvin Bassey (Fulham FC, England); Jamilu Collins (Cardiff FC, Wales)
Awọn agbabọọlu lọwọ aaringbungbun: Raphael Onyedika (Club Brugge, Belgium); Joe Ayodele-Aribo (Southampton FC, England); Frank Onyeka (Brentford FC, England); Alex Iwobi (Fulham FC, England)
Awọn agbabọọlu lọwọ iwaju: Kelechi Iheanacho (Leicester City, England); Sadiq Umar (Real Sociedad, Spain); Moses Simon (FC Nantes, France); Ademola Lookman (Atalanta FC, Italy); Nathan Tella (Bayer Leverkusen, Germany); Taiwo Awoniyi (Nottingham Forest, England); Terem Moffi (OGC Nice, France); Victor Boniface (Bayer Leverkusen, Germany)