Ọ̀pọ̀ dúkìá ṣòfò níbi ìjàmbá iná tó ṣẹlẹ̀ nílùú Ilorin

Ijamba ina to ṣẹlẹ niluu Ilorin ni ipinlẹ Kwara ti sọ awọn eeyan kan di alainile lori tan ti ọpọ dukia si tun ṣofo.

Lowurọ kutu ni Iṣẹlẹ jamba ina ọhun ṣẹlẹ nibi ti ilegbe oni yara mẹfa ti deeru.

Iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni agbegbe Aduramigba phase one Akeribiata, Ilọrin, ipinlẹ Kwara.

Lasiko ti asoju kọroyin ile isẹ wa BBC Yoruba sabẹwo si ibi iṣẹlẹ na, ṣe ni awọn kafinta tu ajoku paanu ile to jona naa.

Ẹni to ni ile naa, Ọgbẹni Saka Jimọn to ba BBC sọrọ sọ pe ibi isẹ loun wa ti wọn fi pe oun pe ile oun jona lọwọ.

Amọ, kawọn panapana to de, gbogbo ile ti jona tan, o ṣalaye pe gbogbo dukia oun lo jona pata.

O fikun un pe oun o ri nnkan kan mu jade ninu ile naa, ati pe asọ toun ''wọ jade lana nikan naa ni o ku lọrun oun.''

Bakan naa ni o sọ pe aṣọ ile ẹkọ nikan lo wa lọrun awọn ọmọ oun.

Lasiko ti asoju kọroyin ile isẹ wa n fi ọrọ wa ọga agba ile isẹ panapana ipinlẹ Kwara lẹnu wo, Ọmọba Falade John ni wọn pe awọn lori ẹrọ ibanisọrọ tawọn si lọ pa ina naa.

O fikun un pe Iṣẹlẹ ina (NEPA) ti ko duro 're lo ṣokunfa Iṣẹlẹ ijamba ina naa.

O gba ara ilu ni imọran lati maa pa gbogbo ohun to ba n lo ina ki wọn to kuro ni ile laarọ.

O ṣalaye siwaju si pe bi ki ba se pe ile isẹ panapana tete de, ibi iṣẹlẹ naa ni iba kọsisọ nitori ọpọ ile lo wa lẹgbẹ ile to jona ọhun ti ina ọhun le ran mọ.