Ṣé lóòótọ́ ni èèyàn méjì ti lùgbàdì ààrùn Ebola ní Naijiria? Àlàyé rèé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ aarun lorilẹede Naijiria, NCDC, ti kede pe eeyan meji ti wọn fura si pe wọn ti lugbadi aarun Ebola ko ni aarun naa.

Ọga agba ajọ naa, Jide Idris, fidi rẹ mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita loju opo X ajọ NCDC wi pe, ayẹwo ti wọn ṣe fun awọn eeyan meji naa niluu Abuja fi han pe ko si Ebola lara wọn.

Ọga agba ajọ NCDC wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati wa ni ifura, ki wọn si mu eto ilera wọn lọkunkundun.

Ọgbẹni Idris sọ pe eeyan ti ajọ NCDC fura si kẹyin wi pe o ṣeeṣe ko ni aarun naa ni arinrinajo kan to de si ilu Abuja lati Kigali, orileẹede Rwanda.

O ni ẹni naa lọ si ile iwosan lati gba itọju lẹyin to ṣakiyesi pe ara oun ko ya daadaa.

Ọga agba NCDC ni gbogbo ayẹwo to yẹ ki wọn ṣe fun onitọhun nile iwosan ni wọn ti ṣe lati mọ bo ya o ni aarun Ebola lara.

Ọgbẹni Idris sọ pe ẹka eto ilera lorilẹede Naijiria ti wa ni imurasilẹ lati igba ti iroyin ti jade wi pe, Ebola tun ti ṣẹyọ lorilẹede DR Congo ati awọn orilẹede ilẹ Afirika mii.

Ọga agba NCDC ṣalaye pe ijọba ti ṣeto fun ayẹwo awọn arinrin-ajo to n de si Naijiria lawọn papakọ ofurufu ti wọn n gba wọle.

Bakan naa ni Ọgbẹni Idris sọ pe ijọba tun ti ṣeto ibudo iyara ẹni sọtọ fun awọn to ba ti lugbadi aarun naa, ki awọn ẹlomiran maa ba ko aarun ọhun lati ara wọn nipasẹ ifarakanra.

Aarun Ebola tun ṣẹyọ ni DR Congo, pa ọpọ eeyan

Ṣaaju ni ibẹrẹ oṣu Kẹsan an yii ni iroyin kan sọ pe o kere tan, eeyan mẹẹẹdogun lo jade laye lorilẹede Olominira Congo, latari arun Ebola tuntun to ṣẹyọ nibẹ.

Ileeṣẹ eto ilera orilẹede DR Congo lo fidi eyi mulẹ.

Obinrin alaboyun ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn kan ni wọn kọkọ fidi rẹ mulẹ pe Ebola tuntun naa kọlu loṣu Kẹjọ, ti wọn si da a duro sile iwosan fun itọju.

Awọn apẹẹrẹ Ebola bii akọ iba, ki ẹjẹ maa jade kaakiri ara ati ki eeyan maa bi lai dawọ duro ni alaboyun naa fi han, ti wọn fi fura pe Ebola lo kọlu u.

Ileeṣẹ ilera orilẹede DR Congo fi kun un pe alaboyun yii pada ku lẹyin ọjọ diẹ, nigba ti awọn ẹya ara rẹ pupọ ti daṣẹ silẹ, ti wọn ko wulo fun un mọ.

Ninu eeyan mẹẹẹdogun ti wọn lo ti ku latari Ebola, mẹrin ninu wọn lo jẹ oṣiṣẹ eleto ilera bi wọn ṣe sọ.

Bi aarun Ebola ṣe wọ Naijiria ni 2014

Loṣu keje, ọdun 2014 ni Naijiria kọkọ kagbako ọrọ aarun Ebola.

Eniyan mẹjọ lo kọkọ ba iṣẹle yii lọ ninu ogun eniyan to kọkọ kọlu.

Arakunrin Patrick Sawyer to jẹ ọmọ orilẹ-ede Liberia lo ko Ebola wọ Naijiria.

Iwadii fihan pé arun ebola tun n pada wa silẹ Adulawọ nitori pé awọn eeyan ilẹ Afrika kii ye jẹ ẹran igbẹ.

Wọn ni aarun ebola wa lara awọn ẹran igbẹ bii igala, inaki, ọbọ ati ẹyẹ adan.

Awọn onimọ ni imọtoto ṣe pataki lawujọ ki arun gbogbo ma le ṣe akoba fawọn eniyan.

Iru aarun wo gan an ni Ebola ati pe bawo lo ṣe n tan kalẹ?

Gẹgẹ bii ohun ti ajọ WHO sọ, ara ẹyẹ adan ni aarun Ebola ti wa, aarun naa si buru pupọ nitori bo ṣe maa n gbẹmi eeyan laaarin asiko perete.

Lati ara ẹranko to ba ti ni aarun naa bii inaki, adan ati ẹgbin lo ti maa n ran eeyan.

Ara adan ti wọn n pe ni 'fruit bat' ni aarun naa ti kọkọ wọ abule kan lẹyin ti wọn fọwọ kan ẹjẹ, omi ati ara ẹran to ni aarun naa ṣaaju.

Oriṣiriṣi ẹda Ebola meji lo wa, akọkọ ni Sudan ti ekeji rẹ si n jẹ Zaire.

Aarun naa maa n tan lati ara ẹnikan si omiran lati ara igbọnsẹ, ẹje, eebi ati oogun ara eni to ba ni.

Ti eeyan ba fi ara kan oku ẹni ti Ebola gbẹmi rẹ, o ṣeeṣe ki irufẹ ẹni bẹẹ ko aarun ọhun.

Ebola maa n mu ki ọna ọfun dun eeyan, o tun maa n ṣadeede fun eeyan ni iba lairo tẹlẹ.

Ti aarun naa ba ti wọ ara eeyan daadaa, irufẹ ẹni bẹe yoo maa bi, yoo si maa ṣe igbọnsẹ gburu, nigba mii ẹni to ba ni Ebola yoo maa yọ ẹjẹ jade lati idi.

Laarin ọjọ meji pere si ọsẹ mẹta ni aarun Ebola fi maa n dagba lara eeyan, o si le mu awọn aisan mii bii iba dani.

Omi ara awọn to ba ni aarun naa ma n tete gbẹ, eyii to maa n yọri si iku wọn.

Bi o ṣe le dena aarun Ebola

Ọdun 2014 ni aarun naa milẹ titi julọ lagbaye ninu eyi ti ẹmi ẹgbẹrun mọkanla eeyan lọ si.

Awọn ọna wọnyii ni o fi le daabo bo ara rẹ lọwọ Ebola:

Maa fọ ọwọ rẹ pẹlu omi ati ọṣẹ ni gbogbo igba

Lọra ni fifi ọwọ kan ẹni to ba ti ko aarun naa tẹlẹ

Maṣe fi ọwọ tabi ara kan oku, paapaa ẹni ti o ko mọ irufẹ iku to gbẹmi rẹ

Ṣọra fun pipa, fifi ọwọ kan tabi jijẹ ẹran igbẹ

Abẹrẹ ajẹsara wa nigba kan ri fun ẹda Zaire aarun naa amọ ko tii si abẹrẹ ajẹsara kankan fun ẹda Sudan.

Wayi o, awọn onimọ ti sọ pe ẹni ti wọn ba tete ṣawari aarun naa lara rẹ to si gba itọju to peye le ru u la.