Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
O n bọ, o n bọ, awọn laa dẹ de o!
Ewo la tun ri gbọ o?
Ajọ to n risi idabobo ohun jijẹ ni Naijiria, FCCPC ti kede pe ayederu ṣuga ti gba igboro kan
Oya jẹ ka ri gbọ
Ṣuga ọhun ni wọn sọ pe awon kan ko wọ Naijiria lati orilẹede Brazil
Hmmmmmmm
FCCPC sọ pe ṣuga naa ko ni eroja Vitamin A atawọn eroja aṣaraloore mii ninu
Bawo ni a wa ṣe le da ṣuga naa mọ ninu ọja bayii?
Kan soju opo BBC Yoruba fun ẹkunrẹrẹ
Ọlọpaa orilẹede Finland ti fi ṣikun ofin mu olori ẹgbẹ IPOB, Simon Ekpa
Iroyin ni ilẹ ẹjọ kan nibẹ ti paṣẹ ki wọn fi si ọgba ẹwọn lati lọ gba atẹgun fun igba diẹ
Ekpa lo n ṣe iwuri fun awọn ajijagbara Biafra lati maa kọju ija si awọn agbofinro ni Naijiria
Igba keji ree ti ọwọ ọlọpaa orilẹede naa yoo tẹ afurasi ọhun lori ẹsun sisọ ọrọ igbesunmọmi lori ayelujara