You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìyá ìjọ kó sí àhamọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn tí ìyá àti ọmọ tuntun kú sí ilé ìjọsìn lásìkò ìgbẹ̀bí
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo ni àwọn ti fi ṣìkú òfin gbé ìyá ìjọ kan Folashade Adekola lórí ikú arábìnrin kan, Jumoke Adesuwa.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ondo, Funmilayo Odunlami nígbà tó ń fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún BBC News Yorùbá ṣàlàyé pé ẹ̀gbọ́n olóògbé náà ló mú ẹjọ́ lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá pé ìyá ìjọ náà ṣokùnfà ikú àbúrò òun àti ọmọ rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé olóògbé náà jáde láyé lẹ́yìn tó bímọ sí ilé ìjọsìn ìyá ìjọ náà tó wà ní agbègbè Oke-Aro ní ìlú Akure ìpínlẹ̀ Ondo.
Odunlami ṣàlàyé pé ẹ̀gbọ́n olóògbé ọ̀hún wá fẹjọ́ sùn pé ìyá ìjọ náà kò tètè gbé àbúrò òun lọ sí ilé ìwòsàn lẹ́yìn tí ẹ̀jẹ̀ kò dá lára rẹ̀ lẹ́yìn tó bímọ tán.
Ó ní ẹ̀gbọ́n náà ṣàlàyé fún àwọn pé àbúrò òun lọ bímọ sílé ìjọsìn ìyá ìjọ náà àmọ́ ti nǹkan padà yí sódì nígbà tí ọmọ àti ìyá pàdánù ẹ̀mí wọn.
Ó fi kun pé èyí ló mú àwọn ránṣẹ́ pé ìyá ìjọ, Folashade Adekola láti wá wí tẹnu rẹ̀ lórí ohun tó mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Bákan náà ló ṣàlàyé pé ìwádìí ti ń lọ lórí ilú Jumoke Adesuwa àti ọmọ rẹ̀ àti pé ẹjọ́ náà ti wà ní ẹ̀ka tó ń rí sí ìwà ọ̀daràn láti tú iṣu dé ìsàlẹ̀ ìkòkò lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Iléeṣẹ́ ìròyìn The Punch nínú ìròyìn kan tí wọ́n fi léde ní mọ̀lẹ́bí Jumoke tí kò fẹ́ kí àwọn dárúkọ òun ṣàlàyé fún àwọn pé èèyàn kan láti ilé ìjọsìn náà ló pe àọn láti to àwọn létí pé Jumoke ti bímọ.
Ó ní èyí ló mú ọkọ Jumoke àti ẹbí wọn kan sáré lọ sílé ìjọsìn náà àmọ́ òkú ọmọ ni àwọn bá nígbà tí àwọn fi máa débẹ̀.
Ó fi kun pé nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ gan ni àwọn ti bá Jumoke táwọn sì sáré gbé lọ sí ilé ìwòsàn.
Ó ṣàlàyé pé ilé ìwòsàn mẹ́ta tí àwọn kọ́kọ́ gbe dé ni wọn kò ti gbà á lọ́wọ́ àwọn, tó sí kù lásìkò tí ilé ìwòsàn tó gbà á lọ́wọ́ àwọn fún ìtọ́jú ń dóòlà ẹ̀mi rẹ̀ lọ́wọ́.
Ó ní èyí ló mú àwọn lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá Oke-Aro láti lọ fi ẹjọ́ náà, tó sì ṣokùnfà ìdí tí wọ́n fi mú ìyá ìjọ ọ̀hún.
Òkú obìnrin náà ni wọ́n ti gbé sí mọ́ṣúárì báyìí.