You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Tinubu yan Ọ̀jọ̀gbọ́n Amupitan gẹ́gẹ́ bíi alága INEC tuntun, ìgbìmọ̀ aláṣẹ orílẹ́èdè Naijiria buwọ́lù ú
Igbimọ alaṣẹ orilẹede Naijiria, the National Council of State, ti buwọlu iyansipo Ọjọgbọn Joash Ojo Amupitan (SAN) gẹgẹ bii alaga ajọ eleto idibo INEC tuntun.
Aarẹ Bola Tinubu lo mu orukọ Ojọgbọn Amupitan lọ siwaju igbimọ alaṣẹ orilẹede Naijiria fun ibuwọlu, eyi ti gbogbo wọn si fẹnu ko le lori ti wọn si buwọlu u.
Tinubu sọ fun igbimọ naa wi pe Ọjọgbọn Amupitan ni ẹni akọkọ lati ẹkun aarin gbungbun Naijiria ti ijọba yoo yan sipo alaga INEC, ati pe ki i ṣe oloṣelu rara.
Gomina Ahmed Usman Ododo toun naa wa nibi ipade ọhun ṣapejuwe Ọjọgbọn Amupitan bi ẹni to ṣee fọkan tan to si tun jẹ Ọmọluabi.
Gẹgẹ bi alakalẹ iwe ofin orilẹede Naijiria, ohun to kan bayii ni pe Aarẹ Tinubu yoo forukọ Ọjọgbọn Amupitan ranṣẹ sile igbimọ aṣofin agba l'Abuja fun ayẹwo.
Ta a ni Ọjọgbọn Joash Amupitan ti Tinubu ṣẹṣẹ yan sipo alaga INEC?
A bi Ọjogbọn Joash Ojo Amupitan lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹrin ọdun 1967, eyi tumọ si pe ẹni ọdun mejidinlọgọta ni i ṣe.
Ilu Ayetoro Gbede ni ijọba ibilẹ Ijumu nipinlẹ Kogi ni Ọjọgbọn Amupitan ti wa.
Ọjọgbọn Amupitan jẹ olukọ imọ ẹkọ ofin nile ẹkọ giga fasiti UNIJOS, nipinlẹ Plateau.
Fasiti UNIJOS yii naa ni Ọjọgbọn ti kẹkọọ jade.
Ofin to ni ṣe pẹlu awọn ileeṣẹ, idadari ileeṣẹ ati ofin to da lori sisọ nnkan di ti aladaani ni Ọjọgbọn Amupitan jẹ akọṣẹmọṣẹ ninu rẹ.
O di agbẹjọro agba eyi ti wọn maa n pe ni Senior Advocate of Nigeria (SAN) lede oyinbo lọdun 2014.
Lẹyin to jade ile ẹkọ alakọbẹrẹ ati ile ẹkọ giga girama tan ni o tẹsiwaju ẹkọ rẹ nile ẹkọ giga gbogbonṣe Kwara Poly, Ilorin, nipinlẹ Kwara laarin ọdun 1982 si 1984.
Lọdun 1984 ni Ọjọgbọn Amupitan wọ ile ẹkọ giga fasiti UNIJOS ti o si kẹkọọ gboye jade nibẹ gẹgẹ bi amofin lọdun 1987.
Ọdun 1988 to tẹ le e ni Ọjọgbọn Amupitan yege lati maa ṣiṣẹ gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ agbẹjọro.
Lọdun 1993 ni Ọjọgbọn Amupitan gboye keji ni fasiti ninu ẹkọ imọ ofin (LLM) jade ni UNIJOS.
Lọdun 2007 lo si gboye Ọmọwe ninu ẹkọ imọ ofin ni UNIJOS bakan naa.
Ọjọgbọn Amupitan lo rọpo alaga INEC tẹlẹ, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, to fipo naa silẹ lẹyin to pari saa rẹ.