You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo àwọn orílẹ̀ èdè to lè wọ̀ nílẹ̀ Adúláwọ̀ láì lo 'visa'
Ààrẹ orílẹ̀ Rwanda, Paul Kagame ti kéde pé àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ kò ní nílò láti máa lo físà láti máa wọ orílẹ̀ èdè àwọn mọ́.
Kagame ní ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé ọmọ ilẹ̀ Adúláwọ̀ kò nílò láti san owó láti gba ìwé tí a mọ̀ sí “visa” láti wọ Rwanda mọ́.
Rwanda ni orílẹ̀ èdè kẹrin nílẹ̀ Adúláwọ̀ tó máa gbé irú ìgbésẹ̀ yìí.
Ó ní ìgbésẹ̀ àwọn yìí ń wáyé láti mú ìgbòro bá ẹ̀ka ìnàjú ilẹ̀ Adúláwọ̀ àti láti mú kí ètò ọrọ̀ ajé ilẹ̀ Adúláwọ̀ túnbọ̀ gbèèrú si.
Rwanda ló ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti mú ìgbòrò bá ẹ̀ka ètò ìgbáfẹ́ wọn, tí wọ́n sì ti ń ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù bíi Arsenal àti Bayern Munich.
Seychelles, The Gambia àti Benin ni àwọn orílẹ̀ èdè tó fàyè gba àwọn orílẹ̀ èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ láti máa wọ orílẹ̀ èdè láì lo físà.
Ṣáájú nínú ọ̀sẹ̀ yìí ni Ààrẹ Kenya, William Ruto náà kéde pé orílẹ̀ èdè àwọn máa bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ààyè gba àwọn ọmọ ilẹ̀ Adúláwọ̀ láti máa wọ orílẹ̀ èdè wọn láì gba físà.
Ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè náà ni wọ́n ti ń ní àjọṣẹpọ̀ láti gba àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè ara wọn wọlé láì lo físà.
Láìpẹ́ yìí ni Ghana àti South Africa tọwọ́bọ àdéhùn láti máa wọ orílẹ̀ èdè ara wọn láì lo físà, tí Uganda àti Democratic Republic of Congo náà sì ṣe bẹ́ẹ̀.
Àwọn orílẹ̀ èdè Adúláwọ̀ tí o le wọ̀ láì ní "visa"
Ní ọdún 2022, àjọ Africa Vis Openness Index, AVOI gbé àtẹ̀j;ade síta pé Benin, Seychelles àti The Gambia ni àwọn orílẹ̀ èdè tó fi àyè gba àwọn àlejò láti ilẹ̀ Adúláwọ̀ mìíràn láì lo físà.
Àmọ́ ní báyìí orílẹ̀ èdè Rwanda náà ti darapọ̀ mọ́ wọn.
Nínú àtẹ̀jáde náà ọ̀hún, ó hàn pé orílẹ̀ èdè mẹ́sàn-án ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà ló ń ṣe dada jùlọ nínú àwọn orílẹ̀ èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ ogún tí ènìyàn le wọ̀ láì ní físà tàbí ṣe wàhálà físà púpọ̀.
Àwọn orílẹ̀ èdè mẹ́sàn-án náà ni Benin, The Gambia, Senegal, Ghana, Nigeria, Guinea Bissau, Cape Verde, Togo àti Sierrs Leone.
Senegal ló wà ní ipò kẹrin, Ghana wà ní ipò karùn-ún tí Nàìjíríà sì wà ní ipò keje nínú àwọn orílẹ̀ èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ tí èèyàn le wọ̀ láì ṣe wàhálà físà.
Àwọn orílẹ̀ èdè mẹ́rin ní ẹkùn gúúsù Áfíríkà ló wà ní ipò mẹ́rin àkọ́kọ́. Àwọn ni Madagascar, Mauritius, Mozambique àti Namibia.
Àtẹ̀jáde náà fi kun pé orílẹ̀ èdè mẹ́fà láti ìlà oòrùn Adúláwọ̀ ló wà nínú àwọn orílẹ̀ èdè ogún náà, àwọn náà sì ni: Comoros, Rwanda, Seychelles, Somalia, Tanzania àti Uganda.
Ghana àti South Africa tọwọ́bọ àdéhùn láti máa wọ orílẹ̀ èdè ara wọn láì lo físà
Orilẹ-ede Ghana ati South Africa ti tọwọbọ adehun pe awọnọmọ orilẹ-ede mejeji le maa wọ orilẹ ede arawọn lai gba iwe iwọlu ti a mọ si “visa”.
Ohun ti eyi tumọ si ni pe iwe irinna nikan ni awọn ọmọ orilẹ ede mejeeji yii nilo lati wọ orilẹ arawọn lati lo aadọrun-un ọjọ.
Atẹjade kan ti Minisita to n risi ọrọ ilẹ okere ni orilẹ-ede Ghana fi lede ni lati ọjọ Kiini, osu Kọkanla, ọdun 2023 ni ilana tuntun yoo bẹrẹ.
Lẹyin ti aadọrun-un ọjọ ba pe ti ẹni to rinrinajo yii ṣi fẹ maa wa ninu awọn orilẹ ede yii, onitọhun yoo ṣẹṣẹ gba iwe aṣẹ lati tunbọ wa ninu orilẹ ede naa.
Atẹjade kan lati ile iṣẹ South Africa to wa ni Ghana ni ti kii ba ṣe inu ọdun kan ni gbogbo awọn aadọrun-un ọjọ yii bọ si, onitọhun ko ni gba iwe igbelu.
Ṣaaju asiko yii, awọn ọmọ orilẹ-ede Ghana ati South Africa maa n nilo fisa lati wọ orílé ede arawọn.
Awọn ọmọ Ghana ko ni anfani pe ti wọn ba de South Africa ki wọn to gba fisa gẹgẹ bo ṣe wa fun awọn orilẹ ede kan tẹlẹ amọ ti anfani naa ti wa fun wọn bayii.
Gbigba fisa lọ si South Africa lati Ghana maa n gba ọpọlọpọ ọsẹ tabi oṣu nitori awọn eniyan maa n pọ nibẹ.
Nigba to n ba BBC sọrọ, Ernest Apraku ṣalaye pe o gba oun to oṣu meji lẹyin ti oun kọwe lati gba fisa lọ si orilẹ-ede South Africa fun isinmi.
O fi kun pe pẹlu igbesẹ tuntun yii, o maa din gbogbo iṣoro ati ọpọlọpọ wahala lati gba fisa ku fun awọn ọmọ orilẹ-ede naa.
Ninu oṣu Kẹsan-an ọdun yii, adẹrininpoṣonu kan ni Ghana, OB Amponsah kò ribi kopa nibi ayẹyẹ awada kan ni South Africa ti awọn akẹgbẹ rẹ n ṣe.
O kọ sori ayelujara nigba naa pe oun ko ribi kopa nibi ayẹyẹ naa pẹlu gbogbo wahala ti oun ṣe lati ri iṣẹ naa gba latari bi oun ko ṣe ri fisa gba.
Lẹyin ti wọn kede igbesẹ tuntun yii, o ni aarẹ orilẹ ede awọn ṣe dada pẹlu ohun ti wọn ṣe yii.