You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ayédèrú òṣìṣẹ́ EFCC méjì rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìndínláàdọ́ta he l’Eko
Ọkunrin meji kan, Ugwu Chijioke ati Ibrahim Adekunle, ti ri ẹwọn ọdun mẹridinlaadọta he lẹyin ti wọn jẹbi ẹsun pipe ara wọn ni oṣiṣẹ ajọ EFCC.
Ninu atẹjade kan ti ajọ naa fi lede lọjọ Aiku, inu oṣu Karun un, ọdun 2021 ni ọwọ tẹ aswọn ayederu oṣiṣẹ EFCC naa lagbegbe New Horizon Estate, to wa ni Lekki, nilu Eko.
Ibi ti wọn ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bii ọkan lara oṣiṣẹ EFCC gan ni ọwọ ti tẹ wọn.
Lara awọn nnkan ti wọn ka mọ wọn lọwọ ni ayederu kaadi idanimọ EFCC, aṣọ EFCC ati ayederu iwe aṣẹ lati ile ẹjọ majistreeti kan ni Mushin.
Lẹyin naa ni wọn gbe wọn lọ sile ẹjọ lori ẹsun marun un ọtọtọ to rọ mọ fifi ara ẹni pe ẹlomiran lati lu jibiti, igbimọpọ lati lu jibiti dukia, nini ayederu iwe ijọba ni kawọ ati wiwọ aṣọ EFCC lọna to lodi si ofin.
Nigba ti wọn yọju siwaju adajọ O.O Abike nile ẹjọ to wa ni Ikeja, awọn mejeji sọ pe awọn gba pe awọn jẹbi ṣun ti EFCC fi kan awọn.
Lẹyin ti wọn sọ beẹ tan ni olupẹjọ Abdulhamid Tukur fa iwe ẹjọ naa le adajọ lọwọ, to si sọ pe wọn ti gba pe awọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.
Tukur wa rọ ile ẹjọ naa lati ṣe idajọ wọn bo ṣe tọ atibo ṣe yẹ.
Adajọ Abike-Fadipe ni ẹri to wa niwaju oun fi han pe awọn eeyan naa jẹbi gbogbo ẹsun mararun ti wọ fi kan wọn.
Ile ẹjọ ọhun tun fun awọn afurasi naa lanfani lati sọrọ, ninu eyii ti wọn ti bẹbẹ fun oju aanu adajọ ọhun.
Nigba to n ṣedajọ rẹ, Adajọ Abike-Fadipe fi ẹnikọọkan wọn si ẹwọn ọdun meje-meje fun ẹsun kinni si ikẹta.
O tun fi wọn si ẹwọn ọdun kan fun ẹsun kẹrin ati ẹwọ oṣu mẹjọ fun ẹsun karun un.