You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìjọba Tinubu kò ní pariwo lórí àyájọ́ ọdún kan tó dé ipo ààrẹ - Iléeṣẹ́ ààrẹ
Ijọba apapọ orileede Naijiria ti kede sita pe ko nii si afẹfẹyẹyẹ kankan ti yoo waye ninu eto ayajọ iṣẹ iṣejọba awa-ara-wa ti ọdun yii.
Minisita fọrọ eto iroyin ati ilanilọyẹ, Mohammed Idris lo sọ eyi di mimọ loni, Ọjọru nibi ipade awọn akọroyin to se nile redio tiluu Abuja, iyẹn Radio House.
Idris sọ pe abẹle ni wọn yoo ti ṣe ayẹyẹ naa, ati pe ijọba apapọ ko ṣetan lati na owo ilu lori ayẹyẹ.
Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun, ọdun 2024 ni yoo pe ọdun kan gbako ti Aṣiwaju Bọla Tinubu gba ijọba gẹgẹ bi aarẹ kẹrindinlogun fun orileede Naijiria.
Gbogbo ọjọ kọkandinlọgbọn ọdọọdun naa si ni ilẹ Naijiria maa n fi saami ayẹyẹ ayajọ ọjọ ti wọn bẹrẹ eto iṣejọba awa-ara-wa, iyẹn ọjọ ti wọn bẹrẹ ijọba alagbada.
Aarẹ ana, Muhammadu Buhari lo yi eto ọhun kuro ni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un si ọjọ kejila, oṣu kẹfa ọdọọdun lati fi bu ọla fun eto idibo June 12, 1993, eyi ti ijọba ologun danu.
Abajade esi eto idibo ọhun fi ye wa pe Moshood Abiọla lo jawe olubori, bo tilẹ jẹ pe wọn ko kede rẹ labẹ ofin, ti ijọba ologun labẹ iṣakoso Ọgagun Ibrahim Babangida ko si gbe ijọba le lọwọ.
Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko yii ni ko tii sẹni to le sọ pato boya ijọba Naijiria yoo ṣayẹyẹ ọhun lọjọ kejila, oṣu kẹfa, ọdun yiii, eyi ti ijọba ana ṣagbekalẹ rẹ.
Tinubu to jẹ ọkan pataki lara awọn alatilẹyin Abiọla nigba naa ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe wọn yi ayajọ ọjọ iṣejọba awa-ara-wa pada si June 12.
Ṣugbọn nigba to n sọrọ nipa eto to ti wa nilẹ fun ayẹyẹ ọdun kan Aarẹ Tinubu lori ipo, Idris sọ pe ijiroro ni eto ayẹyẹ ọhun yoo gbajumọ, dipo ki wọn dana ariya, gẹgẹ bo ti maa n waye tẹlẹ.
Ninu ọrọ rẹ, “Abẹle ni eto ọhun yoo ti lọ, ko nii si afẹfẹyẹyẹ kankan, bi ko ṣe ipade ẹkun iṣejọba lati ọdọ awọn minisita.
“Pataki rẹ ni lati rii pe a tọju owo ijọba fun lilo araalu.”
O tẹsiwaju pe ipade ati ijiroro ọhun yoo da lori ẹka eto iṣejọba mẹjọ ọtọọtọ, ati pe awọn minisita ni yoo sọrọ ni oriṣiriṣi ẹka naa lori ohun ti wọn ri.