You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn ìlúmọ̀ọ́ká obìnrin olóṣèlú Nàìjíríà réè tí wọn fí ẹsùn àjẹbánu kan nìdí ipò tí wọn fí wọn sì
Orileede Naijiria jẹ ilẹ kan to gba orukọ buruku lori ọrọ ajẹbanu eyi to mu abuku ba awọn eeyan ilẹ naa jakejado agbaye.
Ọrọ naa buru debi pe olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi nigba kan David Cameron níbi apero kan ṣapejuwe Naijiria gẹgẹ bi orileede kan ti iwa ajẹbanu gbogo.
Koda ninu akọsilẹ to n safihan awọn orileede kọọkan ati bi iwa jẹgudujẹra se6 rinlẹ to nibẹ, iwaju ni Naijiria wa ninu awọn orileede alajẹbanu.
Ninu awọn ti aje iwa ibajẹ yi máa n ṣi mọ lori l'awọn to dì ipo oṣelu mú ti wọn a sí maa tọka siwọn gẹgẹ bi agbatẹru iwa jibiti.
Idi si ni pe t'awọn eeyan ba ti dé ipo ijọba pẹnrẹn nise ni igbe aye wọn maa n sare yatọ sí tatẹyinwa.
Ajẹbanu a maa mu ki ọpọ naka sí ohun tí owo oṣu wọn ko ka ti a ba ni ka ṣe agbeyẹwo rẹ daada.
Lẹnu lọọlọ yi iroyin ti ṣafihan awọn obìnrin to di ipo mu labẹ ìjọba ti wọn si wa n ṣe iwadii wọn tabi ti wọn ni wọn ka wọn mọ nidi lilu owo ọba ni ponpo.
Lọsẹ to kọja yi ni a gbọ pe wọn ni ki adari ẹka to n mojuto ipese iranwọ ati atilẹyin fàwọn to n da iṣẹ ará wọn ṣe NSIPA ìyẹn Halima Shehu.
Minisita ileeṣẹ to n risi ipese iranwọ ati idẹkun iṣẹ lawujọ to jẹ ọga rẹ Dr Betty Edu lọ ni ko lọ rọọkun nile ki iwadii ba le tẹsiwaju lori ẹsun magomago ti wọn fi kan an.
Wọnyi lakojọpọ awọn obìnrin ilumọọka marun un to dipo mu ni Naijiria ti wọn fẹsun ajẹbanu kan yala nigba ti wọn wa lenu6 ise5 ati lẹyin ti wọn kuro tan.
Stella Odua
Minisita ileeṣẹ ọkọ ofurufu ni Stella Oduah jẹ labẹ ijọba aarẹ tẹlẹ Goodluck Jonathan.
O ti to ọdun meloo kan bayii ti wọn ti n ṣe ẹjọ rẹ lori ẹsun ajẹbanu ti wọn si tori rẹ aga nidi rẹ lọdun 2014.
Aarẹ Jonathan yọ nipo lẹyin ti ariwo pọ lati ọdọ awọn ọmọ Naijiria lori ẹsun pe o ṣe magomago owo ijọba to sunmọ biliọnu marun un Naira.
Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan ni pe o ko owo ijọba ra ọkọ ayọkẹlẹ lọna aitọ.
Ọrọ naa sí wa ni ile ẹjọ ti Oduah si sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.
Diezani Alison-Madueke
Ninu awọn Minisita ti ẹnu kan julọ ninu awọn minisita labẹ isakoso ijọba Goodluck Jonathan.
Lati igba ti ijọba aarẹ tẹlẹ Muhammadu Buhari de ori oye ni 2015 títí dì asiko yi ni wọn tí n ṣe ẹjọ Diezani lori ẹsun ajẹbanu.
Ni oṣu kẹjọ ní igbimọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni ilẹ Gẹẹsi fi ẹsun abẹtẹlẹ kan Minisita ọrọ epo rọbi tẹlẹ naa.
Bẹẹ naa ni wọn fẹsun kan Diezani pe gba aimọye miliọnu owo pọun gẹgẹ bi abẹtẹlẹ lori awon iṣẹ akanṣe lọdọ awọn kọngila lẹka afẹfẹ gaasi ati epo rọbi.
Lati igba ti won ti mu ni London loṣu Kẹwa ọdun 2015 titi di asiko yi ni Diezani ti gba beeli.
Minisita tẹlẹ naa tako gbogbo ẹsun ti wọn fi kan an.
Sadiya Umar- Farouq
Lọjọ Aje yi ni Minisita tẹlẹ ri to n mojuto ipese iranwọ ati idẹkun iṣẹ lawujọ labẹ ìjọba Aarẹ Buhari jọwọ ara rẹ fun ajọ Efcc.
Eyi ni ko baa le dahun ibeere lori awọn ẹsun ajẹbanu ti wọn fi kan an..
Minisita tẹlẹ ri náà sọ pe oun gba lati yọju si Efcc lati le yanju awuyewuye lori awọn iwadii ti ajọ naa n ṣe lori ẹsun ajẹbanu.
Lọsẹ to kọja Efcc fi iwe pe Sadia Farouq lati wa tan imọlẹ si awọn ọrọ kan to nise pẹlu inakuna biliọnu náírà ti ijọba ya sọtọ fawọn alaini lawujọ.
Minisita tẹlẹ naa sọ pe oun ko lọwọ ninu aṣemáṣe kankan.
Lasiko to wa lori ipo o jẹ ọkan ninu awọn minisita ti ẹnu ko ja lara wọn labẹ ìjọba aarẹ Muhammadu Buhari.
Halima Shehu
Lọsẹ to kọja Aarẹ Tinubu buwọlu aṣẹ lọ rọọkun nile ti wọn pa fun adari ẹka to n mojuto ipese iranwọ ati atilẹyin fàwọn to n da iṣẹ ará wọn ṣe, NSIPA, iyẹn Halima Shehu.
Wọn fẹsun kan pe o lọwọ ninu jiji owo aimọye biliọnu Náírà jẹ ti ajọ Efcc si ti n tọ pinpin ọrọ naa.
Ìṣẹlẹ yí waye ni oṣu meloo kan lẹyin ti wọn yan sipo.
Ariwo pọ lori ọrọ yi debi pe wọn ti ni ko lọ rọọkun nile titi ti iwadii yoo fi pari.
O ṣeéṣe ko koju ile ẹjọ ti wọn ba ri pe ejo rẹ lọwọ ninu.
Halima Shehu sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.