You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Afurasí kú sí àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Ilorin, àwọn agbófinró ṣàlàyé ohun tó ṣekúpa á
Ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelọgọta kan, Alhaji Taye Hussein Abubakar ni a gbọ pe o gbekuru jẹ lọwọ ẹbọra lẹyin ti o ti wa latimọle ọgba ẹwọn Oke-Kura, ni Ilorin, olu ilu ipinlẹ Kwara.
Lọjọ Ẹti, ọjọ Kẹwaa, oṣu karun-un, ọdun 2024 ni iṣẹlẹ naa waye ni nnkan bii ago mẹjọ owurọ.
Iwadii fihan pe Abubakar jẹ ontaja ilẹ, o si ta ilẹ kan fun awọn onibaara rẹ kan to n gbe ni ilu kereje ti o wa lagbegbe Ilorin.
Ọrọ ilẹ yi lo di wahala laarin oun ati awọn to ra ilẹ lọwọ rẹ, ti wọn si wọ ọ lọ si ile ẹjọ.
Iwadii tun fidi rẹ mulẹ pe ontaja ilẹ to di oloogbe yii ti wa latimole Oke-Kura fun bii osu diẹ bayii.
Mọ̀lẹ́bí bu ẹnu àtẹ́ lu ilé ẹjọ́, iléesẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n lórí ikú Abubakar
BBC Yoruba ba ọkunrin kan ninu awọn mọlẹbi oloogbe naa, to ni ka forukọ bohun lasiri sọrọ, o si tanmọlẹ si ọrọ naa.
Ọkunrin yi bu ẹnu atẹ lu ile ẹjọ ati ajọ ọgba ẹwọn lori iṣẹlẹ naa.
O ni "ọrọ ilẹ ni o di ọrọ ẹjọ ti a n wọ ra ẹni lọ sile ẹjọ, ile ẹjọ gba beeli Abubakar sugbọn ko farahan ni ọjọ ti ile ẹjọ sun igbẹjọ mii si nitori aisan ti o n ṣe e.
"Wọn nawọ gan-an wọn si tii mọle lati igba naa to ti jẹ bi osu mẹrin si marun-un bayii. Wọn ko gbe lọ ile ẹjọ mọ sugbon wọn pa a ti si ọgba ẹwọn Oke-Kura.
"Ṣe bi o yẹ ki wọn fún-un ni anfani ẹlẹẹkeji, bawo lo ṣe fẹ rowo da pada fun awọn ti wọn jọ ṣe owo ilẹ ninu ọgba ẹwọn ti wọn fi si.
"A lọ ba adajọ pẹlu awọn oniduro a bẹ ẹ ki o tun gba beeli rẹ, sugbọn pabo ni gbogbo igbiyanju wa jasi.
"Ni ọjọ Ẹti ni a gbọ pe wọn gbe e digba digba lọ ile iwosan, awọn kan sọ pe o ti ku lati ọna, awọn mii ni o ku nibi to ti n gba itọju nile iwosan. Ọrọ ilera rẹ koyanranti, adajọ si mọ si.
BBC Yoruba tun ba alukoro Ileesẹ ọgba ẹwọn ipinlẹ Kwara, iyẹn Phillip Adegbulugbe sọrọ, o si fidi ọrọ naa mulẹ.
O ni oloogbe naa ku si ile iwosan lori aisan to niise pẹlu kidinrin.
"O ku si ile iwosan gbogbogbo Ilorin, mo ri awọn faili rẹ nile iwosan to fidi aisan to paa mulẹ, ni irọlẹ ọjọbọ ni wọn gbe e lọ sile iwosan.
"Ko ku si akata wa gẹgẹ bii awọn kan ṣe n polongo rẹ ọsibutu lo ku si".