Awakọ̀ tó ń wa 'ìwàkuwà' kọlu àwọn ológun tó ń yan fanda l'Eko, ológun kan kú, ọ̀pọ̀ farapa

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awakọ kan ti gbẹmi ọmọ ogun niluu Eko lẹyin to ya bo aarin awọn ologun nibi ti wọn ti n yan fanda.

Ẹka 81 Division ileeṣẹ ọmọ ogun kede pe ṣe ni awakọ naa n wa iwakuwa ko to fi ọkọ rẹ gba awọn ọmọ ogun to n yan fanda nileegbe awọn ologun Myhoung Barracks, to wa ni yaba, niluu Eko.

Wọn ni ologun kan padanu ẹmi rẹ sinu ijamba naa nigba ti awọn mii farapa yanayana.

Olabisi Ayeni, to jẹ igbakeji agbẹnusọ ileeṣẹ naa lo fi ikede ọhun sita.

Ayeni sọ pe ileeṣe naa atawọn agbofinro mii ti bẹrẹ iwadii lati mọ kulẹkulẹ ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa.

O fi kun pe ọga agba ẹka 81 Division, ọgagun Farouk Mijinyawa ti ba mọlẹbi gbogbo awọn ti ọrọ naa kankẹdun.

Lẹyin naa lo ke si awọn araalu ki wọn ṣe suuru, ki wọn ma si fi ofin si ọwọ ara wọn nitori iwadi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.

O ni "ẹka ileeṣẹ yii ko yẹsẹ ninu afojusun rẹ lati ṣiṣẹ rẹ lai fi ti ohun to waye ṣe.

"Siwaju si, iṣẹlẹ buburu yii ko ni di wa lọwọ ninu ojuṣe wa, eyii to jẹ ṣiṣe abo lori ẹmi ati dukia awọn eeyan agbegbe ti a n bojuto gẹgẹ bii ofin ileeṣe ọmọ ogun ṣe gbe kalẹ."

Iyanfanda ti awọn ologun n ṣe ṣaaju iṣẹlẹ naa jẹ eyii ti wọn maa n ṣe loorekoore kaakiri ipinlẹ Eko.

Eto naa lo wa fun itẹsiwaju igbaradi wọn lẹnu isẹ gẹgẹ bii ologun.